Èyí ni bí Canada ṣe di ibùba fún àwọn jàgùdà ajọ́kọ̀gbé lágbáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Nadine Yousif
- Role, BBC News, Toronto
Logan LaFreniere ji lowurọ ọjọ kan loṣu kẹwaa ọdun 2022 lo ba ti wọn ti ji ọkọ ayọkẹlẹ rẹ lọ nibi to gbe e si.
Ẹrọ ayaworan abo to fi si ile ṣe afihan awọn eeyan meji kan ti wọn fi ipa wọ inu ọkọ rẹ loru ni ilu Milton, Ontario ti wọn si fi irọrun wa ọkọ naa lọ.
Lẹyin oṣu diẹ, ọkọ rẹ yii kan naa fi ara han lori oju opo itakun ayelujara kan lorilẹede Ghana nibi ti wọn ti n ta awọn ọkọ.
Nnkan bii ẹgbẹrun mẹjọ o le ẹẹdẹgbẹta ibusọ lo wa laarin Ontario lorilẹede Canada si orilẹede Ghana
LaFreniere ṣalaye pe “Ko si aniani lori boya ọkọ mi ni tabi ohun kọ. Apo ẹrẹ kọmputa alagbeka ti a gbe sibi ijoko ẹyin awakọ fun ọmọ mi ọkunrin lati maa lo ṣi wa nibẹ.”
Lọdun 2022, o le ni ẹgbẹrun marunlelọgọrun ọkọ ti wọn ji lọ ni orilẹede Canada – eleyi tumọ si pe laarin iṣẹju marun-marun wọn gbọdọ ji ọkọ kan lọ lorilẹede Canada.
Lara awọn to ti fi ara ko ina iṣẹlẹ yii ni minisita fun eto idajọ lorilẹede naa. Igba meji ọtọọtọ ni awọn ole agbewiri ti ji Ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Highlander XLE ti ijọba orilẹede naa gbe fun un gbe.
Ni aipẹ yii, ajọ ọlọpaa agbaye, Interpol kede orukọ orilẹede Canada gẹgẹ bi ọkan lara awọn orilẹede mẹwaa ti gbewiri ọkọ ti n waye julọ ninu ọrilẹede mẹtadinlogoje ti wọn gbe yẹwo.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Awọn alaṣẹ sọ pe ni kete ti wọn ba ti ji awọn ọkọ naa, yala ki wọn kọkọ lo wọn lati fi hu iwa ọdaran, tabi ki wọn ta a fun awọn ọmọ orilẹede Canada miran ti ko mọ pe ọkọ ole ni wọn ra, tabi ki wọn ko o lọ si oke okun fun tita.
Ajọ ọlọpaa agbaye, Interpol ni nnkan bii aẹgbẹrun kan o le ẹẹdẹgbẹta (1500) kọ ni oun ti ri kaakiri agbaye to jẹ wi pe lati orilẹede Canada ni wọn ti ji wọn gbe lọ laarin oṣu keji dun 2024 si asiko yii, bẹẹni igba ọkọ ni wọn ṣi n ri lọsọọsẹ kaakiri awọn ibudokọ ojuomi lawọn orilẹede miran lagbaye.
Wahala yii ti mu ki awọn ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede naa maa gbe ikede sita loorekoore lori idanilẹkọ nipa awọn ọna tawọn araalu le e gba daabo bo ọkọ wọn.
Amọṣa awọn eeyan kan lorilẹede naa ti gbe igbesẹ ojulalakan fi n ṣọri funrawọn nipa ṣiṣe awọn ohun elo imọ ẹrọ atọpinpin ọkọ, (tracker) si ara ọkọ wọn tabi gba ọdẹ adugbo.
Bi ọrọ iṣẹlẹ ọkọ jijigbe ṣe n pọ sii lorilẹede Canada n kọ ọpọ lominu paapaajulọ bi o ṣe jẹ pe iye awọn eeyan to n gbe orilẹede naa gan ko to nnkan, bi eeyan ba gbe e yẹwo ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu awọn orilẹede bii Amẹrika ati ilẹ Gẹẹsi, gẹgẹ bi ọgbẹni Alexis Piquero, oludari ajọ to n mojuto awọn iwadi nipa eto iṣedajọ ṣe sọ.
Lọwọ yii ọwọja iṣẹlẹ ọkọ jijigbe ti mu ẹnu lọ soke lorilẹede Amẹrika, Canada ati ilẹ Gẹẹsi lati igba ti ajakalẹ arun COVID 19 ti waye. Iye iṣẹlẹ ọkọ jijigbe ni Canada pọ ju ti ilẹ Gẹẹsi ati Wales lọ gẹgẹbi awọn abajade iwadi kan ṣe sọ.
Bakan naa lo sun mọ ti Amẹrika, to sọ pe laarin ẹgbẹrun lọna ọgọrun un eeyan ọ̀kọ ọọdunrun ni wọn n jigbe.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images















