Onímọ́tò ò ríbi gbà, ẹlẹ́sẹ̀ kò ríbi rìn – ohun tójú ń rí láwọn òpópónà tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun rèé
Onímọ́tò ò ríbi gbà, ẹlẹ́sẹ̀ kò ríbi rìn – ohun tójú ń rí láwọn òpópónà tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun rèé
Laipẹ yii ti ojo arọọrọda kan rọ lapa iwọ oorun Naijiria, ọpọ aṣiri awọn opopona to ti di ẹgẹrẹmiti lo tu sita.
Amọṣa lara awọn eyi ti ọpọ araalu da ẹnu bo julọ, paapaajulọ lori ayelujara ni awọn opopona ipinlẹ Ogun.
BBC Yoruba tẹkọleti gba ipinlẹ Ogun lọ lati fi oju ganni ipo ti awọn opopona naa wa ati iriri awọn araalu lagbegbe naa nipa awọn opopona yii.
Ọpọ awọn eeyan ipinlẹ naa paapaa awọn awakọ atawọn oniṣowo ni wọn n sọ pe ipo ti awọn opopona naa wa jẹ ọgbẹ ọkan fun.
Wọn ni kii ṣe ọṣẹ diẹ ni awọn opopona naa n ko ba ọrọ aje wọn ti awọn miran tilẹ ni o ti ran awọn lọ si oko gbese.







