Àwọn egúngún mánigbàgbé nínú àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ilẹ̀ Ibadan

Oríṣun àwòrán, Others
Eegun gbigbe ni ilẹ kaarọ ojire jẹ ohun ti pataki, to si ni iṣẹ to n ṣe nipasẹ aṣa Yoruba.
Bi ọpọ eegun se ma n da nnkan boju ni ọpọ gbagbọ pe ohun lo mu da yatọ bo ti lẹ jẹ pe eeyan lo wa labẹ oro lo n jẹ ki oro fọhun sita.
A le pe eegun ni Orisa nitori bi awọn olugbagbọ wọn n se ẹbọ ati etutu fun ni ọdọọdun
Ara oorun ni wọn ma n pe awọn eegun, ti ọpọ si gbagbọ pe adura le gba latara wọn.
Bi eegun kan se n da nnkan boju pe wọn ko gbọdọ fi oju kan oun ni awọn mii ma n si oju silẹ.
Bakan naa ni awọn eegun kan wa to jẹ ẹgba ni wọn mu kiri, ti awọn ololufẹ wọn yoo si ma na arawọn lasiko ajọdun eegun.
Ti a si ni awọn to jẹ pe ijo ni wọn ma n jo kiri.
Eegun pe orisi meji, a ni eegun alare ati eegun onidan.
Ilu ibadan, gẹgẹ bi ilu ologun jẹ ọkan lara ilu ti eegun ti wọpọ, ti ajọdun si ma waye ninu oṣu kẹfa ọdun.
Ẹ ma ba kalọ bi o se ma ṣafihan awọn eegun naa
Eegun Oloolu
Ti a ba sọrọ nipa eegun nilẹ Ibadan ati ilẹ Yoruba ni apapọ, ọkan gboogi ti ko ṣe fi ọwọ rọ lọ sẹyin ni eegun Oloolu.
Igbagbọ wa pe oun ni eegun to ma jade sita gbẹyin ni ilẹ Ibadan.
Ọpọlọpọ eewọ lo rọ mọ eegun oloolu ti ti wọ asiko yii.
Ni kete ti eniyan ba ti darukọ eegun Oloolu ní Ibadan ni kaluku ti ma maa forí gbarí, tí wọn maa sa asala fun ẹmi ara wọn nitori ẹru, paapa awọn obinrin.
Awọn obinrin kii ti ẹ sọsẹ rara nigba ti wọn ba ti gbọhun wi pe eegun Oloolu fẹ jade.
Oloolu funrarẹ foju han lori itakun BBC Yoruba, Ọkan pataki ni gbajugbaja egungun yii jẹ laarin gbogbo eegun to n bẹ nilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo.
Alapasanpa
“Alapansanpa ‘o dele Olubadan, Ibadan o f’ararọ”
Awọn mii ma n pe eegun yii ni Eegun Ogundeji, ti oun naa jẹ olokiki ni ilẹ Ibadan.
Eegun yii ni wọn ma n ko ọrẹ tẹle lẹyin ju ni ilẹ Yoruba.
Ọpọ ija lo ma n waye lẹyin eegun yii lasiko to ba jade.
Eegun naa lẹru lara, ti ọmọde ati agbalagba si bẹru rẹ.
Bẹẹni, o ni ẹwọ fun obinrin, ẹ irinju. Igbagbọ wa pe Obinrin to ba n se nnkan oṣu lọwọ ko gbọdọ wọple si yara agbara rẹ.
Igbagbọ wa pe irufẹ obinrin naa le gba ibẹ jade laye.
Eegun Iponriku
Iponriku pa Oloolu si Gege
Eegun mi to tun jẹ eegun alagbara ni ilẹ Ibadan ni Iponriku, ko da awọn mii agbagbọ pe o ni agbara ju eegun oloolu lọ.
Ni ọdun 1928, ija waye ni eegun Oloolu ati Iponriku ni ọja Gege niluu Ibadan.
Iponriku bẹ ori Oloolu lasiko ogun naa, to si jẹ pe ohun lo di ifa fun ori ti wón ma n kọ pe Iponriku pa Oloolu ni Gege.
Omi ni ẹrọ Iponriku, wọn gbọdọ ma bu omi si lori ni gbogbo igba.

Oríṣun àwòrán, Others
Abidiẹlẹgẹ
Eegun yii na jẹ agba eegun ni ilẹ Ibadan, to jẹ pe ẹkan lo ma n jade laarin ódun mẹta.
Lasiko ti eegun ba jade, awọn eeyan to ba tẹle lẹyin ma n fi nnkan bori ori wọn nitori pe o fi fọn oyin sita.
Ọpọ awọn eeyan lo ma n fi ewe bo ori wọn
Eegun Ajitoni
Orukọ abiku ni wọn n pe ni ajitoni, eegun ọlọmọ ni.
Pupọ awọn to ma n tẹle eegun lo jẹ awọn to n wa ọmọ.
Wọn ko gbọdọ pọn ọmọ pada eegun Ajitoni.
Eegun Atipakọ.
Eegun yii ni baba eegun ni ilẹ Ibadan.
O jẹ eegun ti wọn ko ki n ko ẹgba dani lasiko to n ba jade.
Awọn obinrin lo ma n tẹle ju, to si ma n ru ẹru sori.

Oríṣun àwòrán, Others















