Àyẹ̀wò DNA kó Pásítọ̀ yọ lọ́wọ́ ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀

Àkọlé fídíò, Àyẹ̀wò DNA kó Pásítọ̀ yọ lọ́wọ́ ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀

Pasitọ Titus Ajibade Oladipupo to jẹ olusọ aguntan ile ijọsin Baaki Baptist niluu Ogbomoso ni awọn eeyan kan fẹsun kan wipe o fun ọmọ loyun, to si tun fipa ba lọpọ.

Isẹlẹ naa waye ninu oṣu keji ọdun 2022, ti pasitọ si dero atimọle.

Pasitọ Oladipupo salaye pe aburo iya ọmọ to ti mu ọmọ sọdọ lati ọdun mẹfa , to si n ṣe itọju rẹ, ti ọmọ naa si ma tẹle mama rẹ wa gba ilẹ ile ijọsin lẹẹkan laarin ọsẹ.

“Inu ọfisi mi ni mo joko si lọjọ yẹn, ni ọjọ keje oṣu keje ọdun 2022, ni mama to mu sọdọ wa ba mi pe ọmọ fi ẹsun kan mi pe emi ni mo fun oun loyun.

“Mo dẹ sọ pe emi, laye ati laye ko le waye, kooda, ko le gbagbọ, mo fi Bibeli bura lọjọ yẹn.”

Aworan Pasitọ Oladipupo

Pasitọ tẹsiwaju pe lẹyin igba naa ni ẹnikan to pe ara rẹ ni Pasitọ ni o lọ ba wọn wipe wọn ko gbọdọ gba, ti wọn si ransẹ si Pasitọ lati ẹka ijọba Welfare, ti wọn si gbe wọn lọ si ile ẹjọ lọjọ keji.

“Nigba ti a de ileẹjọ, ni wọn ba tun fẹsun mi kan mi pe mo fipabalopọ ni.”

Oladipupo ni ọtọ ni ohun ti awọn ba wa ile ẹjọ sugbọn wọn mu ẹsun mi jade pe oun tun fipaba ọmọ naa lopọ, ti wọn si gbe lọ si ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Owode niluu Ogbomoso.

Nigba ti mo wa ni ahamọ, awọn ọlọpaa ni pe ki gba pe emi ni mo fun ọmọ naa loyun sugbọn mo kọ pe n ko gba nnkan ti n ko se rara.

“Mo wa ni ahamọ fun ọjọ mẹta ki ọlọpaa kan to wa de pe o yẹ ki n ti jade sugbọn mo sọ fun n ko le gba nnkan ti awọn ọlọpaa ni ki ṣe.

“Ọlọpaa yẹn wa lọ ba awọn, igba naa ni wọn wa ọrọ naa gbe kalẹ pe ki ma tọju ọmọ naa, iyẹn ni mom wa gba ti wọn fi wa fi mi silẹ

'Mo n san ẹgbẹrun lọna 25 fun ọmọ naa loosu, ki ayẹwo to jade'

Pasitọ Oladipupo ni oun gba lati ma se itọju ọmọ naa,ti oun si san owo fun itọju rẹ ni osoosu ati awọn owo ile iwosan lorisirisi.

“A lọ se DNA, igba ti a de, adajọ ba tun yari pe ki ni idi ti a fi lọ ṣe ni ileeṣẹ aladani, ti a ko lọ ṣe ni ile iwosan ijọba.

“Wọn ba ni a tun imi ṣe, pe ki a lọ si ilu Eko lati lọ ṣe.

“Ayẹwo lo fi han pe ko si nnkan to jọ mọ pe emi ni mo ni ọmọ naa. Adajọ binu rẹpẹtẹ pe ko si itọna kankan pe mo ni nnkan kan pẹlu ọmọ naa, ti Adajọ si da wa lare.”

Nigba ti mo gbọ ẹsun ti wọn fi kan ọkọ, mo ni ko le ri bẹ laye- Iyawo Pasitọ

Arabinrin Dorcas A. Oladipupo ni omije jabọ loju oun lasiko ti oun ri ókọ oun ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa lori isẹ ti ko mọ wọ mọ ẹsẹ nipa rẹ.

“Ọkan mi bajẹ, mo ni layelaye, lati ọdun mọkandinlọgbọn ti a ti ṣe igbeyawo, n ko ka nnkan bayi lọwọ ọkọ mi.

“Mo sunkun nigba ti mo ri wọn ni ahamọ ti wọn fi wọn si sugbọn mo ni igbekẹle ninu ọkọ mi ti mo fẹ lo jẹ ki duro wi pe gbogbo ohun iyowu ti ka ba jẹ, irọ ni Satani pe.”

Igbagbọ ti emi ni wipe Pasitọ ko lo fun loyun- Alagbabọ Ọmọ to loyun

Arabinrin Cecila Olatunji ni oun gba ọmọ to ni oyun yii tọ lati gba to wa ni ọmọ ọdun mẹfa, ti oun si le gba ẹri rẹ jẹ pe ko ki n ṣe ọmọ to to n ri irinkunrin sugbọn ohun iyalẹnu ni ọrọ oyyun jẹ.

“Ọmọ yii, bi ọpọlọpọ ti n pariwo pe wọn n ba ọmọ yii sun, mo maa n ja pe irọ ni, ti ọmọ yii si mọ si

“Emi gab ni mo pe nigba ti mo ri pe o ti loyun amọ ko jẹwọ fun mi.

“Nigba to di ọjọ Aiku ni baba kan, o jẹ aburo baba wa, ransẹ si mi pe, wọn ba ni Pasitọ lo fun ọmọ loyun.

“Igbagbọ ti emi ni ni pe gbogbo bi wọn ṣe fi ẹsun kan Pasitọ, awọn kọ lo fun ọmọ naa loyun.

“Bibeli ni ka wadi ohun gbogbo dajudaju, ki a si di eyii ti ṣe ododo ati otitọ rẹ mu.