Jimmy Odukoya di pásítọ̀ ìjọ Fountain of life lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Jimmy Odukoya/Facebook
Oṣere Nollywood, Jimmy Odukoya ti di pasitọ agba ijọ Fountain of Life lẹyin iku baba rẹ, Taiwo Odukoya.
Lasiko ijọsin ọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan an ni pasitọ Rotimi Okpaise kede pe Jimmy ni igbimọ alaṣẹ ijọ naa yan.
Pasitọ Okpaise to kede ọrọ yii ṣalaye pe oloogbe Odukoya ti sọ ṣaaju iku rẹ pe ọmọkunrin rẹ Jimmy yoo di pasitọ agba ijọ ọhun ti oun ba dagbere faye.
Pasitọ naa fikun ọrọ rẹ pe Jimmy tun ni alaga igbimọ alaṣẹ ijọ Fountain of Life bayii yatọ si pe oun ni pasitọ agba ijọ naa.
O ni igbimọ alaṣẹ ijọ naa ti ya ọgbọnjọ oṣu kẹsan an sọtọ fun ayẹyẹ fifi Jimmy sori ijọ gẹgẹ bi pasitọ agba ijọ naa.
Ọjọ keje oṣu Kẹjọ ni oludasilẹ ijọ Fountain of Life, Pasitọ Taiwo Odukoya dagbere faye lorilẹede Amẹrika lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin.
O din diẹ ni ọdun meji si akoko iku rẹ ni o padanu iyawo rẹ keji, Nomthi eleyii to ku lọjọ kẹsan an oṣu kọkanla ọdun 2021.
Arun jẹjẹrẹ to ti ba a finra fun bii ọdun meji ni a gbọ pe o ṣeku pa a.
Ọdun mọkanla lawọn mejeeji fi jọ jẹ tọkọ taya ti Eleduwa si fi ọmọkunrin tawọn lọrẹ.
Bimbo Odukoya to ku ninu ijamba ọkọ ofurufu Sosoliso niluu Port Harcourt lọdun 2005 ni iyawo akọkọ pasitọ Odukoya.
Ọdun mọkanlelogun ni wọn fi jọ wa papọ gẹgẹ bii tọkọ taya ki Bimbo Odukoya to dagbere faye.















