Olùkọ kàn réè tó pàdánù akẹ́kọ̀ọ́ rẹ 32 nínú ìṣẹlẹ ilẹ́ riri

School bags and a chair in a school

Oríṣun àwòrán, Adaseel Schools

    • Author, Yassmin Farag
    • Role, BBC World Service

" Ero náà wa sí mi lọkan lati mu iwe ti wọn kọ orúkọ awọn ọmọ kilaasi mi sí ti mó si bẹrẹ sí ní fa ila sí orúkọ wọn lọọkọọkan titi ti ko fi orúkọ kankan to sẹku nínú awọn mẹtalelọgbọn.Gbogbo wọn lò ti ku bayii"

Nesreen Abu ElFadel, olùkọ ede larubawa ati Faransé ni Marrakech lo n sọ nípa iriri rẹ lọjọ to sare lọ sí abúlé rẹ Adassel tó wa lagbegbe ori oke nla Atlas.

O lọ sibẹ lati lọ wa awọn akẹkọọ rẹ lẹyìn ti ilẹ riri nlá kan ti iwọn agbara rẹ tó 6.8 kọlù agbegbe ọhun.

Ita ni Nasreen ati Iya rẹ sùn sí lalẹ lẹyìn ilẹ riri ọjọ Ẹti kì iroyin iru akoba ti ilẹ riri naa ṣe l'awọn abule ori oke dé si eti igbọ rẹ.

Kia lọkan rẹ lọ sọdọ awọn akẹkọọ ilẹ ẹkọ to ti n ṣiṣẹ iyen ile eko Adassel ati awọn akẹkọọ to fẹràn láti maa pé ní awọn ọmọ mi.

O ní "mo lọ sí abule tinko sí bẹrẹ sí ní beere awọn ọmọ mi-nibo ni Somaya wa?Youssef nkọ?Lagbaja nkọ tamẹdun náà nkọ? Esi ibeere mi de ni wakati diẹ.Gbogbo wọn lò ti ku"

Awọn akẹkọọ n ka iwe ni yara ẹkọ

Oríṣun àwòrán, Adaseel Schools

Àkọlé àwòrán, Nesreen sapejuwe awọn akẹkọọ rẹ ki isẹlẹ naa to waye- gẹgẹ bi "Angẹli."

Lọjọ kẹjọ oṣù Kẹsán ni ilẹ riri to lagbara julọ ninu akọsilẹ kọlu orilẹ-ede naa.

Ohun lo lagbara julọ lati nkan bí ọgọta ọdun sẹyìn ti wọn sì tí rí pé eeyan ẹgbẹrun mẹta ti kù tí àìmọye sí dawati.

Àwọn agbègbè to ba julọ l'awọn to wa ni guusu Marrakech nibi t'awọn abule ori oke ti parẹ patapata.

Ọkan lara awọn akẹkọọ to ku ti Nesreen rí oku rẹ a máà jẹ Khadija.

Wọn rí oku ọmọ ọdún mẹfa yi lẹgbẹ ọmọ iya rẹ ọkunrin Mohammed ati awọn ọmọ iya rẹ obinrin meji Mena ati Hanan.

Ori ibusun ni gbogbo wọn ku sí lasiko ilẹ riri naa.

Ile ẹkọ Nesreen ni gbogbo wọn tí n kẹkọọ.

"Khadija ni mo fẹran julọ.O já fáfá,o lọyaya o sí fẹràn lati maa kọrin.O máa n wa sí ìlé mi mo sí fẹràn lati maa ba sọrọ"

Nesreen ṣe iranti awọn ọmọ rẹ gẹgẹ bi angẹli kekere, ọmọ to ni itẹriba tí wọn sì nifẹ sí kíkọ ẹkọ.

Toun ti bi nkan kò ṣe rọgbọ awọn ọmọ yi ati awọn obi wọn ri lilọ sí ile ẹkọ gẹgẹ bi "ohun tó pataki julọ lagbaye."

Nesreen ṣe iranti pe" lọjọ Ẹti la ṣe kilaasi ìkẹyìn wa ni nkan bí wakati marun ùn gerege ki ilẹ riri yi to sẹlẹ "

"Ohun táa kọ nipa rẹ ni orin akọmọna Morocco táa sí gbero lati kọ orin yi niwaju gbogbo ile ẹkọ ni ọjọ Aje tó n bọ"

'No sleep'

Ile ẹkọ to bajẹ
Àkọlé àwòrán, Ile ẹkọ ti Nesreen ti n sisẹ ni ọpọlọpọ ijamba de ba lasiko isẹlẹ naa
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Toun ti bi ohun rẹ ko ṣe gbọn, ọgbẹ ọkàn ṣi n daamu Nesreen.

Ko yi ribi f'ọkan ro ohun to mu k'awọn akẹkọọ rẹ wà nínú ijamba nla yi.

O sọ pe "Mi o ri orun sun.O si n ṣe mi bi ala."

"Àwọn eeyan n wo mi bi ọkàn lara awọn ti ori ko yọ ṣugbọn mi o mọ bi mo ṣe lè máa gbe ile ayé "

Nesreen nifẹ sí kíkọ àwọn ọmọde ni ede larubawa ati Faransé ni Adaseel abule kan ti o kún fún awọn èèyàn ẹyà Amazigh tí wọn sọ ede tí wọn ìyẹn Tamazight.

"Ede larubawa ati Faransé ṣòro ni kikọ ṣugbọn awọn ọmọ yi ni làákàyè ti wọn a sí maa sọ ede mejeeji daradara."

Nesreen n gbero lati tẹsiwaju nidi iṣẹ olùkọ.

Ọ lohun ni ireti pé wọn yoo tun ile ẹkọ Adaseel to wo ninu ilẹ riri yi kọ padà.

Ile ẹkọ 530 lo farakasa lorisirisi ninu ìṣẹlẹ ilẹ riri yi.

Awọn kan wo patapata tàwọn mii sí wo lẹgbẹ kan gẹgẹ bi awọn alaṣẹ tí ṣe sọ .

Ìjọba Morocco ti dawọ ẹkọ kíkọ duro fún ìgbà díẹ láwọn agbegbe Al-Houz, Chichaoua ati Taroudant to faragba ìṣẹlẹ yi julọ.

Nasreen sọ pe " boya lọjọ kan tí wọn ba tun ile ẹkọ yi kọ padà táa sí padà sẹnu iṣẹ boya a o ṣe iranti awọn ọmọde mètalelógbọn to ku táa sí so nipa itan wọn "