Èèyàn tótó 20,000 lo ti jáde láyé lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ Omíyalé

Aworan bí omiyale ṣe waye ni Libya

Eeyan toto ẹgbẹrun lọna Ogun lo ti padanu emi wọn lẹyin ijamba omiyale to waye lorilẹede Libya.

Iṣẹlẹ omíyale lo sọ sẹ ni apa ila oorun orilẹede Libya lọjọ Aiku.

Olori agbegbe Derna sọ fun Ileeṣẹ momaworan Saudi, Al Arabiya pe o to eeyan ẹgbẹrun lọna mejidiogun si ogun to jade laye lẹyin ti ile omi ja, to si fa ọpọlọpọ ijamba lasiko ti awọn eeyan n sun.

O ni iye awọn eeyan to jade tí oun darakọ lo wa lati awọn agbegbe ti iṣẹlẹ naa ṣe kọlu si.

Ọpọlọpọ oku awọn eeyan lo wa ni abẹ omi to si fa aisan ni awọn agbegbe naa.

Bakan naa ni ni awọn ẹgbẹ alatako ni Libya n pe fun Iranlọwọ lọwọ ajọ agbeye.

Àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ omiyalé lọ ní Libya tí lè ní 5300-Mínísítà

Aworan eeyan kan to di alainilelori nitori omiyale Libya

Oríṣun àwòrán, Reuters

O ti le ni ẹgbẹrun marun un oku awọn eeyan ti wọn ri bayi ni agbegbe Derna ti iṣẹlẹ omiyale ti ṣẹlẹ ni Libya.

Minisita kan lagbegbe ila oorun orileede naa lo sọ bẹ fun ileeṣẹ iroyin Reuters.

Hichem Abu Chkiouat sọ pe o ṣeeṣe ki iye awọn to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa lọ soke ju iye to wa bayii,koda o lo le lekun ni ilọpo meji.

Igbimọ to n risi eto idoola ẹmi lagbaye International Rescue Committee sọ pe niṣe lawọn ileewosan kun fọfọ lagbegbe ila oorun Libya.

Wn ni wọn n gbe awọn eeyan kan lọ si awọn ilu mii lọ gba itọju ṣugbọn pẹlu bi pipe lori foonu ti ṣe nira tawọn oju ọna naa si bajẹ,niṣe lo nira lati ribi doola ẹmi awọn eeyan.

Eli Abouaoun to jẹ oludari igbimọ ẹlẹyinju aanu yi ni Libya sọ pe ''Awọn ọkọ to n gbe alaisan nilo atunṣe,riri awọn eeyan gbe ati awọn nkan eelo miran n jẹ ki iṣẹ awọn to n doola eeyan nira lati de ibi ti wọn nilo wọn.''

O fikun pe ''ọkan ko balẹ lori pe o ṣeeṣe ki awọn aisan to n tara omi wa le ti gbalẹ taa si ni mọ''

Ìṣẹ̀lẹ̀ omiyalé àti ìjì líle kọlu Libya, èèyàn 1,000 bá omi lọ
Libyan floods

Oríṣun àwòrán, getty

O kere tan, wọn ti ṣawari oku ẹgbẹrun kan eeyan lẹyin iṣẹlẹ omiyale to waye lagbegbe Derna, lorilẹ-ede Libya.

Ọkan lara awọn aṣoju ijọba orilẹ-ede naa ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe “ọkẹ aimoye ni oku awọn to sun nilẹ.”

Pupọ ninu agbegbe Deran, ti nnkan bii ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan n gbe lo ti wa labẹ omi bayii lẹyin ti awọn afara kan dawo, ti adagun omi si faya.

Ajọ adoola ẹmi Red Cross sọ pe lọwọ yii, nnkan bii ẹgbẹrun mẹwaa eeyan lo ti di awati lẹyin ti iji lile Storm Daniel ṣẹlẹ.

Ọjọ Aiku ni iji lile naa waye, to si ṣọṣẹ pupọ lawọn ilu bii Benghazi, Soussa ati Al-Marj.

Minisita fun irinna ọkọ ofurufu, Hichem Chkiouat sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe “Iye oku ti a ti ri bayii ti le ni 1,000.”

“Mi o parọ rara ti mo ba sọ pe nnkan bii ida 25% ilẹ wa lo ti ba omi lọ, ọpọ ile lo si ti dawo.”

Tamer Ramadan, to jẹ olori Red Cross ni Libya naa sọ fun awọn akọroyin pe “o ṣeeṣe ki awọn ti yoo ku pọ ju iye ti a lero lọ.”

“Awọn eeyan wa ti wa ni ikalẹ bayii ti wọn n ṣe iwọn ti wọn le ṣe... bo tilẹ jẹ pe a ko tii mọ iye awọn eeyan to sọnu ṣugbọn nnkan bii ẹgbẹrun mẹwaa eeyan ni a ṣi n wa.”

Ṣaaju ni minisita fun agbegbe ila oorun, Osama Hamad, sọ pe ẹgbẹrun meji eeyan lo jade laye.