Naira Marley fọhùn lẹ́yìn ọjọ́ kẹ́ta tí Mohbad jáde láyé

Aworan Mohbad ati Naira Marley

Oríṣun àwòrán, MOHBAD/INSTAGRAM/NAIRA MARLEY/TWITTER

Ọga agba fun ileeṣẹ orin Marlian, Onkọrin Azeez Fashola ti ọpọ mọsi Naira Marley ti sọrọ sita lẹyin ọjọ kẹta ti ọkan lara ọmọ lẹyin rẹ tẹlẹ, Ilerioluwa Alob, ti ọpọ mọ si Mohbad jade laye.

Mohbad, ẹni to jade laye lọjọ Isẹgun ni ọrọ nipa iku rẹ ti fa ọpọlọpọ awuyewuye lori ayelujara.

Naira Marley, ninu atẹjade to di oju opo ayelujara Instagram rẹ lowurọ ọjọ Satide pe fun iwadi oni kiakia lori iku Mohbad.

O ni iku Mohbad jẹ ohun ti ba gbogbo eeyan ninu jẹ, ti ọpọ si gbọdọ di de lati ṣe iwadi lori iku to pa.

“Bi a n ṣe n kẹdun lori iku Mohbad, a n pe fun iwadi to kuna lori ohun to dirọ mọ iku Mohbad.

“Inu wa ko dun si bi nnkan se n lọ lati ọjọ Isẹgun ti Mohbad ti jade laye.

“Eeyan wa ko lẹtọ si bi eto isinku rẹ ṣe lọ.”

'Ti a ba n ja, bi ka ku kọ'

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Naira Marley salaye pe Mohbad jẹ ọkan lara onkọrin to ko ipa ribiribi ninu idasilẹ Ileeṣẹ orin Marlians

Lati igba ti Mohbad ti ku ni ọpọlọpọ ti na ika alebi si Naira Marley ati awọn mii pe wọn lọwọ ninu iku rẹ.

Naira Marley salaye pe otitọ ni pe Mohbad kuro ni Marlian sugbọn oun sin n se igbe larugẹ fun oye orin kikọ rẹ.

“Ko si mọlẹbi to dara, mọlẹbi maa n ja sugbọn bi ka ku kọ. Ọpọlọpọ nnkan lo waye sugbọn ti a ko le sọ nitori ifẹ ti a ni si ara wa.

“Ko ki n ṣe Marlian nikan lo padanu Mohbad, gbogbo wa ni kaakiri agbaye.

Bakan naa ni Samson Erinfolami Balogun ti ọpọ mọ si Sam Larry, tọ jẹ ọrẹ timọtimọ fun Naira Marley, ninu fọnran kan to gbe sita salaye pe bi aburo ni Mohbad jẹ si oun ti oun si nifẹ rẹ pupọ.

Sam Larry ni Ọlọrun ri inu oun pe oun ko mọ ohunkokun nipa iku Mohbad

O kú ọjọ́ méjì tí Mohbad yóò jáde láyé, mo làlá burúkú kan - Baba Mohbad

Aworan Baba Mohbad

Oríṣun àwòrán, @og_baba1

Baba Ilerioluwa Oladimeji Ayoba, olorin takasufe ti ọpọ mọ si Mohbad,to di oloogbe, Joseph Ayoba ni oun lala buruku ni o ku ọjọ meji ti ọmọ oun jade laye.

Mohbad jade laye lọjọ Isẹgun, ti wọn si gbe wọ kaa ile sun niluu Ìkorodu.

Pẹlu ibanujẹ ni Baba rẹ fi ba akọroyin @og_baba1 sọrọ, to si se apejuwe ibasepọ rẹ pẹlu Mohbad gẹgẹ ọrẹ timọtimọ.

O salaye akọkọ igbẹyin to ni pẹlu pẹlu ọmọ rẹ, o ni awọn jọ jẹun papọ lọjọ Satide to kọja nigba to ṣe abẹwo si.

"Ọrẹ mi ni Mohbad. Mo maa pe ni Oladimeji, to rí pe o jẹ ẹnikeji mi nitori emi nìkan ni awọn obi mi bi. A sumọ arara gan.

"Ọjọ ti mo rí gbẹyin to jẹ Satide to kọja, mo lọ si ile Mohbad, ti a si jọ jẹun papọ.

"Nigba ti mo n lọ, o fun mi lọwọ gẹgẹ bi o ṣe ma fun mi ni gbogbo igba."

Nigba to n sọrọ nipa ala to ni ki Mohbad to jade laye.

"Mo ni ala nípa Mohbad ni o ku ọjọ meji ti iṣẹlẹ naa yoo waye. Ninu ala naa, mo ri ẹnikan to fẹ yin mi ni Ìbọn sugbọn mo yẹ fun ibọn naa lia mọ pe nnkan bayi yoo sẹlẹ si mi.

Lori ohun to sokunfa iku ọmọ rẹ, o ni,

"Gẹgẹ bii nnkan ti mo gbọ lẹnu awọn eeyan, nnkan ti n ko gbagbọ ni pe nọọsi akọsẹ lo fun ni abẹrẹ."

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìnira ní Mohbad là kọjá kò tó jáde láyé - Ìyàwó

Aworan Mohbad àti Iyawo rẹ, Wunmi

Oríṣun àwòrán, Instagram/ _c33why

Iyawo Ilerioluwa Oladimeji Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad ti salaye pe ọkọ oun la ọpọlọpọ nkan kọja ko to di pe ọlọjọ de.

Omowunmi to jẹ ẹni ọdun merinlelogun ni iyawo Mohbad to tu kẹkẹ ọrọ loju ọpọ ayelujara Instagram lẹyin iku ọkọ rẹ.

O salaye pe ọpọlọpọ inira ni Mohbad ni, to si jẹ pe awọn kan tun dunkooko mọ titi to fi jade laye.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Instagram/_c33why_

"Wọn pe e ni ọpọlọpọ orukọ. Wọn ní pe o ti yawere.

"O ti ku bayii, gbogbo yin ti ye ge, ẹ wa gba ami ẹyẹ".

O ni ibanujẹ lo jẹ fun oun lati di opó ni ẹni ọdun mẹrinlelogun, to ke si Ọlọrun lati ja fun.

Wunmi ni ko si nkankan to mu inu Mohbad dun mọ.

O ni lẹyin to ri ọmọ bibi inu rẹ, ironu rẹ tun pọ si nitori ko fẹ ki aburu sẹlẹ si iyawo ati ọmọ rẹ.

'Ọmọ wa sẹsẹ pe ọmọ oṣu marun un'

Omowummi ni ọjọ ti ọmọ Mohbad pe ọmọ oṣu marun un ni Mohbad jade laye.

O sọ eleyi lori opo ayelujara nibi to fi ọpọlọpọ fọnran ati aworan sita lati sọ nípa irinajo rẹ pẹlu Mohbad.

"Oni ni Laim pe ọmọ oṣu marun un, nibo ni ki n ti bẹrẹ.

"Ẹ gba mi, n ko le da eleyi ṣe.

A ni ọpọlọpọ afojusọn, ẹru eeyan meji ti di ti eeyan kan.

"Mo sa gbogbo ipa mi lati ma jẹ ki o lọ Ilerioluwa."