Ọlọ́pàá pinnu ìwádìí kíkún lórí ohun tó ṣòkùnfà ikú Mohbad

Aworan ami idanimọ ọlọpaa ati Mohbad

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti fi da mọlẹbi ọrẹ ati awọn ololufẹ olorin takasufe nii to jade laye Ilerioluwa Oladimeji Aloba pe awọn yoo ṣe iwadii kikun lori ohun to ṣokunfa iku rẹ.

Ilerioluwa ti ọpọ eeyan mọ si Mohbad jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ti ọpọ awuyewuye si n tọ iku rẹ.

Lọjọ Iṣẹgun lawọn to n dari eto fun olorin naa kede iku rẹ.Ninu atẹjade ti wọn fi sita, wọn sọ pe''Imole ti wa nipo ifọkanbalẹ bayii''

Amọ kaakiri oju opo ayelujara lawọn ọmọ Naijiria ti n beere pe ki gaan lo ṣokunfa iku ilumọọka olorin yi?

Niṣe ni awuyewuye orisi n tọ iku rẹ tawọn kan si n sọ pe oju lasan kọ ni iku rẹ yi.

Bẹẹ lawọn kan n kesi ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iwadii nipa ohun to ṣokunfa iku Mohbad ni paapa idunkoko tawọn kan ṣe si ẹmi rẹ ṣaaju ko topada jaye laye.

Atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi soju opo X lati ọwọ alukoro agba ileeṣẹ ọlọpaa Muyiwa Adejobi ṣalaye pe awọn ti paṣẹ ki Kọmiṣana ọlọpaa nipinlẹ Eko tọ pinpin ọrọ yi.

Wọn ni bi nkan ba ṣe n lọ lawọn yoo ma fi to araalu leti.

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa Eko sọ pe awọn mọlẹbi Ilerioluwa Oladimeji Mohbad ko fi ọrọ iku rẹ to awọn leti.

Agbẹnusọ ọlọpaa SP Benjamin Hundeyin sọ fun BBC pe titi di ọjọ Kẹrinla oṣu Kẹsan mọlẹbi ko sọ nkankan nipa iku ọmọ wọn.

Hundeyin sọ pe o yẹ ki wọn ti fi iku rẹ to awọn leti pẹlu bi ọrọ ti ṣe ri nipa iku rẹ.

Lọjọ Kejila ni Mohbad jade laye ti iroyin iku rẹ si gbode kaakiri oju opo ayelujara ki awọn alakoso rẹ to wa jade sita tu ọfọ rẹ.

Wọn fi ikede wọnyi sita ninu atẹjade kan loju opo wọn ni Twitter taa mọ si X nipa ikanni olorin naa official Twitter page, @iammohbad_.

''Pẹlu ibanujẹ la fi kede ọrọ iku Promise Aloba AKA Mohbad lonii tii ṣe ọjọ kejila oṣu Kẹsan ọdun 2023''

Tohun ti ikede yi,ọrọ yi ṣokunkun nipa ohun to ṣokunfa iku Mohbad.

Ẹwẹ iku olorin yi n fa awuyewuye loju opo ayelujara tawọn eeyan si n naka alebuu sawọn ti wọn fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu iku Mohbad.

Amọ ṣa baba to bi Mohbad, Joseph Aloba ninu fọnran ifọrọwerọ to ṣe pẹlu oju opo kan sọ pe oun ko fura si ẹnikankan pe o lọwọ ninu iku ọmọ rẹ.

Bẹẹ naa lo sọrọ nipa igba ikẹyin to wa pẹlu ọmọ rẹ .

O ni lọjọ Abamẹta to kọja loun ati ọmọ rẹ jijọ wa papọ nigba toun lọ ṣabẹwo si.

''O gbe ounjẹ fun mi.Koda oun lo gbe ounjẹ naa si mi niwaju.Nigba ti mo fẹ ẹ pari ounjẹ naa, o sunmọ mi taa si jijọ bẹrẹ si ni jẹ ounjẹ naa pọ.Mo sọ fun pe mo ti n pada sile to si fun mi ni owo bo ṣe maa n fun mi''

Ẹkún, ìdárò bí Mohbad ṣe wọ káà ilẹ̀ sùn

Aworan ibi tí wọn sin Mohbad si

Oríṣun àwòrán, Twitter

Pẹlu omije ni agbaagba ati awọn ọdọ to peju sibi eto isinku Mohbad fi ṣe idaro lẹyin to wọ kaa ilẹ lọ nílùú Ikorodu.

Mohbad, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn lo jade laye lọjọ Kejila oṣu kẹsan an.

Ọpọ ero lo peju sibi eto sinkun olorin takasufee yìí, ti wọn si n kọrin ibanujẹ kíkankíkan ni ile itẹ oku si niluu Ìkorodu.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Bakan naa ọpọ eeyan ti bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe sin oku Mohbad lai ṣe ayẹwo lati mọ irufẹ nnkan to ṣekupa.

Ṣaaju ni ileeṣẹ iroyin kan, Pulse NG ni aarun eti lo ṣekupa Mohbad.

Gẹgẹ bii Pulse NG ṣe ṣalaye, Mohbad, gbera lọ ile iwosan lọjọ Isẹgun to si jade lẹyin to gba abẹrẹ ni ile wosan naa.

Ileeṣẹ BBC ko ti le fidi rẹ mulẹ ohun pato to ṣekupa Mohbad.

Oloogbe fi iyawo ati ọmọ silẹ laye.

Kí ló wà láàrin Mohbad àti Naira Marley?

Aworan Mohbad àti Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mohbad

Lọdun 2022, Ilerioluwa Oladimeji ti ọpọ mọ si Mohbad pariwo síta pe ti oun ba ku, ki wọn di Ọga rẹ, Naira Marley ati awọn ọmọ lẹyin rẹ mu.

Mohbad jẹ ọkan lara ọmọ lẹyin gbajugbaja olorin takasufe, Azeez Fashola ti ọpọ si Naira Marley.

Ede ayede waye laarin Naira Marley ati Mohbad, ti ipinya si waye lọdun to kọja.

Ninu fọnran kan to wa lori ayelujara ni Mohbad ti pariwo síta bẹẹ lẹyin to kuro ni ahamọ ajọ NDLEA.

O ni awọn ọmọ ẹgbẹ Marlians n gbero lati ṣekupa oun lẹyin to kuro ni ahamọ.

"Wọn ti n se ohun buruku si mi, mo fẹ le yawere lori ọrọ yii, ní bayi wọn fẹ pa mi.

"Gbogbo agbaye, ẹ gbami o, ti mo ba ku, Naira Marley ati Marlians lo pa mi."

Ọpọlọpọ eeyan lo ti bẹrẹ si ni bere ibeere lẹyin ti Mohbad jade laye lana.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Olamide, Tacha àti àwọn olórín takasufe ṣé ìdárò lẹ́yìn Mohbad

Gbajugbaja olorin takasufe bi Olamide Adedeji tí ọpọ mọ si Olamide ati awọn olorin mii bi M.I, Burna Boy ti ṣe idaro lẹyin Mohbad to di oloogbe lana.

Irọlẹ ana iroyin nipa iku Mohbad gba ori ayelujara, to si ba ọpọlọpọ ninu jẹ.

Bakan naa ọpọ awọn ololufẹ Mohbad ni wọn tu sita lori ayelujara lati se idaro ẹni to lọ.

Mohbad jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3

Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa olórin tàkasúfèé, Mohbad

MOHBAD

Oríṣun àwòrán, MOHBAD

Iroyin to n lọ nigboro bayii ni pe Ilerioluwa Oladimeji Aloba, ti ọpọ eeyan mọ si MohBad, ti jade laye.

Oniṣowo orin, Ovie, lo kede iku rẹ loju opo X rẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun.

Olamide tun wa lara awọn olorin to ti n daro rẹ.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 4

Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Mohbad ree

Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 1996 ni wọn bi Ilerioluwa Oladimeji Aloba.

Orukọ ti ọpọ eeyan mọ olorin naa si kaakiri agbaye ni Mohbad.

O jẹ olorin takasufe, o tun maa n kọ orin silẹ funra rẹ tabi fun awọn olorin miran bii tirẹ.

Abẹ asia ileeṣẹ Naira Marley, iyẹn Marlian Records lo wa tẹlẹ ko to kuro labẹ asia ileeṣẹ naa lọdun 2022.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 5

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lara awọn orin rẹ to milẹ titi julọ ni Ponmo, Feel Good, ati KPK ‘Ko Por Ke,’ eyii to gbe jade pẹlu Rexxie, ti wọn si fa kalẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn orin to ta lẹnu julọ fun ami ẹyẹ Headies lọdun 2022.

Ọdun 2020 lo kọkọ gbe awo orin rẹ ‘Light EP’ jade lẹyin orin rẹ ‘Ponmo’to milẹ titi, eyii to ṣe pẹlu Naira Marly ati Lil Kesh.

Lọdun 2021, o wa lara awọn olorin ti awọn eeyan gbọ julọ lori Audiomack ni ẹka orin Afrobeat.

O wa loke tente tabili TurnTable lọdun 2021, o tun gbiyanju bakan naa lọdun 2022.

Ninu oṣu keji ọdun 2023, ajọ to n gbogun ti egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA, mu oun, Zinoleesky atawọn olorin mii lẹyin ti wọn ka oogun oloro igbo mọ wọn lọwọ nile kan to wa lagbegbe Lekki, niluu Eko.

Lọjọ karun un, oṣu Kẹwaa, ọdun2022, Mohbad fẹsun kan Naira Marly pe o maa n lu oun nilu bara, o tun n ran awọn eeyan kan si oun pe ki wọn maa na oun, o tilẹ sọ nigba naa pe ti ounkohun ba ṣẹlẹ si oun, ọwọ Naira Marley ni ki awọn agbofinro atawọn ẹbi oun ti bere.