Ìdí rèé tí mo fi wa lórí 'Wheelchair' tí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń gbàdúrà fún mi - Saidi Balogun

Saidi Balogun joko lori kẹkẹ onirin

Oríṣun àwòrán, SAidi Balogun Instagram

Laipẹ yìí ni àwòrán kan gbà orí ayélujára kan, èyí tó ṣe àfihàn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Saidi Balogun, tó jókòó sórí kẹ̀kẹ́ onírin tó wà fún àwọn eeyan ti ẹsẹ n dùn.

Àwòrán yìí sí lọ dá ọkàn àwọn èèyàn tó wòó láàmú, pàápàá àwọn olólùfẹ́ rẹ.

Ọ̀pọ̀ wọn sì lọ ń fi ìtara pèé lórí fóònù tàbí fi atẹjisẹ ránṣẹ́ sì, bí wọn ṣe ń béèrè pé kí lo faa, tí Saidi Balogun ṣe di èrò orí kẹkẹ onírin, naa ni wọn ń gbàdúrà fún pé Ọlọ́run yóò fún ní àlàáfíà.

Èrò ọpọ wọn ní pe ijamba kan ló wáyé, tí gbajúmọ̀ òṣèré náà kò ṣe leè rìn bo se yẹ, tó sì ń fi kẹkẹ onírin ṣe ẹsẹ rìn.

Esi wo ni Saidi Balogun fọ lori bo se wa lori kẹkẹ onirin?

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Èyí sì lo mú kí Saidi Balogun ṣe tete ṣàlàyé fáwọn olólùfẹ́ rẹ náà, ìdí tó ṣe ń lọ kẹkẹ onírin láti rìn.

Saidi Balogun, nínú fídíò tó gbé soju òpó Instagram rẹ ṣàlàyé pé kò sí ìjàmbá kankan tó ṣe òun, ko ko ko si ni ara òun le.

O ni ère sinima ni àwọn n ya lọwọ lásìkò tí òun jókòó sínú kẹkẹ onírin naa n ìbámu pẹ̀lú ipa tí òun kò nínú sinima àgbéléwò náà.

Koda, ṣe ni Saidi ń fò sókè, tó sì na apa àti ẹsẹ rẹ láti fi dá àwọn olólùfẹ́ rẹ lójú pé saka ni ara òun da

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà náà wá ń kilọ fáwọn èèyàn tó ń gbé ayédèrú ìròyìn kiri lórí ayélujára pé kí wọn ṣọ́ra, kí wọn sì dẹkùn ìwà aláìdára yìí.

Bákan náà lọ wà fi ẹ̀mí imoore rẹ hàn sáwọn olólùfẹ́, ebi, ara, ọrẹ àti ojulumọ tó kàn sí lásìkò tí wọn rí àwòrán náà, tí wọn sì ń gbàdúrà fún.