Kí ni Akeredolu rí tó fi ṣe àgbékalẹ̀ ìjọba ìbílẹ̀ 33 tuntun?

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi
Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu, lo ti buwọlu ofin to ṣe idasilẹ oriko iṣejọba ibilẹ mẹtalelọgbọn tuntun nipinlẹ naa.
Akeredolu sọ abafofin naa di ofin ni ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹsan oṣu kẹsan ọdun yi, lẹyin ọjọ meji to pada si orilẹ-ede Nigeria lati ilẹ Germany to ti lọ gba itọju fun oṣu mẹta.
Gomina naa ni abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ Ondo, Olamide Oladiji, atawọn adari ile to ku lọ fun ni abadofin naa lati buwọ luu nilu Ibadan nibi ti o ti n gba alejo lati igba to ti pada si orilẹ-ede yi.
Bo tilẹ jẹpe awọn ara ilu kan atawọn ajọ kan ti yonbo gomina lori idasilẹ awọn ijọba ibilẹ tuntun naa, ọpọ awuyewuye lo ti waye sẹyin lori ọrọ ọun ki gomina too fi ọwọ sii.
Níbo ni ọ̀rọ̀ ìdásílẹ̀ ìjọba ìbílẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀
Ni ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹta, ọdun 2019 ni gomina Akeredolu gbe igbimọ ẹlẹni mọkanla kan kalẹ lati wo bi ipinlẹ naa yoo ṣe ni awọn ijọba ibilẹ tuntun yatọ si mejidinlogun ti o ni tẹlẹ.
Botilẹ jẹ pe ofin orilẹ-ede Nigeria ko nii da awọn ijọba ibilẹ tuntun yi mọ, Akeredolu to jẹ amofin agba to si tun fi igba kan ri jẹ aarẹ ẹgbẹ agbẹjọro lorilẹ-ede yi, wi pe idasilẹ awọn ijọba ibilẹ tuntun naa ti ko gba oore-ọfẹ ijọba apapọ ni yoo jẹ ki ijọba awa-arawa o le de awọn igberiko ati ẹsẹkuku.
Akeredolu fi kun pe “ohun ti awọn eeyan wa n fẹ la fẹẹ ṣe fun wọn. Eleyi ko ni ọrọ oṣelu ninu rara. Ki awọn eyan wa o le yan aṣoju to sunmọ wọn ki iṣejọba o si le kari ni a ṣe gbe igbesẹ yi”.
Kete ti Akeredolu ṣe ifilọlẹ igbimọ naa ni alaga igbimọ ọun, Ọmọọba Lanke Odogiyan, ti kede pe ki awọn araalu o maa fi iwe apinlẹkọ wọn ranṣẹ ti wọn ba fẹẹ ki ijọba o boju wo agbegbe wọn fun ijọba ibilẹ tuntun.
Lẹyin ọsẹ bii mejidinlogun ti wọn ti rin kaakiri origun mẹrẹẹrin ipinlẹ Ondo, igbimọ ẹlẹni mọkanla naa jabọ iṣẹ wọn fun gomina ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu keje, ọdun 2019, ti wọn si wipe awọn gba iwe apinlẹkọ mẹrinlelaadọrun (94) ti awọn araalu fi beere fun ijọba ibilẹ tuntun marundinlaadọfa (105).
Gomina Akeredolu dupẹ gidi lọwọ igbimọ naa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe to si wipe oun ko nii jẹ ki gbogbo akitiyan igbimọ naa o ja si ofo.
Ninu ọrọ rẹ lọjọ naa, gomina Akeredolu ṣeleri pe ijọba oun yoo boju wo esi igbimọ naa ti awọn ijọba ibilẹ tuntun naa yoo si di dida silẹ lẹyin oṣu diẹ.
Ẹwẹ, lẹyin ọdun mẹrin ni awọn araalu too gbọ nkankan nipa idasilẹ awọn ijọba ibilẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Ray Adekunle
Orúkọ àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tuntun jáde àmọ́ ìjọba ní irọ́ ni
Lẹyin ọdun mẹrin ti gomina Akeredolu ṣe ileri pe oun yoo ṣe idasilẹ awọn ijọba ibilẹ tuntun lakoko to n tẹwọ gba abajade iwadi igbimọ ẹlẹni mókanla ti o gbe kalẹ lori ọrọ naa ni awọn araalu too gbọ ohunkohun nipa rẹ.
Ọsan ojọ kẹtadinlọgbọn oṣu keje, ọdun 2023 ni kọmiṣọna f'eto iroyin n'ipinlẹ Ondo, Bamidele Ademola-Olateju, sọ fun awọn akọroyin lẹyin ipade igbimọ iṣejọba ipinlẹ naa pe awọn ti boju wo idasilẹ ijọba ibilẹ tuntun ti awọn si ti gbe igbesẹ ti o tọ lee lori.
Ademola-Olateju wi pe “ninu ipade wa loni, a ti fi ọwọ si idasilẹ ijọba ibilẹ tuntun mẹtalelọgbọn. Eyi yoo jẹ ki gbogbo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ondo o di mọkanlelaadọta.
“Ki awọn ijọba ibilẹ tuntun yi o le jẹ ojulowo, a ti fi iwe ṣọwọ si ile aṣofin ipinlẹ yi ki wọn le sọọ di ofin ti yoo fidimulẹ.”
Lẹyin ọjọ marun ti kọmiṣọna f'eto iroyin kede ọrọ yi ni awọn orukọ kan gba ori ẹrọ ayelujara gẹgẹ bii orukọ awọn ijọba ibilẹ tuntun naa.
Eyi lo fa oniruuru ariwo lati ọdọ awọn ti ijọba ibilẹ tuntun naa ko ri bi wọn ṣe fẹ.
Amọ ki ilẹ ọjọ naa too ṣu, kọmiṣọna fun eto idajọ nipinlẹ naa, amofin Charles Titiloye, kede pe ayederu ni awọn orukọ ori ẹrọ ayelujara naa nitori pe ijọba ko tii fi awọn orukọ naa lede.
Titiloye wi pe “o di igba ti ile aṣofin ipinlẹ ba joko lori awọn orukọ ati agbeegbe ti awọn ijọba ibilẹ tuntun naa yoo wa, ti wọn si sọọ di ofin ki a to le gbe awọn orukọ naa jade.
“A rọ awọn araalu lati ma ṣe jẹ ki awọn ọbayejẹ tan wọn jẹ nipa awọn ayederu orukọ yii, amọ ki wọn duro di akoko ti ijọba yoo fi awọn orukọ naa lede lọna ti o tọ.”
Àwọn ìlú kan tako LCDA tí ìjọba fún wọn
Bo tilẹ jẹ pe ọrọ ti kọmiṣọna feto idajọ sọ nipa awọn orukọ ori ẹrọ ayelujara naa mu ki awuyewuye lọlẹ diẹ, ọpọ idarudapọ lo waye lọjọ ti ile aṣofin ipinlẹ naa pe awọn araalu lati wa sọ nipa awọn ijọba ibilẹ tuntun naa.
Awọn olugbe ijọba ibilẹ Ẹsẹ-odo ni wọn ti bẹrẹ ifẹhonuha ni gbọngan ti awọn aṣofin naa fẹẹ lo pẹlu oniruuru iwe ti wọn fi n rọ awọn aṣofin naa lati yọwọ ninu fi fi ilẹ wọn tọrẹ fun ilu miran.
Kalasuwei ti ilẹ Apoi to jẹ ọkan lara awọn ọba alaye onipo kini nipinlẹ Ondo, Ọjọgbọn Sunday Amuseghan, ati Pere Zaccheaus Doubra Egbunu, Agadagba ti Arogbo-Ijaw, wi pe wọọdu idibo meji nijọba ibilẹ Ese-odo ni yoo di ti ijọba ibilẹ Ilaje ati Irele labẹ ijọba obilẹ tuntun ti wọn fẹẹ da silẹ naa.
Wọn waa fun ijọba ni ọjọ mọkanlelogun lati ṣe ayipada ti o tọ ti ijọba ko ba fẹ ki wọn fi ija gba ilẹ naa pada.
Bakan naa ni laasigbo diẹ waye ninu gbọngan naa lakoko ti awọn ọdọ kan lati ilu Akure tako Iralepo Isikan lakoko to fẹẹ sọrọ bi wọn se ni awọn ko nii fi aye gbaa lati wi ohunkohun lọjọ naa.
Lẹyin ọpọ atotonu, abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ naa, Olamide Oladiji, rọ gbogbo wọn lati gba alaafia laaye tori pe ilu ti laasigbo ba wa ni ko nii ni ijọba ibilẹ tuntun.
Eyi ko ni ki awuyewuye miran ma waye laarin awọn ijoye Kabiyesi Olowo ti ilu Owo ati Kabiyesi Ọjọmọluda ti ilu Ijebu-Owo.
Lẹyin ipade ita-gbangba yi ni awọn ẹgbẹ kan to pe ara wọn ni ‘Akoko Consultative Forum’ pe akiyesi ijọba si bi wọn ṣe fun ijọba ibilẹ mẹrẹẹrin to wa ni agbeegbe Akoko ni ijoba ibilẹ tuntun mẹsan ti ijọba ibilẹ Owo ati Ose si ni ijọba ibilẹ tuntun mẹjọ.
Wọn waa rọ ijọba lati fun Akoko ni ijọba ibilẹ tuntun mẹrindilogun lati le dọgba pẹlu Owo/Ose.
Gbogbo awọn awuyewuye lọtun-losi yi ni ijọba ko tii fesi si ko too di pe gomina buwọlu abadofin naa.
Ẹwẹ, lati igba ti gomina ti buwọlu idasilẹ awọn ijọba ibilẹ tuntun naa, awọn araalu ko tii ri orukọ ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn tuntun naa.












