Ohun tó wáyé níléẹjọ́ rèé lórí ìgbẹ́jọ́ Tani Olohun

Tani Olohun

Oríṣun àwòrán, Tani Olohun/BBC

Ile ẹjọ Upper Area Court to kalẹ si ilu Ilọrin, ti da ẹjọ atako si ofin ti awon agbẹjọro Tani Olohun ati Oloye Ademọla Ọlawoore, tii ṣe Oluwo ilu Tede nu.

Eyi lo waye loni, ọjọ Aje, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023, niwaju Adajọ Sunday Adeniyi.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ni igbẹjọ to kọja ni awọn agbẹjọro fun Tani Olohun ti fi iwe atako si igbẹjọ rẹ to n lọ lọwọ sita pe makaruru ofin ni ki onibara awọn maa jẹjọ ni ile ẹjọ meji ọtọtọ lori ẹsun kan naa.

Won tun sọ pe ile ẹjọ Upper Area Court ko ni agbara to labẹ ofiun lati gbọ igbẹjọ naa, won si gba ile ẹjọ ọhun ni iyanju ko da igbẹjọ naa nu ki wọn si pa ọkan pọ si ojukan tii se ti ile ẹjọ Majisireti.

Adajọ ile ẹjọ naa ninu idajọ ranpẹ rẹ kede pe ile ẹjọ Upper Area Court ti igbẹjọ ọhun ti n waye dantọ, o si ni agbara ati asẹ lati gbọ ẹjọ naa.

Adajọ naa kun pe lotitọ ni ẹjọ le jọ ara wọn ṣugbọn awọn eeyan ọtọọtọ lo pe awọn olugbẹjọ naa lẹjọ ni ile ẹjọ meji ọtọtọ.

O ṣalaye pe ẹgbẹ kan to n jẹ Ogo Ilorin ni olupẹjọ ni ile ẹjọ Majisireti ti Alfa Okutagidi si jẹ olupẹjọ si ile ẹjọ Upper Area Court.

Idajọ yii n tumo si pe Tani Olọhun yoo tẹsiwaju lati maa jẹjọ lọ ni ile ẹjọ mejeeji, iyẹn ilẹ ejọ Upper Area Court ati ilẹ Majistreeti.

Lẹyin idajọ yii ni oga awọn agbejọro fun Tani Ọlọhun, Ademola Bank, rọ ile ẹjọ pe ki o fun awọn olujẹjọ mejeeji ni beeli ki won si maa tatile wa jẹjọ.

Agbejẹrọ fun Alfa Okutagidi, Umar Sa'ad Imam tako ọrọ naa pe ti wọn ba fun wọn ni beeli, wọn yoo tun ṣe ohun to buru ju ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn n jẹjọ rẹ lọwọ lọ.

Lẹyin naa ni ile ẹjọ sun igbẹjọ ọhun si ogunjọ oṣu yii.