Àìpèsè ààyè ìgbé-ọkọ̀-pàmò-sí wà lára ìdí tí a fí wo ilé ìtajà DATKEM ní Ijebu Ode- iléeṣẹ̀ ààtò ìlú sàlàyé

Oríṣun àwòrán, @Ogun state
Ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ilẹ ati aato ilu nipinlẹ Ogun ti ko alaye ṣe lori idi ti wọn fi wo apa kan ile itaja alaranbara kan to wa ni ilu Ijebu Ode.
Ile itaja yi tawọn agbaṣẹṣe ṣi n kọ lọwọ la gbọ pe o jẹ ti ileeṣẹ DATKEM Enterprises ileeṣẹ kan to jẹ ti iyawo Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Ogun, Gbenga Daniel.
Gẹgẹ bi akọwe agba ileeṣẹ yi ti ṣe sọ,ọpọlọpọ ohun amuyẹ to yẹ ko wa ni ile itaja yi ni ko si nibẹ.
Onimọ ẹrọ Olayiwola Abiodun ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin BBC ṣalaye pe ijọba ti n kilọ fawọn agbaṣẹṣe ile yi tipẹ ṣugbọn wọn keti ikun si ikilọ ijọba.
Ni paapa, o sọ pe awọn agbaṣẹṣe ko tẹle ilana ati igbesẹ to wa ni ibamu pẹlu iwe aṣẹ ile kikọ ti wọn gba lọdọ ijọba.
''Lati ọjọ kerinlelogun, oṣu karùn-ún ọdún 2022 ni ijoba tí kọ̀wé sì àwọn agbasese náà láti da ọwọ ìṣe dúró ṣùgbọ́n nise ni wọn kọ etí ikun sì ọpọlọpọ ìwé tí ìjọba tí kò láti dawo ìṣe náà dúró.''
Olayiwola fi kun pe ko si aaye igbọkọsi ati awọn ohun amuyẹ mii ninu ile naa bi wọn ṣe n kọ lọwọ.
Tori naa lo fi ni awọn fẹ fi da ile naa wo ki o maa ba wa da wahala silẹ lọjọ iwaju.
Ọjọ mẹta pere ni ijọba fun wa ki wọn to wa da ile wo
Lowurọ kutu ọjọ Aiku ọsẹ yi ni ijọba ipinlẹ Ogun ko awọn ọlọpaa lọ si ile itaja alarambara yi lati bẹrẹ si ni wo iloe naa.
Opopona Falagbade ni Ijebu Ode ni ile itaja naa wa.
Ninu awọn aworan ati fidio taa ri loju opo ayelujara, apẹrẹ wa wi pe wọn ba awọn apa kan jẹ nibi ile itaja yi ṣugbọn ko yi ti da wo lulẹ patapata.
Agbaṣẹṣe ile naa Ọgbẹni Olusegun Lawal fidi ọrọ mulẹ pe lootọ lawọn kan wa lati da ile naa wo.
O sọ pe yoo ti to biliọnu Naira kan tawọn ti na sori ile yi ki wọn to wa ba ile naa jẹ.
O ṣalaye pe ọjọ mẹta pere ni ijọba ipinlẹ Ogun fun awọn pe kawọn kuro nibi ile naa ki wọn to pada wa da ile naa wo.
Gbenga Daniel ti yọju si ile itaja naa ni Ijebu Ode
Ninu awọn fọnran fidio kan to wa kaakiri loju opo ayelujara, a ri ibi ti Sẹnẹtọ Gbenga Daniel ti yọju si ile itaja ti aawọ wa lori rẹ yi.
Ọkan ninu fidio taa ri ṣafihan igba ti o bọọlẹ ninu ọkọ tawọn alatilẹyin rẹ si n ki ni mẹsan mẹwa bo ṣe wa wo ile naa.
A ko ribi to ti sọrọ yala pẹlu awọn akọroyin tabi awọn to peju sibẹ.
Ohun taa ri ni pe o rin kaakiri ile naa to si ko si inu ọkọ rẹ lẹyin to wo ayika naa tan.












