Ìpànìyàn lemọ́lemọ́ fún ètùtù ọlà l'Ogun ń kà mí láyà, ẹ fopìn sí i - Dapo abiodun

aworan

Oríṣun àwòrán, dapo abiodun/facebook

Bi ipaniyan lati ṣoogun owo nipinlẹ Ogun se n pọ si, Gomina Dapo Abiodun ti kesi awọn oniṣegun ibilẹ lati ran ijọba lọwọ fi dẹkun iwa ibajẹ naa.

Gomina Abiodun rawọ ẹbẹ yii nibi idanilẹko ti ẹgbẹ awọn onisegun ibilẹ nipinlẹ Ogun, Alternate Medicine Board (OGAMB) ṣe pẹlu ifowosowopo ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ naa lori ilanilọyẹ tako iwa ipaniyan.

Abiodun wa bu ẹnu atẹ lu iwa buruku ti awọn apaniyan ṣoogun ọrọ n se, tawọn eeyan yoku ni Naijiria si n fi oju aitọ wo ipinlẹ naa.

Gomina ni asiko ti to lati gba ipinlẹ Ogun kuro lọwọ awọn oloogun owo lọna ati fun ipinlẹ Ogun ni oju titun.

Bakan naa ni Abiodun rawọ ẹbẹ si awọn oniṣegun abalaye lati ran ijọba lọwọ, ki wọn le dẹkun iwa ibajẹ naa.

"Ma a da ayajọ ọjọ Ìṣẹ̀ṣẹ́ silẹ fawọn onisegun ibilẹ, ti yoo maa waye lọdọọdun"

O wa ṣeleri pe oun yoo fọwọ si iwe-aṣẹ lati da ayajọ ọjọ Isese silẹ eyiti yoo maa waye lọdọọdun gẹgẹ bii ọjọ ti wọn ya sọtọ fun gbogbo awọn oniṣẹṣe ni ipilẹ naa.

Gomina naa tun ṣeleri pe ijọba oun pẹlu ajọṣepọ awọn ile-iṣẹ ijọba ti ọrọ kan lati ṣeto Ile-ẹkọ giga ti yoo risi idasilẹ ṣiṣe oogun ibilẹ nipinlẹ Ogun.