Islam àti ìfẹ́ tí mo ní sí ìlú ni mo fi fẹ́ kí wọ́n kà mí kún àwọn tó ń ṣe dáadáa - Salihu Mustapha APC
Ninu ifọrọwanilẹnuwo yii ti BBC Yoruba ṣe pẹlu oludije sipo aṣofin labẹ Asia ẹgbẹ All Progressives Congress nipinlẹ Kwara, Salihu Mustapha ti sọ pe kii ṣe ti owo loun n ba lọ ile aṣofin toripe Ọlọrun ti ṣe f’oun na.
Salihu n figagbaga pẹlu Minisita eto idaraya tẹlẹri to si tun jẹ agbẹnusọ ẹgbẹ APC tẹlẹri, Bolaji Abdullahi amọ to wa n dije labẹ Asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party bayii.
Salihu sọ fun BBC Yoruba pe o da oun loju pe oun yoo bori.

Bakan naa lo mẹnu ba awuyewuye to n lọ kaakiri pe oun ati ọkan lara awọn agba ẹgbẹ APC to di opo rẹ mu ni Kwara, Sẹnetọ Oloriegbe ko ni ija kankan koda awọn ti jọ ṣiṣẹ pọ.
Èmi àti Sẹ́nétọ̀ Oloriegbe kò jà, ẹni to ba ni wọn o ṣe daadaa n parọ ni.”
O ni “àwa ń wá bí gbogbo wa ní APC yóò ṣe wọlé ní Ilorin ni”, o si ṣalaye idi ti wọn ṣe fẹ ko ri bẹẹ.
Salihu sọ pe ni gbogbo ibi ti oun ba wa, oun fẹ ki wan ka oun kun ara awọn to n ṣe daadaa.





