Kí ló fa awuyewuye láàrín Adeleke àti Oyetola lórí ìṣákọ́lẹ̀ ìwakùsà l’Osun?

Aworan Oyetọla ati Adeleke

Oríṣun àwòrán, @IBRAHIMMAURUFG1

Ko da bii pe ọrọ awuyewuye to n waye laarin gomina Ademola Adeleke ati Adegboyega Oyetọla to jẹ ṣaaju rẹ, tii mura ati sinmi bayii.

Idi ni pe gomina Adeleke tun ti de pẹlu awọn ẹsun aṣemaṣe tuntun to ni ijọba ana ni ipinlẹ Ọṣun labẹ Adegboyega Oyetọla hu.

Lọtẹ yii lori iwakusa ni gomina Adeleke n pariwo le lori.

Gomina Adeleke fi ẹsun kan iṣejọba APC to kọja ni ipinlẹ Ọṣun pe gbogbo ọdun ti wọn lo nipo, awọn ileeṣẹ awakusa ni ipinlẹ naa ko san kọbọ to yọ sinu aṣuwọn ijọba ipinlẹ naa.

Gomina Adeleke sọrọ yii lasiko to fi n ṣe agbekalẹ igbimọ kan lori iwakusa nipinlẹ naa.

O wa ṣeleri pe gbogbo owo ti awọn agbefọba lẹka iwakusa, amojuto igbo ọba atawọn ẹka miran yẹ ki wọn san fun ijọba, loun yoo gba pada patapata.

Ileesẹ kan to n wa goolu ko sanwo kankan funjọba Osun lati ọdun mẹẹdọgbọn sẹyin - Adeleke

Gomina Adeleke tẹnumọ ọrọ ileeṣẹ awakusa goolu kan, ti o ni ko tii san kọbọ si apo ijọba ipinlẹ Ọṣun lati nnkan bii ọdun marundinlọgbọn to ti n wa goolu ni ipinlẹ naa.

O ni nipa ilana ofin, o yẹ ki ida mẹtala gbogbo owo ori goolu tabi ohun alumọni ilẹ kankan ti ẹnikẹni ba wa ni ipinlẹ Ọṣun, maa wọle si apo ijọba ipinlẹ naa.

“Titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ko si akọsilẹ owo kankan ti ileeṣẹ Sẹgilọla atawọn ileeṣẹ̀ awakusa miran san si apo ijọba ipinlẹ Ọṣun.

Iṣejọba mi yoo gba gbogbo owo ti awọn ileeṣẹ to n wa kusa goolu nipinlẹ Ọṣun ba jẹ wa.”

O fi kun un pe gbogbo awọn ileeṣẹ awakusa to n ba ilẹ ati ayika ipinlẹ naa jẹ ni yoo bẹrẹ si ni sanwo ẹtọ gba mabinu fun ṣiṣe afọmọ awọn odo ti wọn n fọ awọn idọti kusa wọn si.

O ni odo Oṣun ti di orisun aisan fun awọn eeyan ipinlẹ naa nipasẹ awọn kusa ti wọn n fọ sinu rẹ lai jẹ pe wọn gbe igbesẹ kankan lati yanju rẹ.

Aimọkan n ṣe gomina Adeleke lori ọrọ ida mẹtala 13% derivation to n pariwo le lori – APC Osun

Ṣe wọn ni bi eeyan ba fi eti gbọ eebu ara rẹ ti ko fesi, ẹru ija lo n ba irufẹ ẹni bẹẹ.

Eyi lo mu ki ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Osun se fesi si awọn ẹsun ti gomina Adeleke fi kan isejọba to kogba wọle.

APC sọ lasọye pe aini imọ ati oye to kuna nipa eto iṣejọba lo n da gomina Adeleke laamu.

Ninu atẹjade kan ti adele alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun, Sooko Tajudeen Lawal fọwọ si ni eyi ti jẹyọ.

APC sọ pe ijọba apapọ lawọn ileeṣẹ awakusa maa n san iṣakọlẹ ida mẹtala ninu ọgọrun, 13% derivation, fun eyi ti gomina n sọrọ pe wọn ko jẹ.

Aworan Adeleke ati Oyetọla nibi ti wọn ti n ki ara wọn lode kan

Oríṣun àwòrán, other

Ijọba fun ileesẹ goolu naa lanfani ati sinmi owo ori sisan fun ọdun mẹta - APC Osun

“Awọn awakusa yii n san iṣakọlẹ to wa laarin ida mẹta si ida marun un lori iwọn goolu kọọkan tabi ohun alumọni ti wọn ba wa lori ilẹ ipinlẹ Osun fun ijọba apapọ.

Idi ni pe ijọba apapọ lo lagbara lori iwakusa”

Ẹgbẹ naa ni ninu owo yii ni ijọba apapọ yoo ti wa san ida mẹtala ninu ọgọrun owo iṣakọlẹ fun ijọba ipinlẹ naa.

APC ni ileeṣẹ iwakusa goolu naa ko tilẹ tii lo ọdun marundinlọgbọn ni ipinlẹ Osun.

O fikun pe lọwọ yii, ijọba fun ileesẹ naa lanfani ati sinmi owo ori sisan fun ọdun mẹta.

APC ni eyi tumọ si pe ileeṣẹ naa ko tilẹ san owo iṣakọlẹ tabi owo ori kankan lasiko ti Oyetọla fi wa nipo gẹgẹ bi gomina.