Wo bí òfin Covid-19 tuntun ṣe kàn ọ́ tó o bá ń rìnrìnàjò pẹ̀lú bàálù

Papakọ ofurufu

Ni irọlẹ Ọjọ Aje ni ijọba Naijiria tun kede awọn ofin tuntun kan to nii se pẹlu awn arinrinajo to n lọ silẹ okeere.

 Awọn ofin tuntun ọhun si lo foju han ninu atẹjade kan ti igbimọ amusẹya to wa fun akoso itankalẹ arun Covid-19 labẹ ijọba apapọ fi sita.

 Agbekalẹ ofin tuntun naa ni wọn lo ni nnkan se pẹlu bi ọwọja arun Covid-19 se n lọ silẹ lorilẹede yii ati ni ọpọ orilẹede jakejado agbaye.

 Nibayii, ọpọ awọn ofin to de arun Coronavirus yii si ni ijọba ti yipada eyi to ni ohun se pẹlu awọn eeyan to n lọ si papakọ ofurufu tabi rinrinajo lọ soke okun.

 Lara awọn ohun to se koko ninu awọn ofin tuntun tijọba gbe sita naa ree:

Wo bi ofin tuntun Covid-19 se kan awọn arinrinajo labẹle atawọn osisẹ papakọ ofurufu:

Lilo ibomu taa mọ si Facemask ko pọn dandan mọ ninu papakọ ofurufu ati awọn ayika rẹ.

 Ki awọn osisẹ ọkọ ofurufu atawọn ero maa lo ibomu ninu ọkọ ofurufu gan kii se ọranyan mọ

 Kikida awọn eeyan to pọn dandan fun lati lo ibomu ni awọn ero ti ọjọ ori wọn ti le ni ọgọta ọdun.

 Ofin naa tun rọ awọn eeyan to ba sisẹ abẹ lati paarọ ẹya ara kan si omii atawọn to ni arun jẹjẹrẹ lati maa lo ibomu.

 Bakan naa ni awọn eeyan to ni aisan atọgbẹ, aisan ọkan ati ẹjẹ riru nilo lati maa lo ibomu.

 Ko tan sibẹ, wọn tun gbọdọ maa fọ ọwọ wọn loore-koore pẹlu ọsẹ ati omi, ki wọn si maa fi sanitaisa ra ọwọ nigba ti wọn ba wa laarin ọpọ ero. 

Wo awọn ofin tuntun miran to nii se pẹlu awọn arinrinajo ni papakọ ofurufu:

  • Kii se dandan mọ fawọn arinrinajo lati maa fi oogun apakokoro sara apo ẹru ti wọn n gbe rinrinajo niwaju abawọle papakọ ofurufu
  • Awọn onileesẹ ọkọ ofurufu yoo bẹrẹ si ni maa pin ounjẹ fawọn ero wọn lẹnu irinajo lati akoko yii lọ
  • Ko si ofin titakete sira ẹni mọ ninu awọn papakọ ofurufu bẹẹ ni ko pọn dandan lati se bẹẹ
  • Awọn ibudo itura to wa ni papakọ ofurufu ni yoo maa seto imọtoto to yẹ nipa ipese afẹfẹ to yaayi
  • Ofin naa tun daba fawọn arinrinajo lati maa lo sanitaisa to ni ogogoro ninu fi ra ọwọ wọn
  • Amọ ofin tuntun yii ko ni mu ayipada ba ilana bawọn ero se n wọnu baalu ati bi wọn se n sọkalẹ.

Wo bi ofin tuntun Covid-19 se kan awọn ileesẹ baalu latilẹ okeere:

Awọn ero ko nilo lati maa lọ se ayẹwo arun Covid-19 mọ lasiko ti wọn ba fẹ wọ baalu tabi sọkalẹ, boya wọn gba abẹrẹ ajẹsara ni tabi wọn ko gba a.

Ayẹwo PCR fawọn ero ti ko gba abẹrẹ ajẹsara pe gan ko wulo mọ.

Gbogbo awọn ilana ofin tuntun ta kọ soke saaju feto irinna ofurufu labẹle naa lo kan awọn arinrinajo soke okun.

Fọọmu to n kede bi ilera rẹ se ri:

Arinrinajo ko nilo fọọmu to n fun ni lasẹ lati rinrinajo soke okun mọPermission to

Iwe ibeere kan soso ti ko nii ohunkohun se pẹlu Covid-19 ni wọn yoo maa fun awọn arinrinajo to n bọ wa si Naijiria lati dahun rẹ

Oju opo ayelujara Nigeria International Travel Portal (NITP) ni awọn arinrinajo to n bọ ni Naijiria naa yoo ti fọwọsi iwe ibeere ọhun

Awọn arinrinajo ti ko ba dahun iwe ibeere naa lori ayelujara ni wọn yoo fun ninu baalu lati fọwọsi tabi ninu ọgba papakọ ofurufu nigba ti wọn ba gunlẹ tan.

Àkọlé fídíò, Vaginismus: Obìnrin kan tó ní àìsàn Vaginismus rí sọ ìrírí rẹ̀ àti bó ṣe bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀

Ìjọba àpapọ̀ wọ̀gile ayẹ́wo Corona fún àwọn arìnrìnàjò

Aworan

Oríṣun àwòrán, Akwa Ibom Ministry of Information and Strategy

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti kede pe awọn ti wọgile ayẹwo Corona fun awọn arin irinajo to n bọ tabi ti wọn kuro lorilẹede naa

Ikede yii wa ninu atẹjade kan ti akọwe ijọba apapọ orilẹee, Boss Mustapha bu wọlu fun awọn akọroyin lọjọ Aje ọsẹ yii.

O ni Aarẹ Buhari gbe igbesẹ naa lẹyin ti awọn igbimọ to n ṣe iwadii lori aarun Corona virus pinnu pe asiko ti to lati wọgile awọn ofin to rọ mọ aarun naa.

Ni bayii, ko kii ṣe dandan lati lo ibomu ati awọn nnkan yoku lati fi dena aarun naa.

“Gbogbo arinrinajo, to n bọ tabi ti wọn kuro lorilẹede Naijria ni wọn ko nilo ayẹwo aarun Corona mọ.

“Pẹlu bi a ṣe ti wọgile ofin yii, awọn arinrinajo ko nilo lati fi iwe ẹri pe wọn ṣe ayẹwo si ori iwe irinajo wọn sugbọn a rọ yin, ẹ rii pe ẹ gba abẹrẹ ajẹsara Corona yin pe.

Ninu oṣu Keji ọdun 2020 ni orilẹede Naijria ṣe akọsilẹ ẹni to kọkọ ni aarun Corona, ti ileeṣẹ ijọba to n risi irinajo ori ofurufu si fi ofin de irinajo ni paapa ofurufu Muritala Muhammed niluu Eko ati Nnamdi Azikwe niluu Abuja."