Mo padà bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣekúpa Deborah bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo yọ ọ̀rọ̀ mi àkọ́kọ́ – Atiku

Deborah Samuel and Atiku

Oríṣun àwòrán, Others

Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, ti bu ẹnu atẹ lu iṣekupa Deborah Yakubu, to jẹ ọmọ ile ẹkọ ipele keji ni Shehu Shagari College of Education ni Sokoto.

Atiku lo ṣe bẹẹ nibi itakurọsọ kan ti ileeṣẹ iroyin abẹle Channels atawọn alabaṣiṣẹpọ rẹ gbe kalẹ.

Igbakeji Aarẹ nigba kan ri yii ni oun yọ ọrọ ti oun kọkọ fi lede loju opo Twitter kuro nibẹ nitori oun kọ fọwọ si ki awọn oṣiṣẹ oun fi ọrọ naa lede.

Inu oṣu Karun un, ọdun 2022 yi ni awọn Musulumi akẹgbẹ oloogbe naa toun jẹ Kristẹni gbẹmi rẹ lẹyin ti wọn fẹsun kan pe o sọrọ abuku si ẹsin Islam.

Ni kete ti Atiku bu ẹnu atẹ lu iṣekupa oloogbe naa ni ọpọ awọn eeyan bẹrẹ si ni tako o.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ko yẹ ki Atiku bu ẹnu atẹ lu iṣekupani ọhun nitori oun funra rẹ jẹ Musulumi, lawọn mii n sọ pe awọn ko ni dibo fun un nitori igbesẹ rẹ naa.

Ka to wi, ka to fọ, Atiku ti yọ ọrọ naa kuro loju opo Twitter rẹ, eyii ti ko dun mọ ọpọ awọn alatilẹyin rẹ ninu, ti wọn si sọ pe o ṣe bẹẹ nitori ki awọn Musulumi le dibo fun un lọdun to n bọ ni.

Mo gbọdọ buwọlu atẹjade ki wọn to fi soju opo Twitter mi

Wayi o Atiku ti wa sọ pe bo tilẹ jẹ pe lootọ ni oun yọ ọrọ naa kuro loju opo Twitter, oun tun pada bu ẹnu atẹ iṣekupa akẹkọọ naa ninu awọn atẹjade mii.

O ni “mo ni ki wọn yọ ọrọ naa kuro lori Twitter nitori mo maa n kọkọ buwọlu gbogbo atẹjade ki wọn fi soju opo Twitter mi.”

“Nitori mi o fọwọ sii ki wọn to fi lede ni mo ṣe ni ki wọn yọ ọ kuro nibẹ, ti ẹ ba woo awọn atẹjade mii ti mo fi lede, mo bu ẹnu atẹ lu ipaniyan naa.”

Atiku pari ọrọ rẹ pe “ko si ibi kankan to wa ninu ẹsin Islam pe ki a lọ paayan, wọn ni lati gba ọna to tọ.”