Ẹgbẹ òṣèlú PDP fi Makinde sílẹ̀, yàn Ademola Adeleke gẹgẹbi ádárì ẹto ìpolongo.

Oríṣun àwòrán, GODWINADEDAYO/FACEBOOK
Awọn olori ẹgbẹ ipolongo ibo Aarẹ ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti fọwọsi iyansipo Gomina Ipinle Osun, Ademola Adeleke, gege bi ọmọ ẹgbẹ ipolongo fún ẹto idibo ṣipo aarẹ Atiku Abubakar. Adeleke ni wọn yan gẹgẹbi Alaga ti Igbimọ ipolongo fun eka guusu iwọ-oorun,gẹgẹ bi atẹjade ti Gomina Tambuwal ẹniti o jẹ alaga gbogbogbo fún ẹto ipolongo Atiku Abubakar towobo. Adekunle Akindele ọkan lara awọn oloṣelu nipinlẹ osun ni Gomina Adeleke ni wọn yan lati dari ẹto ipolongo Atiku Abubakar nitori ohun lọ gbegede julọ Adekunle Alága ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ osun ni botilejẹwipe aawo ranpe wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP eyiti Gomina Seyi Makinde wa ninu igun miran ninu ẹgbẹ pdp, iyansipo Adeleke ko ṣẹyin ọgbọn awọn adari ẹgbẹ oṣelu PDP .
Awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP miiran ti wọn tun yan lati ṣe olori awọn eka ọfiisi ipolongo fun idije dù ipo aarẹ Atiku Abubakar ni. Seneto Dino Melaye ni won yan gege bi oludari eto oro ilu,Senato Theodore Orji ni ó dari agbegbe guusu ila-oorun,senato Duoye Diri dari agbegbe guusu-guusu,Ademola Adeleke gẹgẹbi adari guusu iwọ-oorun,Gomina tẹlẹri Gabriel Suswan dari aringbungbun ariwa,Darius ishaku dari ariwa ila-oorun ti Adamu Aleiro dari ariwa guusu.











