Ìjọba bẹ̀rẹ̀ igbesẹ òfin tí yóò fí àyè gbà 'Iṣẹ́ aṣẹ́wó’!

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Minisita fun eto idajọ ti kede pe awọn fẹ gbe ofin kan kale ti yoo fi aye gbe awọn oni isẹ aṣẹwo lorilẹede South Africa.

Oṣu to kọja ni ile aṣofin buwọlu abadofin lori awọn ofin to ni ṣe pẹlu ibalopo.

Adajọ Ronald Lamola ni “erongba wa ni lati mu idikun ba bi awọn eeyan ṣe n kọlu awọn to ṣe isẹ asẹwo, eyi to tabuku etọ ọmọniyan.”

Ileeṣẹ iroyin AFP ni awọn ẹgbẹ to ja fun ẹtọ isẹ aṣẹwo, SWEAT so pe: “Awọn to n ṣe isẹ asẹwo ko ki n ṣe ọdaran, ti awọn yoo si le ṣe isẹ wọn ti awọn ọlọpaa ba gbogun ti rogbadiyan to waye.”

Ki ni idi ti Ijọba fẹ fi ṣe agbekalẹ ofin naa?

Ọkan gboogi ti ijọba orilẹede Amẹrika fẹ fi ṣe agbekalẹ ofin ọhun ni lati gbogun ti bii awọn obinrin lorilẹede naa ṣe kọju awọn laasigbo.

Iwadii ni pe lorilẹede South Africa, awọn to n ṣe isẹ asẹwo ju ẹgbẹrun lọna aadọjọ eeyan lọ.

Ni aipẹ yii, Ijọba sawari oku awọn eeyan mẹfa ti igbagbọ wa pe alasẹwo niwọn lẹyin ti wọn di awati ni ile kan to wa ni Johannesburg ninu oṣu kẹwaa.

Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, Bheki Cele ni o ti to ẹgbẹrun kan obinrin ti wọn padanu ẹmi laarin ọdun latari pe wọn gbẹmii wọn, ti iwa ifipanilopọ naa po si jaburata lorilẹede naa

Ki ni nnkan ti ofin naa sọ?

Ofin orilẹede South Africa wa lara awọn ofin lagbaye to fi aye gba ẹtọ ọmọ niyan.

Ofin naa fi aye gba oyun sisẹ ati igbeyawo akọ si akọ ati abo si abo sugbọn ko ti fi aye gba isẹ aṣẹwo.

Pẹlu awọn ofin yii, atunṣe yoo de ba ojo ti ọpọ eeyan fi n wo isẹ aṣẹwo.

“Isẹ aṣẹwo ko ki n ṣe ẹsẹ mọ, yoo mu dikun be bii wọn ṣe fi iya jẹ.

“Ofin yoo ri pe orilẹede South Africa tẹle ilana agbaye.”

Wo awọn orilẹede to fi aye gba isẹ aṣẹwo

Ko ki n ṣe gbogbo orilẹede lagbaye lo ri isẹ asẹwo gẹgẹ bii ẹsẹ, awọn miiran fi aye gba awọn to ba nifẹ si lati mu gẹgẹ isẹ ojọ wọn.

Awọn orilẹede naa niyi

Finland, Costa Rica, New Zealand, Austria, Bangladesh, Denmark, Netherlands, Canada, Germany, Greece, Colombia, Turkey, awọn ipinlẹ ni Amẹrika ati Australia.