Mo kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Naijiria ṣáájú ìbò 2015 pé rúgúdù ń bọ̀ àmọ́ wọn kò gbọ́nran – Oyedepo

Shiloh 2022

Oríṣun àwòrán, davidoyedepomin

Alufaa agba ijọ Living Faith Church Worldwide, Biṣọọbu David Oyedepo ti sọ pe olugbala ni Naijiria nilo lọwọ yii, kii ṣe adari.

Oyedepo lo sọ ọrọ naa lasiko to n waasu nibi isin ọlọdọdun Shiloh to n lọ lọwọ niluu Ota, nipinlẹ ogun.

Oluṣoagutan naa sọ pe ṣaaju idibo ọdun 2015, oun kilọ fun awọn ọmọ Naijiria ki wọn yan adari rere sipo amọ wọn ko gbọran si oun lẹnu, ṣugbọn gbogbo araalu lo n jiya aigbọran naa bayii.

O ni “Mo kilọ fun orilẹ-ede yii lọdun 2015 pe rugudu n bọ amọ ko si ẹni to tẹti si mi.

“Nibayii, ohun ti wọn mọ Naijiria si yatọ si eto abo ti ko ṣe dede ati ọrọ aje to ti dẹnukọlẹ ni ijọ.”

Alufaa naa tẹsiweaju pe “Mi o ki n ṣe oloṣelu mi o si ni tọwọ mi bọ oṣelu lailai... amọ ilẹ yii gbọdọ gba isinmi.”

Oyedepo tun fi akoko iwaasu naa ke si awọn ọmọ ijọ rẹ ki wọn gbadura ki Ọlọrun fun Naijiria ni olugbala.

O ni “Ti o ba fẹran Naijiria, o jẹ tete gbadura ki Ọlọrun fun Naijiria ni olugbala ki a le ni isinmi lẹẹkan si.

“Akoko ti to fun wa lati ni isinmi, Ọlọrun ran olugbala si Israel, ilẹ naa si ni isinimi fun ọgọrin ọdun.”

Ijọ nikan lo fun Naijiria lorukọ rere

Oyedepo tun sọ pe ijọ ọmọlẹyin Kristi nikan lo n fun Naijriia ni orukọ rere.

O ni “Ipade nla kan waye ni gbọgan Redemption Camp, ijọ nikan lo n fun Naijiria ni iyi bayii.”

“Awa ijọ, a wa ni alaafia amọ wọn n ba ara wọn ja.”

“Ko ni si ogun ni Naijiria, bẹẹ si ni ko ni si itajẹsilẹ ni Naijiria.

“Naijiria yoo ṣe aṣeyọri, ẹgan wa gẹgẹ bii orilẹ-ede yoo si ka kuro.”

Ẹwẹ, oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi wa lara awọn to peju sibi iwaasu naa.