DSS fún NNPC àti IPMAN gbèdéke ọjọ́ méjì láti fòpin sí ọ̀wọ́n gógó epo bẹntiró

Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lorilẹ ede Naijria, DSS ti kede pe awọn fun ajọ to n risi ọrọ epo rọbi, NNPC ati awọn alagbata epo IPMAN ni gbedeke ọjọ meji lati fopin si bi ọwọn gogo epo ṣe gba igbooro kan.
Agbẹnusọ ajọ ọhun, Peter Afunanya lo ṣe ikede naa nigba to ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ti ajọ naa ati awọn alagbata epo rọbi ṣe ipade oni wakati mẹta niluu Abuja.
O ni ti awọn NNPC ati IPMAN ba kuna lati tẹle asẹ yii, awọn yoo bẹrẹ si ni ṣoro kaakiri awọn ile epo lorilẹede Naijiria.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, o ni bi ọwọn gogo epo rọbi ṣe gba igboro kan le jẹ anfani fun awọn agbebọn lati ṣe ọsẹ fun awọn araalu.
O tẹsiwaju pe ajọ NNPC, nibi ipade naa, fi idi rẹ mulẹ pe epo bẹntiro wa nilẹ jaburata fun lilo awọn ọmọ orilẹede Naijiria paapa julọ lasiko ọdun keresi yii.
Afunanya ni iṣoro ti awọn eniyan n koju lori epo lẹnu ọjọ mẹta yii pọ pupọ ju nitori naa ni awọn ṣe gbe igbesẹ lati wa ojutuu si ọrọ naa.
"Lati ọsẹ diẹ sẹyin, awọn ọmọ Naijiria to ba wa sọrọ lori iriri wọn ni ilu ilọrin, Ikirun, Ondo, Abuja, Eko ati bẹẹ bẹẹ lọ ni ko dẹrun rara, eleyii ti wọn ni ohun kọ wọn lominu nipa orilẹede Naijiria."
"Awọn miran bu ẹnu atẹ lu awọn oloṣelu ti ko naani iṣoro ti awọn araalu n la kọja ati inira to n de ba wọn."
O fi kun pe àwọn eniyan n sọ pe lati Oṣu kẹta ọdun yii ni awọn ti n koju ọwọn gogo epo bẹntiro ni ilu Abuja, ti wọn si n ra a ni iye ti owo rẹ to 250 si 300.















