BBC 100 Women 2022: Ibijoke Faborode, Joy Ngozi Ezeilo jẹ́ ọmọ Nàìjíríà tií wọ́n wà lára àwọn akọni obìnrin 2022

Wo àwọn obìrin tí BBC kéde pé wọ́n làmìlaaka jù lágbàyé
Ileeṣe iroyin BBC ti fi orukọ awọn obinrin ọgọrun lede gẹgẹ bii awọn to gbe igbeaye to ṣe mu yangan ati eyii to jẹ iwuri.
Lara awọn eeyan naa ni Ibijoke Faborode ati Joy Ngozi Ezeilo, lati Naijiria, bẹẹ naa ni Nana Darkoa Sekyiama, lati Ghana, olorin takasufẹ ọmọ Amẹrika, Billie Eilish, iyawo Aarẹ Ukraine, Lady Olena Zelenska, oṣere Priyanka Chopra Jonas lati India, atawọn obinrin mii kaakiri agbaye.
Ọdun kẹwaa ree, ti ileesẹ BBC ti n kede awọn obinrin ọgọrun fun ipa ti wọn n ko lawujọ.
Awọn obinrin ti a kede orukọ wọn wọnyi jẹ awọn ti wọn n gbe ohun ribiribi ṣe nile aye wọn.
Yatọ si awọn obinbrin ti BBC funra fa kalẹ, BBC tun sọ fun awọn araalu lati fi orukọ awọn eeyan mii kalẹ ti wọn gbagbọ pe o yẹ ki orukọ wọn wa ninu awọn eeyan ọhun.
Wo diẹ lara awọn ọmọ bibi ilẹ adulawọ ati lagbaye ti orukọ wọn wa ninu iwe BBC 100 Women fun ọdun 2022.
Ibijoke Faborode, Naijiria

Ibijoke Faborode wa lara awọn to da ileeṣẹ kan ti kii ṣe ti ijọba, ElectHER, silẹ.
Ibijoke Faborode n lo ElectHER lati ṣe itaniji fun awọn obinrin nipa ọrọ oṣelu.
Nipase ileeṣẹ yii, Ibijoke Faborode ti di alafo to wa laarin awọn ọkunrin si obirin ninu eto oselu ni Afrika, koda nnkan bii ẹgbẹrun meji obinrin nilẹ adulawọn ni wọn ti n ṣe oṣelu nipaṣe ElectHER.
Pẹlu eto rẹ to pe ni #Agender35, ileesẹ naa n ṣatilẹyin fun awọn obinrin marundinlogoji ki wọn le ṣaṣeyọri ninu eto idibo gbogbogo ọdun to n bọ.
Lọwọ yii, Faborode wa lara awọn ọmọ igbimọ adari ajọ Leadership Council of The Democracy and Culture Foundation, to n ṣiṣẹ eto idibo to yanranti.
Joy Ngozi Ezeilo, Naijiria

Ọjọgbọn nipa imọ ofin ni Joy Ngozi Ezeilo ni fasiti ijọba apapọ University of Nigeria.
O tun ti fi akoko igba kan ṣiṣẹ pẹlu ẹka 'United Nations Special Rapporteur on Trafficking in Person' ti ajọ iṣọkan agbaye.
O jẹ ẹnikan to maa n gbogun ti fifi eeyan ṣowo ẹru nilẹ okeere.
Oun ni ọga agba ajọ Women Aid Collective, WACOL, to n ṣoju awọn obinrin nile ẹjọ lati nnkan bii ọdun marundinlọgbọn sẹyin.
Joy tun ni oludasilẹ ajọ Tamar Sexual Assault Referral Centre, to n ṣatilẹyin pẹlu iranlọwọ fun awọn obinrin ti wọn fi ipa ba lopọ.
Nana Darkoa Sekyiamah, Ghana

Iwe rẹ, The Sex Lives of African Women', ni wọn ti juwe gẹgẹ bii ọkan lara awọn iwe to ṣalaye ohun 'to n tumọ si lati jẹ obinrin to ni ominira.
Ileeṣẹ iroyin The Economist juwe iwe naa gẹgẹ bii ọkan lara awọn iwe to lamilaaka julọ ninu ọdun yii.
Onkọwe ni Nana Darkoa Sekyiamah, o tun jẹ ajafẹtọ awọn obinrin.
Nana wa lara awọn to da ikanni ori ayelujara kan silẹ ti orukẹ rẹ n jẹ "Adventures from the Bedrooms of African Women" nibi ti wọn ti maa n sọrọ nipa igebaye obinrin, ohun to ba wọn finra ati ọrọ ibalopọ.
Sarah Chan, South Sudan

Sarah ti fi akoko igba kan gba bọọlu alapẹrẹ ri, ni bayii o si n kọ awọn ọjẹ wẹwẹ ni bọọlu naa atawọn nnkan mii ni orilẹ-ede South Sudan ati Kenya.
Oun ni akọnimọọgba akọkọ nilẹ adulawọn lati kọ ikọ agbabọọlu alapẹrẹ Toronto Raptors, ni Canada.
Lẹyin ti ogun le kuro ni Khartoum, ni Sudan, oun atawọn ẹbi rẹ salọ si Kenya, nibi to ti bẹrẹ iṣẹ bọọlu alapẹrẹ.
O laafani lati lọ kọ imọ nipa bọọlu naa si nile ẹkọ Union University, ni Jackson, Tennessee, Amẹrika, o si gba bọọlu alapẹrẹ jẹun ni Afrika ati Yuroopu.
O da ajọ aladani kan, Home At Home/Apediet Foundation, silẹ eyii to n gbogun ti kikanju ṣe igbeyawo laarin awọn ọdọmọde, o tun n fi ere idaraya kọ wọn lẹkọọ nibẹ pẹlu.
Judy Kihumba, Kenya

O jẹ ẹni to maa n ṣagbatẹru ede fu awọn aditi 'sign language.'
Judy ni oludasilẹ ajọ Talking Hands, Listening Eyes on Postpartum Depression, THLEP, to n ṣe iranlọwọ fun awọn obinrin ti ko gbọran pẹlu ede aditi.
O tu maa n ran awọn obinrin to ni iṣoro lẹyin ti wọn bi ọmọ tan lọwọ lati pada sori ẹsẹ wọn.
Priyanka Chopra Jonas, India

O kere tan, Priyanka ti kopa ninu fiimu ti ko din ni ọgọta.
Priyanka Chopra wa lara awọn oṣere fiimu to milẹ titi julọ lorilẹ-ede India.
O ti fi igba kan gba ami ẹyẹ gẹgẹ bii omidan to rẹwa julọ lagbaye.
Lẹyin ti Priyanka Chopra kopa ninu fiimu fun igba akọkọ lọdun 2002, irawọ rẹ ti tan kaakiri agbaye, oun si ni obinrin lati iha Guusu ilẹ Asia akọkọ ti yoo lewaju ninu fiimu lori ẹrọ amohunmaworan l'Amẹrika, iyẹn ninu fiimu Quantico ti wọn gbe jade lọdun 2015.
Lara awọn fiimu to ti Chopra ti kopa l'Amẹrika to si milẹ titi ni "Isn't It Romantic" ati "The Matrix Resurrections."













