BBC100 Women: Billie Eilish: Ọmọ ogún ọdun tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin 100 tí BBC fún ní àmi ẹ̀yẹ fún ìgbé ayé ìwúrí

- Author, Megha Mohan and Yousef Eldin
- Role, BBC 100 Women
Billie Eilish ni ẹni akọkọ ti wọn bi lati ọdun 2001 ti yoo gba ami ẹyẹ oscar. Ẹni ogun naa ṣalaye fun BBC pe oun ko ni igbagbọ ninu ara oun ati ohun ti oun le gbe ṣe nile aye, eyii ti awọn onimọ eto ilera n pe ni "impostor syndrome."
Lati igba ti olorin naa ti wa ni ọmọ ọdun mẹjọ ni wọn ti kọ lati maa jo bii kokoro.
Bo tilẹ jẹ o ti ni idojukọ lati kekere nipa ọjọ ọla rẹ o pada ṣe oriire, o si di ẹni amuyangan laarin awọn akẹgbẹ rẹ kaakiri agbaye.

Orukọ abisọ rẹ gangan ni Billie Eilish Pirate Baird O'Connell, ilu Los Angele si ni wọn bi si nilẹ Amẹrika, si idile awọn obi ti awọn funra wọn jẹ olorin.
Billie Eilish ko lọ sile ẹkọ kankan, nitori inu ile ni awọn obi rẹ ti kọ lẹkọọ to yẹ ko lọ kọ nile ẹkọ, toun ti ẹgbọn rẹ ọkunrin, Finneaqs O'Connell.
Lati ọmọ ọdun mẹrin ni Billie Eilish ti n kọ orun silẹ funra rẹ.
Lalẹ ọjọ kan lọdun 2015, lasiko to wa ni ọmọ ọdun mẹrinla pere lo fi orin rẹ kan, Ocean Eyes, ti Finneas pinlẹ rẹ sori ikannu Soundcloud, ki olukọ to n kọ ni ijo le lọ sibẹ lati gbọ orin naa.
Ori ikanni Soundcloud yii ni ọpọ eeyan ti gbọ orin naa, nibi ti irawọ rẹ ti bẹrẹ si n tan ka gbogbo agbaye.
O ni "Mo wẹyin wo bayii gẹgẹ bii ọmọ ọdun mẹrinla to ni ẹgbọn ọkunrin to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun to si n ṣe oniruru ipade pẹlu awọn agbalaba, ko rọrun rara."
Bi irawọ Billie ṣe n tan si naa ni awọn ololufẹ to n tẹle lori ayelujare naa n pọ si.
Lọwọ yii, ọgọrun miliọnu eeyan lo n tẹle loju opo Instagram, ọgọta miliọnu eeyan n tẹle loju opo TikTok, koda, to ba kọ atẹjaqde lasan, ogunlọgọ eeyan lo maa n fẹ da si ọrọ naa.
Amọ o ni ko rọrun ki ẹgbẹlẹgbẹ eeyan maa sọrọ labẹ ọrọ ti oun ba kọ lori ayelujara, nitori awọn ọrọ kobakungbe ti awọn eeyan miran maa n kọ sibẹ.
CLIP 1
O ni "Ọmọ ori ẹrọ ayelujara ni mi, mo maa n ri awọn gbajumọ lori ayelujara, nibayii emi naa ti di ero ori ayelujara ti awọn eeyn n sọrọ nipa rẹ.
Lọpọ igba lawọn eeyan maa n ṣi ọrọ rẹ tumọ lori ayelujara, eyii to jẹ ọkan lara awọn iṣoro to maa n koju gẹgẹ bii ọdọmọde.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ko rọrun lati wa ni irufẹ ipo bẹẹ.
CLIP 2
"O ṣoro lati yipada si ipele miran gẹgẹ bii gbajumọ, mo ṣẹṣẹ ba 'impostor syndrome' finran tan ni."
Ko rọrun fun olorin naa gẹgẹ bii ọmọde to di gbajumọ ti ọpọ eeyan lagbaye si n tẹle.
CLIP 3
O ni mo maa n ri ara mi gẹghẹ bii alagbara ti mo ba wọ aṣọ ọkunrin ti mo ba si n ṣe bii ọkunrin.
"O rọrun fun mi lati ṣe bii ọkunrin ju ki n ṣe bii obinrin lọ, mo si ba irori yii finra fun ọpọ ọdun.
Orin ti Billie fẹran ju ni "Your Power."
O ṣalaye fun BBC pe "Orin Your Power naa jẹ orin kan ti to kan gbogbo eeyan."

Billie ni orin ọhun jẹ iriri nipa oniruru eeyan to ti ba pade nile aye rẹ, ti wọn si ti ni oniruru ipa ninu aye rẹ.
O ni ohun to ṣoro ni agbara lati ni, bẹẹ ko rọrun ki eeyan ma ni agbara kankan.

BBC 100 Women BBC fi orukọ awọn obinrin ọgọrun ti igbeaye wọn jẹ iwuri kaakiri agbaye. . Tẹle eto BBC 100 women loju opo Instagram, Facebook ati Twitter. Bakan naa ni li o maa lo ami #BBC100Women.












