Ìdí tí èmi àti Tinubu kò fi gbéná wojú ara wa rí láti ìgbà tí a ti ṣègbéyàwó fún bíi ogójì ọdún - Oluremi Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X
Aya aarẹ orilẹede Naijiria, Sẹnẹtọ Oluremi Tinubu, ti sọ pe oun ati ọkọ oun o gbena woju ara wọn ri lati igba tawọn ti ṣe igbeyawo fun bii ogoji ọdun bayii.
Aya aarẹ sọrọ yii nibi eto iṣinu aawẹ awọn musulumi atawọn kristẹni to waye nileeṣẹ aarẹ l'Abuja.
Oluremi ni bo tilẹ jẹ wi pe musulumi ni ọkọ oun toun si jẹ ọmọlẹyin Kristi, o ni kosi ede-aiyede to tii mu kawọn mejeeji pariwo mọ ara awọn lori ri ninu igbeyawo ogoji ọdun awọn.
Sẹnẹtọ Oluremi rọ gbogbo awọn to wa nibi eto naa to fi mọ awọn aya awọn gomina wi pe ki onikalulu maa gbe ni alaafia pẹlu gbogbo eeyan lai fi ti ẹsin tabi ẹya ṣe.
Aya aarẹ tun sọ idi ti o fi ṣe pataki fawọn obinrin lati maa fi ifẹ han sawọn ọmọ wọn, ki wọn si maa fi wọn le ọna to tọ.
O ni igbeyawo oun ati Tinubu tawọn ko jọ jẹ ẹlẹsin kan naa fi han pe awọn ọmọ Naijiria le jọ gbe papọ ni alaafia lai fi ti ẹsin ṣe.
''Bi aawẹ Ramadan ati Lẹnti ṣe bẹrẹ lasiko kan naa fi han pe Ọlọrun n bawa sọrọ ni Naijiria gẹgẹ bii orilẹede.
Ọpọ eeyan lo ti fẹ fi ọrọ ẹsin da aawọ silẹ lorilẹede Naijiria.
Amọ, ko yẹ ko ri bẹẹ rara tori a ti wọ inu ara wa tori ọpọ ninu wa lo fẹ ẹni ti kii ṣe ẹlẹsin kan naa pẹlu wa ni ọkọ tabi iyawo.
Fun apẹẹrẹ, emi ati ọkọ mi to jẹ musulumi ti ṣe igbeyawo fun bii ogoji ọdun bayii.
Mo le sọ fun yin pe ko si igba kan ti awa mejeeji ti gbena woju ara ri.
To ba si wa, bo ya lo le ju igba meji lọ fun ogoji ọdun.
Eleyii ṣẹlẹ tori a bọwọ fun ara wa, mo si gbagbọ pe bo ṣe yẹ ki gbogbo eeyan jọ maa gbe niyi,'' Tinubu lo sọ bẹẹ.
Sẹnẹtọ Oluremi rọ awọn kristẹni wi pe ki wọn ye maa sọ nipa nnkan to tọ si wọn ni gbogbo igba.
O ni oore ọfẹ lawọn onigbagbọ ri gba lati ọdọ Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi.
Aya aarẹ ni o ṣe pataki fawọn ọmọlẹyin Kristi lati ni ibẹru Ọlọrun ninu ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe.
Oluremi ni ''gbogbo wa ni a niṣẹ lati ṣe papaa julọ lori awọn ọdọ.
A ni lati fi wọn le ọna ti wọn yoo tọ, iṣẹ naa wa lọwọ wa.''
Aya aarẹ tẹlẹ ri, Dame Patience Jonathan, aya igbakeji aarẹ, Hajia Nana Shettima, igbakeji aarẹ tẹlẹ, Hajia Namadi Sambo, iyawo aarẹ ile aṣofin agba, Ekaette Akpabio, awọn ọmọ ile aṣofin agba to jẹ obinrin, awọn minisita obinrin atawọn eeyan mii wa nibi eto iṣinu aawẹ naa.


























