Kíkọ VIN sórí fóònù kì í ṣe láti ṣèrú ìbò, INEC fèsì lórí fídíò tó gba orí ayélujára

Oríṣun àwòrán, Twitter
Àjọ tó ń mójútó ètò ní Nàìjíríà, INEC ti kéde wí pé fídíò kan tó gba orí ayélujára lórí wí pé àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà ń yọ nọ́mbà ìdánimọ̀ káàdì ìdìbò àwọn ènìyàn láti fi ṣèrú ìbò gbogbogboò ọdún tó ń bọ̀.
INEC ní ohun tí ẹni tó ṣe fídíò náà fẹ́ ṣe ni láti fi ṣì àwọn ènìyàn lọ́nà láti má nì í ìgbọkànlé nínú àjọ náà.
Wọ́n ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni nǹkan tí ẹni tó ṣe fídíò ń pa nítorí kò sí nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀.
Fídíò náà tó gba orí ayélujára kan ṣàfihàn àwọn òṣìṣẹ́ INEC tẹ̀ka FESTAC Town, ìjọba ìbílẹ̀ Amuwo Odofin, ìpínlẹ̀ Eko tí wọ́n ń yọ nọ́mbà káàdì ìdìbò ìyẹn VIN tí wọ́n sì ń kọ ọ́ sórí fóònù wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
INEC ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan tó dùn mọ́ àwọn nínú ni wí pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ń wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí, síbẹ̀ ó yẹ kí wọ́n máa wádìí ohun gbogbo láti rí àrídájú rẹ̀ mú dípò kí wọ́n máa gbé ìròyìn irọ́.
Àtẹ̀jáde tí alága ẹ̀ka tó wà fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ INEC, Festus Okoye fi síta ní nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ́fíìsì INEC tí ọkùnrin náà lọ jẹ́ ìgbésẹ̀ tuntun tí àwọn ń gbé láti fi àwọn káàdì ìdìbò tí àwọn ènìyàn kò gbà sórí ayélujára.
Okoye ní lára ìlànà tuntun tí àwọn gbé kalẹ̀ ní láti fi àwọn nọ́mbà káàdì ìdìbò tí àwọn ènìyàn láti wá gbà sórí ayélujára kí àwọn ènìyàn náà le mọ ibi tó yẹ kí wọ́n ti gbà á.
Ó ní láti lè ri dájú pé àwọn ènìyàn gba káàdì ìdìbò wọn dáadáa, INEC ti bẹ̀rẹ̀ àwọn ètò èyí tí ṣóṣe àmúlò orí ayélujára náà wà lára rẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ tuntun yìí fi àyè gba àwọn tó bá ti forúkọ sílẹ̀ fún káàdì ìdìbò ní àǹfàní láti wò ó bóyá káàdì ìdìbò wọn ti wà nílẹ̀ fún gbígbà àti láti mọ ibi tí wọ́n máa ti gbà á.

Oríṣun àwòrán, INEC/TWITTER

Oríṣun àwòrán, INEC/TWITTER
Okoye fi kun pé ohun tí àwọn ènìyàn kàn nílò láti ṣe ni fi orúkọ tàbí nọ́mbà VIN wón sórí ayélujára, gbogbo nǹkan nípa wọn yóò jáde láti mọ ibi tí wọ́n ti máa gba káàdì ìdìbò wọn.
“Ìgbésẹ̀ yìí máa mú kí gbígba káàdì ìdìbò rọrùn ṣùgbọ́n èyí kò dá àwọn tó bá fẹ́ lọ sí ọ́fíìsì láti lọ gba káàdì dúró.”
“Gbogbo àwọn káàdì ìdìbò tuntun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ní ọdún láàárín oṣù kìíní sí oṣù keje ọdún 2022 ni a ti fi nọ́mbà ti wọn sórí ayélujára nítorí náà ni àwọn kò ṣe nílò kí wọ́n fi nọ́mbà ti wọn sórí rẹ̀.”
Okoye ní gbogbo àwọn tí wọ́n ṣaájú ìgbà yìí ni àwọn nílò láti fi VIN wọn sórí ayélujára fúnra wọn.
Bákan náà ló ní àwọn kò ní yẹ̀bàá láti ri dájú pé àwọn ṣètò ìdìbò tó ní ẹja ń bákàn nínú.















