Ọwọ́ ọlọ́pàá Kwara tẹ afurasí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gún (15) kan tó ṣekú pa alágbàtọ́ rẹ̀ ní Kwara

Aworan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọwọ sinku ofin awọn ọlọpaa Kwara ti tẹ ọmọ ọkunrin ọlọdunmẹẹdogun kan ti wọn fura si pe o pa alagbatọ rẹ ni Ilorin ni Ipinlẹ Kwara.

Orukọ afurasi ọdaran naa ni Gobri Yusuf, iya alagbatọ to si sekupa, yii jẹ ẹgbọn mọmọ rẹ to ti doloogbe saaju

Iya yii, ti wọn n pe ni Morrow, ni wọn pa sinu ile rẹ ni Ilorin lọjọ Kẹrinla osu kinni ọdun yii.

Orógùn àti òbẹ ni wọ́n fi lu ìyá Morrow pa

Awọn ohun ti ọdọkunrin ọun fi pa iya yii ni awọn ohun ilo ni kisini bii, paanu idana, orogun, ọbẹ ati iwọn.

Kí ni ni ọlọ́pàá sọ nípa rẹ

Igba toun fidi ọrọ naa mulẹ ni ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹfa osu kẹta ọdun yii, ọga agba ajọ ọlọpaa ni Kwara, Adekimi Ojo sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyi to bani ninujẹ jọjọ.

Ojo sọ pe funra oun loun fọrọ we afurasi naa lẹnu nigba iwadii.

O ni iwadii oun si fihan pe afurasi naa ti saaju gbiyanju ni igba meji lati pa oloogbe naa pẹlu majele sugbọn ti o ku naa ko to wa pada rii pa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Afurasi naa ti gbiyanju ni ẹmeeji ọtọtọ lati pa arabinrin naa nipa dida oogun apa kokoro (sniper) sinu ọbẹ ati eso ẹgusi olomi (watermelon) rẹ sugbọn ti ko jẹ nigba ti o gbọ oorun rẹ.

"O kọkọ darukọ eeyan kan ko to tun pada sọ wi pe, oun nikan loun ṣe isẹ ibi yii.

Ọga ọlọpaa naa fi kun-un pe, wọn ti ran afurasi naa lati lọ ra epo bentiroolu ati awọn nnkan mii wa ki iṣẹlẹ naa to waye.

"Bi o se gbe bẹntiroolu naa de naa ni o lọ da sinu ẹrọ amunawa nigba ti obinrin naa n wẹ.

"O jọ bi ẹni pe, o se eyi lati da ariwo silẹ ki ẹnikẹni ma baa gbọ ohun toun sẹlẹ ninu ile.

"Iwadii pada fihan pe, ẹyin ilẹkun ni afurasi naa sa pamọ si ko to paa pẹlu awọn ohun ilo ile.

"Nigba toun ṣe isẹ laabi yi ni arabinrin naa pede kan sita pe 'iwọ kọ lo yẹ ki o pa mi o'.

"Lẹyin ti o rii pe o ti ku tan, o fi ẹrọ amunawa naa kalẹ ni titan o si lọ ra ounjẹ adiyẹ ti o jẹ ara isẹ ti oloogbe naa ran-an.

"Lara ohun ti a gba latẹnu rẹ, afurasi naa jẹwọ pe oun wu iwa ika naa nitori iwa inunibini ti oun ni si oloogbe ọhun.

"Ṣe ni o sọ pe, oloogbe naa maa n yọ oun lẹnu o si tun maa n na oun fun iwa ibajẹ.

Ọga ọlọpaa naa salaye pe, "ipe pajawiri ni a gba ni ọjọ kẹrinla osu kini ọdun yii ni nnkan bii aago mẹjọ abọ alẹ nipa obinrin kan ti wọn ba ninu agbara ẹjẹ ninu ile rẹ.

"Awọn ọlọpaa gbera sọ lẹsẹkẹsẹ wọn si bẹrẹ iwadii ti o fi han pe, afurasi naa fara pamọ si ẹyin ilẹkun, o si kọlu arabinrin naa nibi to ti n wẹ pẹlu awọn ohun ilo ninu ile.

"Afurasi naa parọ aṣọ rẹ nigba to ṣe eyi tan, o si jade bi ẹni pe, o lọ jisẹ ti wọn ran-an ni.

"Ọna lo ti pade ọkọ oloogbe yi ti o pada sile lati ba iyawo rẹ to ti ku.

Ǹjẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gún lè fojú balé ẹjọ́

Ọga ọlọpaa naa wa sọ pe afurasi naa yoo wa ni ikawọ awọn, awọn yoo si wọ ọ lọ ile ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari.