Àwọn olùjọsìn tí wọ́n jígbé nílé Ìjọsìn Cẹ̀lẹ́ n'ilu Uso gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn òbítíbitì owó.

Aworan ile ijọsin Uso
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ti wọn jigbe ni ile ijọsin Celestial Church n'ilu Uso nijọba ibilẹ Owo ti gba itusilẹ bayi lẹyin ti awọn ẹbi wọn san owo itusilẹ wọn.

Awọn marun-un ti wọn jigbe naa ni wọn tu silẹ ni asalẹ ọjọ Aje ọjọ keji oṣu kẹta ọdun yi ni agbegbe Ilado nijọba ibilẹ Ariwa Akure.

Awọn ẹbi awọn ti wọn jigbe naa sọ di mimọ pe wọn san millọnu mẹsan an naira.

BBC Yoruba kan si ile ijọsin naa, ọkan lara adari ile ijosin naa sọ di mimọ pe wọn tu awọn eniyan naa silẹ lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ti n se idunadura pẹlu awọn ajinigbe naa.

Iroyin itusilẹ awọn ti wọn jigbe naa waye lẹyin awuyewuye to suyọ, bí ileeṣẹ Ọlọpaa ṣe fi lede saaju pe wọn fi panpẹ ọba mu lara awọn ajinigbe naa, ti wọn si tu awọn kan silẹ lara wọn.

Awọn ẹbi awọn ti wọn jigbe naa sọ pe irọ to jina si ootọ ni ọrọ ti ileeṣẹ Ọlọpaa sọ, wọn salaye pe awọn marun ti wọn jigbe naa ni wọn lọ gba pada pẹlu Millionu mẹsan naira.

Ọkan lara alagba ijọ naa salaye pe ogoji milionu naira ni awọn ajinigbe naa kọkọ bere titi ti wọn fi ṣe idunadura ti wọn si san millionu mẹsan naira.

Awọn olugbe ilu Uso fi idunu wọn han lori iṣẹlẹ naa, wọn wá kesi ijọba lati wa ojutu si isoro eto abo ti Ipinlẹ Ondo koju.

Wọn sọ pe ijọba Lucky Aiyedatiwa gbọdọ ji giri ki wọn si ri daju pe wọn ro awọn esọ alaabo lagbara lati le koju awọn ajinigbe ati awọn agbebọn to n sọsẹ nipinlẹ Ondo

Kí ní Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀?

Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo Jimoh Abayomi ti fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn ti wọn jigbe ni ile ijọsin Cele lọsẹ ti o kọja ti gba ominira.

O sọ pe ileeṣẹ Ọlọpaa ti bẹrẹ isẹ lati sawari awọn ajinigbe naa ki wọn si fi wọn jofin.

O fi dá gbogbo olugbe Ipinlẹ Ondo loju pe awọn ikọ ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo labẹ idari Kọmisọna Lawal Adebowale yoo sawari awọn ajinigbe naa, wọn yoo si fi wọn jofin.

O wa rọ awọn ara ilu lati maa joye oju ni alakan fi ń sọri ki wọn si maa fi iroyin ohun to ba n sẹlẹ ni ayika wọn to awọn agbofinro leti lasiko.

Alukoro naa ko sọ ohunkohun lori owo itusilẹ ti awọn ẹbi awọn ti wọn jigbe naa sọ pe wọn san.