Ṣé lóòótọ́ ni Tinubu ń pín #30,000 fún àwọn ènìyàn?

Oríṣun àwòrán, APC
Ẹgbẹ oṣelu APC ti ki kede pe atẹjisẹ kan to gba ori ayelujara kan pe oludije aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu n pin ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira fun awọn eeyan ni o jẹ iro nla ati pe iroyin ofege ni.
Atẹjisẹ ọhun ni awọn kan kọ ni ede Hausa, ti wọn si n pe awọn eeyan lati wa si agbegbe kan lati wa gba owo ti n ẹgbẹ iponlogo Tinubu/Shettima n pin fun awọn eeyan.
Lati ninu oṣu kọkanla ni atẹjisẹ ọhun ti n tan kiri lori ayelujara, ti awọn si n pin kiri fun awọ0n eeyan wọn yoku lori ikan ibanisọrọ Whatsapp. Atẹjisẹ naa ni akọle "Tinubu/Shettima dun awọn ọmọ Naijiria ni N30,000 lati fi ponlogo ibo fun ohun."
"Ẹ ma bọ lati ki ẹ wa wo boya orukọ yin wa lara awọn ti yoo gbe N30,000 lati lọwọ Tinubu."
Ayederu ni atẹjisẹ naa- Ẹgbẹ iponlogo Tinubu/Shettima
Gẹgẹ bii wọn ṣe lọdun 2015 ati 2019, ẹgbẹ oṣelu APC ti kede pe awọn nilo iranlọwọ owo lati ọdọ awọn ọmọ Naijiria saaju eto idibo ọdun 2023. Awọn alaatilẹyin ẹgbẹ oṣelu naa, to fi jẹ, oluranlọwọ aarẹ lori ayelujara, Bashir Ahmed, ti bọ si ori ayelujara ni ọpọ igba lati bere fun iranlọwọ lọwọ awọn ọmọ Naijria,
Ẹgbẹ iponlogo Tinubu/Shettima fi nomba banki sita fun awọn to ba fẹ ran wọn lọwọ lati fi owo si ibẹ
"Ẹ ran wa lọwọ lati mu ileri wa si imusẹ lori orilẹede Naijria."
A wa gan nilo iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ iponlogo ibo Tinubu/Shettima fi tako atẹjisẹ naa ni iro nla ni, ti ko si ti ọdọ awọn wa rara.
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Festus Kayemo ni awọn ẹgbẹ alatako ni wọn wa gbogbo ọna lati ṣe akoba fun ẹgbẹ oṣelu APC saaju eto idibo lọdun 2023.
"A ri atẹjisẹ ọhun sugbọn ọdọ wa ko lo ti jade."
"Awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lo n gbe awọn igbesẹ lati fi tan awọn ọmọ orilẹede Naijria."












