Ọmọ ọdún méjìdínlógún di olórí ìlú l'Ámẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, Jaylensmith/Facebook
Ọmọ ọdun mejidinlogun, Jaylen Smith ni wọn ti diboyan lati ṣiṣẹ bi alakọso ilu ti o kere julo ni ila-oorun Arkansas ni orilẹede Amẹrika.
Smith jẹ ọkan ninu awọn ọdọ ti o kere lọjọ ori lati ṣiṣẹ bi adari ilu ni Amẹrika.
Jaylen Smith ẹni ti o ṣẹṣẹ pari ẹkọ girama ninu oṣu karun-un ọdun yii ni wọn diboyan ni ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii gẹgẹ bi adari ilu Earle to jẹ miile ọgbọn si iwọ oorun Memphis ni ilu Tenesse.
Jaylen Smith kọ ni ẹnì akoko to jẹ ọmọ ọdun méjìdínlógún ti wọn maa diboyan gẹgẹ bi adari ilu lorilẹ ede Amẹrika.
Ninu ọrọ rẹ ti o fi lede lori ẹrọ ayelujara Facebook Smith nigba ti oun ti jawe olubori gege bi oludari ilu, i ọtun yoo deba Earle Arkansas.
Smith ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democrat jawe olubori ninu ilu Earle ti o ni olugbe to to ẹgbẹ́sán niye.
Ninu ọrọ rẹ ti o fi lede lori ẹrọ ayelujara Facebook Smith ni igba ọtun yoo deba Earle Arkansas bi oun ṣe jawe olubori gege bi oludari ilu naa.
Smith ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democrat jawe olubori ninu ilu Earle ti o ni olugbe to to ẹgbẹsan niye.
Nigba ti o n dupẹ lọwọ awọn ara ilu Earle ti wọn diboyan-an pẹlu ibo ojilenigb din marun-un nigba ti alatako re si ni ibo marundinlaadọwa.
O ni oun tí ohun yoo ṣe gẹgẹ bi adari ilu ni lati ṣe atunto si ikọ ọlọpaa, titun awọn idominugere ṣe ati lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ara ilu.
Smith ẹni ti o ti di ipo oṣelu mu nigba ti o wa ni ile ẹkọ girama ni oun ni aniyan lati mu ile itaja wa si inu ilu Earle.
Nigba ti o fi idunnu rẹ han lori ipo oṣelu ti wọn diboyan si, o ni akoko ti ohun di ipo oṣelu mu yii naa da nitori ohun ni alawọ dudu akọkọ ti wọn diboyan.
Smith yoo tẹsiwaju ninu iwe kika rẹ nitori oni erongba lati di agbejoro lọjọ iwaju.














