Ọmọ jayéjayé tó mọ ayé ń jẹ ni mí èmi kìí ṣe oníjìbìtì – Dbanj

Oríṣun àwòrán, Instagram/Daniel Banjo/iambangalee
Gbajumọ akọrin takasufe Ọladapọ Oyebanjọ ti ọpọ mọ si D’Banj ti ṣalaye pe lootọ ni ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ ati iwa ibajẹ miran lorilẹede Naijiria, ICPC mu oun si ahamọ wọn ṣugbọn oun kii ṣe onijibiti rara.
D’banj sọ ninu ọrọ kan to fi sita loju opo Instagram rẹ pe lootọ ọmọ jayejaye to fẹran aye jijẹ loun o ṣugbọn ko si igba kan ti oun ti ọwọ oun bọ sọọlọ iwa jibiti ri.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
“Mo dupẹ pupọ fun gbogbo agbaye o. Wọn pe mi lori iwadii kan ti ajọ ICPC nṣe. Mo ti ran aj naa lọwọ pẹlu ohun gbogbo ti mo mọ, bẹẹni mo si ni igbọkanle ninu wọn pe wọn yoo wadi ododo jade. Mi o lọwọ ninu iwa jibiti, ohun kan ṣoṣo ti mo mọọ ṣe ni lati maa jaye. Wọn da mi silẹ nitori ipo mi lawujọ nitori pe wọn ko ri tabi ba ohunkohun ni ikawọ mi.”
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, D'Banj kúrò ní àhámọ́ ICPC

Oríṣun àwòrán, iambangalee
Gbajugbaja olorin Oladapo Oyebanjo, ti gbogbo ọpọ ẹniyan mọ si D’banj, ti gba itusilẹ ni ahamọ ajọ ICPC lẹyin ti wọn mu fun ẹsun lilu owo N-Power ni ponpo.
Ọjọ Ẹti ni wọn fi D’Banj silẹ lẹyin to ti lo nnkan bii wakati méjíléláàdọ́rin ni atimọle ikọ naa.
Agbẹjọro rẹ, Pelumi Olajengbesi, lo fi iroyin naa led eloju opo Facebook rẹ.
O ni akọrin D’banj fọwọsowọpọ pẹlu igbimọ oluwadii ICPC lakoko iwadii rẹ.
Olajengbesi sọ pe wọn tu D’Banj silẹ nitori o jẹ ẹniti o jẹ gbajugbaja ṣugbọn ko jẹrisi boya ICPC ba gba beeli olorin naa.
O tun sọ pe ICPC ko tii tọpa eyikeyi ẹri to fihan pe D'banj jẹbi ẹsun tiwọn fi kan, eleyii ti a ko rii aridaju rẹ lakoko yii.
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
Wọn fẹsun kan D’Banj owo ti iye rẹ aadọta ọkẹ millionu naira ti ijọba Naijiria ti ya sọtọ fun iṣẹ akanṣe N-Power lọdun 2016 lati boju to airiṣẹṣe awọn ọdọ ati idagbasoke awujọ.
Ọjọ iṣegun ICPC fẹsun kan D’Banj pe o kuna lati wa fun ifọrọwanilẹnuwo ṣaaju lẹyin ti wọn ti kọkọ fi iwe pe lọpọlọpọ igba.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Dbanj kò lọ́wọ́ nínú ṣíṣé owó N-power mọ́ku-mọ̀ku- Agbẹjọ́ro rẹ̀ sọ òkò ọ̀rọ̀ sí àjọ̀ ICPC

Oríṣun àwòrán, ICPC
Agbẹjọro olorin takasufe, Oladapo Oyebanjo, tí ọpọ mọ si Dbanj tí gbe lẹyin onibara rẹ lẹyin ti ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, ICPC tí olorin naa mọ atimọle lana.
Maryam Musa, ninu atẹjade kan to fi sita lọjọru ọsẹ yii ni o han gbangba pe Dbanj ko lọwọ ninu ẹsun tí ajọ ICPC fi kan rara nítorí ko ki n ba wọn kopa ninu isowo ti ko ba ofin mu.
Agbẹjọro Musa ni iwadi ti bẹrẹ lori ẹsun tí wọn fi kan lori owo N power.
O tẹsiwaju wa pe ajọ ICPC ransẹ si Dbanj sugbọn ko ni anfani lati lọ rí wọn nítorí isẹ rẹ níbi oṣu kan sẹyin
To si fi iwe ransẹ si ajọ ọhun, eyi ti awọn Agbẹjọro rẹ mọ si pe o wa lorilẹede South Africa, tí o si ṣe ileri lati wa rí wọn kete to ba pada de si Orilẹede Naijiria.
Agbẹjọrọ Dbanj sọ pe:
"Lọjọ Aje, ọjọ Karun un, oṣu kejila, Dbanj gbera funra rẹ lati yoju sì ajọ ICPC ni deede ago meji ọsan ni kete to de si ilu Abuja.
"Awọn osisẹ ajọ naa ni ko pada wa lọjọ kejì nítorí ọjọ ti lọ lati bẹrẹ ifọrọwerọ pẹlu rẹ.
"Dbanj pada lọ lọjọ kejì, iyẹn ọjọ kẹfa, oṣu kejila to si fi ara rẹ kalẹ fun ajọ ọhun fun ifọrọwerọ.
Gẹgẹ bii Musa ṣe sọ, Dbanj n rọ ajọ ICPC lati ṣe ìwadii wọn daada ki wọn si ripe wọn mu awọn eeyan to fẹ ba orúkọ rẹ jẹ wa siwaju ofin.
"A n ro awọn eeyan lati yago fun ofege iroyin pe awọn ajọ naa lọ mú, fun ara rẹ lo fara rẹ kalẹ fun ajọ ICPC niluu Abuja."q
D’Banj dèrò àtìmọ́lé àjọ ICPC lórí ẹ̀sùn lílu owó N-Power ní pónpó
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, ICPC, ti fiṣikun ofin mu gbajugbaja olorin takasufe, Oladipo Daniel Oyebanjo, ti ọpọ mọ si D’Banj.
ICPC ni awọn mu olorin naa, o si ti wa ni ahamọ awọn lori ẹsun lilu jibibitu pẹlu owo eto adojutofo N-Power ti ijọba apapọ gbe kalẹ lọdun 2016.
Ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ, ajọ naa sọ pe awọn mu D’Banj lẹyin ti awọn eeyan ti kọ ọpọlọpọ iwe si awọn lori ọrọ owo naa.
Atẹjade ọhun ni “A fẹ fi akoko yii sọ pe Oladipo Daniel Oyebanjo, ti ọpọ mọ si D’Banj ti wa ni ahamọ wa lori ẹsun to ni ṣe pẹlu jibiti owo N-Power.”
“Eto N-Power jẹ eto ti ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari gbe kalẹ lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2016, lati tan iṣoro airiṣẹ ṣe laarin awọn ọdọ.”
“ICPC si ti gba ọpọlọpọ atẹjiṣẹ nipa bi awọn kan ṣe n fi eto naa lu jibiti, paapaa nipa awọn to n ṣe N-Power ti ijọba n san owo oṣu fun amọ ti owo naa ko de ọdọ wọn.”
A fi iwe pe D'banj amọ ko yọju si wa
Ṣaaju ni ICPC ti kọkọ fi iwe pe D’Banj lati wa sọ tẹnu rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an amọ o kọ jalẹ lati yọju si ajọ ọhun.
Iroyin ni eyii lo mu ki wọn gbe igbesẹ lati fi ṣikun ofin mu nibikibi boya ni Naijiria ni tabi loke okun ko to di pe o jọwọ ara rẹ.
ICPC ni nnkan bii eeyan mẹwaa lawọn ti fi iwe pe lati wa sọ tẹnu wọn lori ọrọ owo N-Power naa lati nnkan bii oṣe melokan sẹyin.
Wọn ni pupọ ninu awọn eeyan naa ni wọn ti gba beeli wọn lẹyin ti wọn fi ọrọ wa wọn lẹnuwo tan ni ọọfisi ICPC.
Wayi o, iroyin ni o ṣeeṣe ki D’Banj foju bale ẹjọ laipẹ ki ICPC le lanfaani lati fi silẹ ni ahamọ wọn fun akoko diẹ si fun iwadii to peye lori ẹsun ti wọn fi kan an.












