Buhari ti gbìyànjú lórí ètò aàbò, ó ti gé ìyẹ́ apa ISWAP ṣùgbọ́n má a gbìyànjú síi- Bola Tinubu
Awọn ijọba ilẹ okeere ko ran ijọba Buhari lọwọ lati ta ohun ija ogun fun wa.- Tinubu
Oludije sipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oselu APC tun sọ nipa erongba rẹ fun awọn eniyan Naijiria pe: Eto abo, igbesoke eto ọrọ aje ati idagbasoke ilu ki awọn ọmọ Naijiria le ri iṣẹ ṣẹ, ki a si mu ọwọngọ kuro laarin ilu. A oo tun ṣe ayẹwo ọrọ aje wa. A ni lati gbe igbesẹ lori afikun owo epo, ki a si yọ afikun naa.
Tinubu ṣalaye fun BBC pe: Adinku ti de ba. Mo maa kin Buhari lẹyin lori iyẹn. Nigba naa lọhun, ijọba ibilẹ mẹtadinlogun ati nnkan bi ipinlẹ mẹrin ni awọn alakakiti ẹsin n ṣakoso ni Naijiria, ko ri bẹẹ mọ bayii.
O rọrun lati bẹrẹ rugudu amọ o ṣoro lati pana rugudu naa. Ni bayii, Buhari ti ge iyẹ apa ISWAP amọ ko tii ṣẹgun wọn patapata.
Wọn maa sọrọ diẹ nipa ohun ija ogun pẹlu imọ ẹrọ to yẹ ki a lo lati ṣẹgun wọn patapata.
Awọn ijọba ilẹ okeere ko ran ijọba Buhari lọwọ lati ta ohun ija ogun fun wa.
- Èmi ni mo dáńgájíá jùlọ nínú gbogbo àwọn olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà
- Baba mí fí ọwọ́ sí Folarin gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ àwọn méjèèjì- Ọmọ Alao Akala-
- À-wọn agbégbọn jí kọmíṣọ́nà gbé lọ ní Benue wo ibi tí ìwádìí dé dúró
- CBN kéde gbèdéke 100,000 owo tí o le gbà ní ATM, POS àti bánkì lọ́sẹ̀
- Ààrẹ láti ẹkùn gúsù Nàìjíríà ni mo fọwọ́sí fún ìdìbò 2023 – Obasanjo-
- Aya àti ọ̀rẹ́ kọ̀ mí sílẹ̀ lẹ́yìn ti mo pàdánù ẹ̀sẹ̀ mi ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti ṣagbe ni mo ṣe padà síṣẹ́ wẹ́dà- Yussuf