Yussuf Adekola: Olè ló sọ mi di aláìlẹ́sẹ̀ ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ pé mo ṣì wà láyé

Àkọlé fídíò, Yussuf Adekola: Olè ló sọ mi di aláìlẹ́sẹ̀ ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ pé mo ṣì wà láyé

Iṣẹ wẹda ni mo kọ lati ọdọ Baba mi, ohun ni mo pada si lẹyin ti mo padanu ẹsẹ mi- Yussuf Adekola

BBC Yoruba wa Yussuf Adekola kan lẹyin iroyin nipa rẹ pe awọn gbewiri gba ọkada tuntun to ṣẹṣẹ ra.

Yussuf Adekola ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lọjọ to gbe ero naa ti ko si mọ pe ole to fẹ gab ọkada tuntun ti oun ra ni.

O sọ bo ṣe rinrinajo aye rẹ to lo ọdun kan nile iwosan fun itọju ọpa ẹyin rẹ ti ole yinbọn si.

Yussuf salaye bi aya rẹṣe kọọ silẹ lẹyin iṣẹlẹ naa, koda o ni pe ọpọ ọrẹ lo kọ oun silẹ ṣugbọn oun kó lati ṣe agbe.

O gba awọn to ni ipenija nimọran lati wa iṣẹ ọwọ kan ṣe tabi ọja tita lai maa ṣagbe.

Bakan naa lo fi imoore han si Oldoumare pe oun ṣi wa laye.

O ṣalaye ọna to fi bori ironu ati ibanujẹ ọkan ko to pada si idi iṣẹ jorinjorin.