Ààrẹ South Africa sọ̀rọ̀ sókè lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn lílu $4m ní póńpó kàn án

Cyril Ramaphosa:

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aarẹ South Africa, Cyril Ramaphosa ti sọ pe ọwọ ẹgbẹ oṣelu oun ni ọjọ ọla oun wa bayii, eyii to jẹ ọrọ akọkọ ti yoo sọ lati igba ti wọn ti fẹsun iwa ibajẹ kan an.

Ṣaaju ni awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ti kọkọ sọ pe o gbọdọ kọwe fi ipo silẹ ni, lẹyin ti igbimọ awọn agbẹjọro kan fẹnuko pe o ṣeeṣe ko ti ṣẹ si ofin.

Amọ agbẹnusọ rẹ sọ lopin ọsẹ pe yoo tẹsiwaju lati maa ja fun ẹtọ rẹ.

Aarẹ ọhun funra rẹ ti wa sọ pe ọwọ awọn adari ẹgbẹ oun ni ọrọ naa ku si bayii lati sọ igbesẹ to kan fun oun.

Awọn adari ẹgbẹ naa, Africa National Congress, ANC, ti n ṣe ipade lọwọ bayii ni niluu Johannesburg lati mọ igbesẹ to kan.

Nigba to ba awọn akọroyin sọrọ nibi ipade ọhun, o ni igbimọ ẹgbẹ ANC fun oun laye lati má darapọ mọ ipade naa ki wọn le ni anfaani lati sọrọ bo ṣe ri lọkan wọn lai si ibẹru kankan.

O ni “Ọwọ awọn ọmọ igbimọ adari ẹgbẹ lo ku si bayii, oun ti wọn ba si sọ ni mo maa tẹlẹ.”

Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ

Wahala naa bẹrẹ fun Ramaphosa ninu oṣu Kẹfa ọdun 2022 yii, nigba ti agba ọtẹlẹmuyẹ ọmọ South Africa kan, Arthur Fraser kọ iwe si agọ ọlọpaa, to si fẹsun kan Aarẹ Ramaphosa pe o lu owo ti iye rẹ miliọnu mẹrin dọla ni ponpo nipaṣẹ oko rẹ, Phala Phala game farm lọdun 2020.

Ramaphosa ni lootọ ni owo naa sọnu, amọ owo naa ko ju ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta dọla lọ, dipo miliọnu mẹrin ti ọkunrin naa pe.

Ramaphosa tun sọ pe owo naa wọle lẹyin ti oun ta ẹranko ẹfọn kan, amọ igbimọ oluwadi to n ṣe iwadii ẹsun naa ni o ṣoro lati gba ọrọ Ramaphosa gbọ.

Wayi o, agbẹnuṣo Ramaphosa, Vincent Magwenya ti sọ pe Aarẹ ọhun ko ṣetan lati kọwe fi ipo rẹ silẹ nitori ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ.