'Àwàdà kẹríkẹrì ni ẹ̀sùn pé Oyetola kó ìgò òróró ọgbẹ́ ‘Methylated spirit ' kúrò nílé ìjọba l’ Osun'

Gboyega Oyetola àti Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Itakangbọn to n waye laarin ijọba ana nipinlẹ Ọṣun labẹ Adegboyega Oyetọla ati ìjọba to wa lóde lọwọ labẹ Ademọla Adeleke lori awọn dukia ilu ti wọn ni awọn oṣiṣẹ ìjọba ana fọ ko tii pari.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina Adeleke, Rasheed Ọlawale, fi sita ṣalaye pe ijọba ana ti gba pe lootọ ni awọn kan fọ ile ijọba, ninu eyi ti ibugbe igbakeji gomina ipinlẹ naa at’awọn ile ijọba miran wa, labẹ oun ki oun to fi ipo silẹ.

Ijọba ipinlẹ Ọsun sọ ọ ninu atẹjade naa lọjọ Aiku pe ijọba ana labẹ Adegboyega Oyetọla ti tẹwọ gba aṣiṣe rẹ o ninu atẹjade kan ti Funkẹ Ẹgbẹmode to jẹ kọmiṣọna feto iroyin fi sita.

O ni ki I ṣe ọrọ oṣelu ijoba Adeleke ni ijọba Adeleke n fi ọrọ naa ṣe bi ko ṣe lati fi bi ipo ti ipinlẹ naa wa ṣe ri to awọn araalu leti gẹgẹ bi ojuse rẹ.

Awada kẹrikẹri ni ẹsun ile ijọba fifọ ti gomina Adeleke, ẹgbẹ oṣelu PDP n gbe kiri – Funkẹ Ẹgbẹmode, kọmiṣọna feto iroyin labẹ gomina Oyetọla

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu atẹjade kan eyi ti Funkẹ Ẹgbẹmode to jẹ kọmiṣọna feto iroyin labẹ gomina Oyetọla ti kọkọ fi sita, ijọba ana naa ni lootọ ni won ti kẹẹfin pe awọn arungun kan ti n fọ awọn ile ijọba wọnyi ki gomina Oyetọla to fa okun ijọba le Adeleke lọwọ.

Ẹgbẹmode ni awọn si ti kọwe si ọga agba ajọ abo ẹni labo ilu, NSCDC ni ipinlẹ Ọṣun lori rẹ ni ọjọ karundinlọgbọn oṣù kọkànlá ti wọn si beere fun igbesẹ awọn agbofinro lati dẹkun iṣẹ laabi naa.

O ni awada kẹrikẹri ni ẹsun ti gomina Adeleke ati ijọba rẹ n fi sun kiri ni gbagede ilu pe Oyetọla fọ ile ijọba o ko gbogbo dukia ibẹ lọ paapaajulọ pẹlu fidio ti wọn fi sita nipa awon ohun wlo ile ti wọn ko ri lawọn ile kan ni ibugbe gomina at’awọn miran ro dipo oṣelu mu lasiko iṣejọba ana ni ipinlẹ Ọṣun.

Atẹjade naa ni gbogbo igbesẹ ti Gomina Adelek n gbe lati ba orukọ Adegboyega Oyetọla jeẹ ni bibẹẹkọ, awada nla ni ki eeyan maa fi ẹsun kan eeyan bii gomina Oyetọla pe o gbe ohun elo idana ile ijọba, igo ororo itọju ọgbẹ Methylated spirit…”

O ni “awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko da mọ” lo ṣe ọṣẹ yii nitori naa ki Adeleke ati ikọba rẹ ye ṣe bi ẹni pe saa kan oṣelu kọjá ọdún mẹrin.