‘Lóòtọ́ làwọn kọmíṣọ́nà kó ọkọ̀ ìjọba lọ ṣùgbọn gómìnà àná, Oyetọla fọwọ́ síi’

Adeleke ati Oyetọla n ki ara wọn

Oríṣun àwòrán, other

Lati ọjọ diẹ sẹyin ti ayipada ti de ba iṣejọba ni ipinlẹ ṣun ni ọrọ dukia ijba ti n da awuyewuye silẹ laarin ijọba to kogba wọle labẹ idari Adegboyega Oyetọla ati ijọba to wọle bayii labẹ akoso Ademọla Adeleke.

Gomina Ademọla Adeleke bọ sode lẹyin wakati diẹ to gba akoso ijba lati pari wo sita pe ida meji ninu mẹta awọn oṣiṣẹ to ba ijọba ana ṣiṣẹ ni wọn ko ọkọ ijọba atawọn dukia miran to wa ni ikawọ wọn lọ.

‘Awọn to lẹtọ si ọkọ ijọba ni wọn gbe e lọ lẹyin ti wọn gba aṣẹ’

Nibayii, adari akanṣe eto gbogbo lẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Sunday Akere ti fi to BBC News Yoruba leti pe lootọ ọkọ ijọba wa lọwọ kan bii kọmiṣọna ati bẹẹlọ ti wọn ba ijọba ana ṣiṣẹ ṣugbọn wọn ko jii gbe tabi gbe e lọna ẹburu ti ko ba ofin mu.

Akere sọ fun BBC News Yoruba pe nigba ti awọn kọmiṣọna, akọwe agba ati bẹẹbẹẹ nlọ, gomina ana, Adegboyega Oyetọla kọ iwe aṣẹ fun ọkọọkan wọn lati maa gbe ọkọ ijba ti wọn fi ṣiṣẹ lọ ni.

Akere ni eyi kii ṣe tuntun nitori bẹẹ lo ṣe n ri lawọn iṣejọba to ti lọ ni ipinlẹ naa bẹrẹ lati ori Bisi Akande to jẹ lọdun 1999 ti iṣejọba alagbada pada bẹrẹ.

Aworan Oyetola, ọkọ ijọba, ati Adeleke

Oríṣun àwòrán, Gboyega oyetola/ademola adeleke

“Ẹni ti ọkọ ba wa lọwọ rẹ, wọn fun laṣẹ pe ko maa gbe e lọ ni. Mi o dẹ ro wi pe eleyii jẹ ohun ti a ko riri. Awọn to jẹ bi kọmiṣọna ni ijọba gomina ana, Gboyega Oyetọla, ọkọ ti wọn lo, wọn ni ki wọn maa gbe e lọ.”

Ọgbẹni Akere ni apẹrẹ ti oun le ṣe ni igba ti oun jẹ kọmiṣọna ni ipinlẹ Ọṣun nigba ti awọn nlọ nigba naa, gbogbo wọn ni gomina igba naa, Rauf Arẹgbẹṣọla ni ko maa gbe ọkọ ti wọn lo lọ.

Adari akanṣe eto gbogbo lẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọsun naa wa sọ pe oṣelu lasan lariwo ti Adeleke n pa.

Ida meji ninu mẹta awọn to ba gomina ana ṣiṣẹ ni wọn ti ko dukia ijọba lọ - Adeleke

Gomina Ademọla Adeleke yọju rẹ sita lẹyin to gba iṣakoso ijọba ipinlẹ Ọṣun pe ida meji ninu mẹta awọn to ṣiṣẹ pẹlu gomina ana ni ipinlẹ naa ni awọn ṣe akiyesi pe awọn dukia ijba to wa ni ikawọ wọn ti poora.

Adeleke sọ ọ ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Rasheed Ọlawale fi sita nigba naa pe jọ meji loun fun wọn nigba naa lati fi da wọn pada bi wọn ko ba fẹ kan idin ninu iyọ.

Bakan naa lo sọ ọ ninu atẹjade ọhun pe awọn ohun elo ijọba bii kọmputa ati ina ara ile ni wọn yọ lọ.

Gbogbo dukia ile igbakeji gomina lo ti poora

Lara awọn ọrọ to ṣi n fa awuyewuye ni ti ipo ti igbakeji gomina Adeleke, Ọgbẹni Kọla Adewusi sọ pe oun ba ile ijba to wa fun igbakeji gomina ni ilu osogbo.

Adewusi ni igba ti oun de inu ile igbakeji gomina, korofo gbayawu loun baa pẹlu bi wọn ti ṣe yọ awọn ohun ọṣọ ile titi kan awọn ohun elo idana ni ile idana lọ.

Ko si dukia ile igbakeji kkan to wa ni ikawọ mi, gbogbo rẹ lo wa nibẹ - Benedict Alabi, igbakeji gomina ana ni ipinlẹ Ọṣun

Aworan igbakeji gomina ọṣun nibi eto ibura fun

Oríṣun àwòrán, Iyiọla Ọlayẹmi

Igbakeji gomina ni iṣejọba ana ni ipinlẹ Ọṣun, Benedict Alabi ti fsei fun igbakeji Gomina Adewusi. O niohun to jina si otitọ ni ati wi pe o ṣeeṣe ko jẹ wi pe igbakeji gomina tuntun ni ipinlẹ Ọṣun ko tii de ile ti ijba ya sọtọ fun igba keji ki o to maa fi ẹ̀ẹsun kan oun.

Igbakeji gomina Oyetọla, ṣalaye ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Gafar Suleiman fọwọsi pe ọkọ ijọba to wa fun igbakeji gomina ati ọkọ hilux meji ti awọn ẹṣọ agbofinro oun n lo nikan lọkọ to ba oun jade ni ile ijọba.

O ni awọn ọkọ naa ko si ṣa dede wọ akata oun bi ko ṣe pẹlu aṣẹ to yẹ.

Benedict Alabi, Igbakeji gomina ana ni ipinlẹ Ọṣun

Oríṣun àwòrán, Adegboyega Oyetola

O wa rọ igbakeji gomina tuntun naa lati dari gbogbo ohun to ba ṣokunkun si i nipa awọn dukia to wa ni ile igbakeji gomina si adari agba to n mojuto ọfiisi igbakeji gomina.

“A n sọ ọ laifọtape wi pe, ọwọ akojọpọ aga ile lọna mẹta, aga ati tabi yara ijẹun, ọpọlọpọ ẹrọ amule tutu, tẹlifiṣan, ẹrọ amohuntutu, ẹrọ idana atawọn ohun elo miran ni igbakeji gomina ana fi silẹ.”