Tinubu lẹ́bọ lẹ́rù, a kò lè máa fi òun àti Atiku wé ara wọn – Dino Melaye

Tinubu and Atiku

Oríṣun àwòrán, @officialABAT

 Agbẹnusọ fun ikọ ipolongo idibo Aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Dino Melaye ti sọ pe oniruru ohun ti ko bojumu lo so mọ oludije ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu, nigba ti ọrọ ko ri bẹẹ fun oludije ninu ẹgbẹ oun, Atiku Abubakar.

Melaye lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹlẹ Channels.

O ni gbogbo aye lo mọ itan aye Atiku ati ibi to ti ṣẹ wa, ko si da bii Tinubu ti awọn araalu ko mọ ipinlẹṣẹ rẹ.

Melaye sọ pe “Atiku gẹgẹ bii ẹnikan, ẹ le ka itan igbesi aye rẹ ti awọn eeyan kọ ati eyii ti oun funra rẹ kọ, ti ẹ ba si wo itan aye rẹ naa lọ si nnkan bii ọgbọn ọdun tabi ogoji ọdun sẹyin, ẹ o ri pe oun kan naa ni.”

“Ẹ le da awọn akẹgbẹ rẹ nile ẹkọ mọ, ẹ le ka nipa ile ẹkọ to ti kẹkọọ, ko si ariyanju nipa ibi to ti wa, ko si ariyanjiyan kankan nipa Atiku, bẹẹ ni ko si da bi Tinubu ti ko si ẹni to mọ nnkankan nipa rẹ.”

O tun sọ pe irọ ni ohun ti Adams Oshiomole sọ nigba kan pe Atiku ni ki awọn eeyan Ariwa má dibo fun ọmọ Yoruba tabi ọmọ Igbo kankan gẹgẹ bii Ararẹ Naijiria.

Melaye ni ọrọ ile ọti lasan ni, kii si ṣe nnkan to yẹ ki awọn ọmọ Naijiria ka si.

O fi kun pe ọmọ Naijiria rere ni Atiku, oun nikan si ni ipo Aarẹ tọ si ati ẹni ti awọn ọmọ Naijiria le fọkan tan.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, Atiku ninu igbiyanju rẹ lati di oludije ipo Aarẹ ẹgbẹ PDP ti ṣabẹwo si gbogbo kọrọkọndo Naijiria, amọ Tinubu ko bẹ awọn ipinlẹ to wa ni iwọ oorun Naijiria anbelete pe o ṣabẹwo si ilẹ Igbo ṣaaju eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC.

O sọ siwaju si pe baba olowo ni Atiku nitori o jẹ oniṣowo, amọ baba olowo ni Tinubu bo tilẹ jẹ pe ko ni owo kankan to n ṣe.

O pari ọrọ rẹ pe Atiku nikan lo le tun Naijiria ṣe, o si yẹ ki awọn eeyan fi ibo wọn gbe wọle lọdun to n bọ.