Ilẹ̀ rírì mú ẹ̀mí èèyàn méjì lọ ní Brazil, ọ̀pọ̀ àwọn míì di àwátì

Oríṣun àwòrán, Reuters
O kere tan, eeyan meji lo ti ku, nigba ti ọpọ awọn mii di awati lẹyin iṣẹlẹ ilẹ riri kan to waye ni Brazil.
Iṣẹlẹ naa waye lasiko ti yẹpẹ nla kan ya bo oju ọna BR-376 to wa niluu Paraná, eyii to kọlu nnkan bii ọkọ mọkanlelogun.
Awọn adoola ẹmi to lọ sibẹ sọ pe oju ọjọ ti ko ṣe dede ati agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye mu ko ṣoro fun awọn lati ṣiṣẹ daadaa.
Wọn ni nnkan bii ọgbọn eeyan lawọn ṣi n wa bayii.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aworan kan lati oju ofurufu ṣafihan han ọkọ ajagbe kan to ha si eti afara kan amọ awọn adoola ẹmi ti ri oku awakọ rẹ, João Pires, to jẹ ẹni ọdun mejilelọgota.
Ọkan lara awọn mọlẹbi ọkunrin naa ni gbogbo ọjọ aye rẹ lo fi n ṣiṣẹ awakọ ajagbe ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ wọn ko tii darukọ ẹni keji to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
Awakọ mii ti ọkọ rẹ ri sabẹ ilẹ naa, José Altair Biscaia ni ori ti kọ koyọ nibi iṣẹlẹ ọhun.
Biscaia ya fidio ara rẹ labẹ yẹpẹ to bo ori rẹ mọlẹ ki awọn adoola ẹmi to yọ jade, bo tilẹ jẹ pe ko farapa pupọ.
O sọ ninu fidio naa pe “Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun . Aarin ẹrọfọ naa ni mo wa bayii… gbogbo ara mi lo ti bo amọ mo ṣi wa laaye.”
Wayi o, eeyan mẹfa ni wọn ti ri yọ labẹ yẹpẹ ọhun, lara wọn si ni olori ilu Guaratuba, Roberto Justus.












