Ìyà gé orí ọmọ ara rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ Oṣù mẹ́wàá, bí ọwọ́ ọlọpàá ṣe tẹ̀ẹ́ nìyí

Ọlọpaa ti fi panpẹ ofin mu arabinrin kan latari ẹsun pe o ge ori ori ọmọ rẹ, ikoko ọmọbinrin to jẹ ọmọ Oṣu mẹwaa.
Iṣẹlẹ naa waye ni ilu Ugep nijọba ibilẹ Yakurr, ipinlẹ Cross River.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Irene Ugbo sọ fun BBC pe lootọ̀ ni iṣẹlẹ ọhun waye ni ọjọ Isegun.
O ni awọn eeyan tilẹ gbiyanju lati bẹrẹ si ni lu arabinrin naa to jẹ iya ọlọmọ meji amọ awọn ọlọpaa tete ko si aarin wọn.
Ṣe obinrin naa ni aarun ọpọlọ ni?
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa ṣe sọ, wọn gbe obinrin naa lọ si ẹka iṣewadii iwa ọdaran niwọn igba to ti jẹ pe ẹsun ipaniyan ni.
SP Irene sọ pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadi bayii.
Bakan naa lo ni wọn yoo ṣe ayẹwo ọpọlọ fun obinrin naa ki wọ́n to mọ igbesẹ to ki ti wọn yoo gbe.
“A wa lori ẹsun naa lati ri aridaju nnkan to mu u dan iru iwa bẹẹ wo,” agbẹnusọ ọlọpaa ti sọ bẹẹ.
Iṣẹlẹ awọn iya mii to pa ọmọ wọn
Eyi kii ṣe igba akọkọ ti ọlọpaa yoo fi panpẹ ofin mu awọn obinrin lori ẹsun pe wọn pa ọmọ wọn.
Iru awọn iroyin yii maa n mu ki awọn eeyan woye pe ki lo ṣẹlẹ gangan?
Irufẹ iṣẹlẹ bayii ti ṣẹlẹ ni ipinlẹ Enugu ri lọdun 2018 nibi ti arabinrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan ko si gbaga ọlọpaa latari ẹsun pe o pa ọmọ tuntun rẹ.
Awọn ọlọpaa fẹsun kan pe ẹni naa to n gbe ni Royal Lodge Agbani ni agbegbe Nkanu naa ti pa ọmọ rẹ ki awọn ara adugbo to de ibi to ti ṣẹlẹ.
Lafikun, iru iṣẹlẹ yii tun ti ṣẹlẹ ninu Oṣu Kẹwa Ọdun 2022 ni agbegbe Olocha-Adogba ni ilu Awgu nipinlẹ Enugu nibi ti arabinrin ẹni ọdun mejidinlogun ti kan ati iya rẹ bọ sọwọ ọlọpaa tori ẹsun pe wọn gbimọ pọ pa ọmọ to ṣẹṣẹ bi.
Ọlọpaa ni iwadii ti wọ́n kọkọ ṣe lo fihan pe iya ọmọ naa lo ọbẹ ile idana lati fi gun ọmọ ikoko naa tutu ti fi ku laipẹ igba to ṣẹṣẹ bi ọmọ ọhun.
Ni Anambra, arabinrin kan naa ko si gbaga ọlọpaa lẹyin ti wọn fẹsun kan pe o n na ọmọ rẹ, ọmọ́ ọdun mẹta titi doju iku ninu Oṣu Kẹwaa Ọdun 2022.
Iroyin jade pe nigba ti arabinrin naa rii pe oun ti pa ọmọ lo sare gbe oku rẹ sinu baagi to si lọ ju u sinu igbo ni Amikwo, Akwa tii ṣe olu ilu ipinlẹ naa.
Awọn araalu atawọn oṣiṣẹ alaabo lo kaa mu to si mu wọn lọ sinu igbo to ju oku ọmọ ọhun to ti n jẹra si.
Wọnyii ni diẹ lara awọn ẹsun bii eyi to maa n ṣẹlẹ loore koore.















