Èdè abínibí ni kẹ́ẹ máa fi kọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ alákọbẹrẹ báyìí; Ìjọba pàṣẹ!

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ijọba apapọ Orilẹede Naijiria ti buwọlu ofin tuntun to fi aye gba pe ki wọn máa fi ede abinibi kọ awọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ, eyi ti wọn ṣe ni dandan.
Nigba to n sọrọ pẹlu awọn akọroyin ile ìjọba loni. Minisita fun eto ẹkọ lorilẹede Naijiria, Adamu Adamu lo kede igbesẹ naa. O ni ìjọba mọ pe igbesẹ naa nira pupọ ṣugbọn o ṣe koko fun igbega aṣa ati iṣe awọn ede abinibi lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Ministry of Education
O tẹsiwaju pe loni, ó toto ede abinibi mọkandinlọgbọn tí ko si ẹnikakan to n sọ wọn, tí o si ni pe ìdí kan pataki ti awọn fi gbe igbesẹ naa kalẹ ni lati ri pe awọn akẹkọọ mọ ijinlẹ nínú ede abinibi wọn fún odidi ọdun mẹfa tí wọn ba lo ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ. Adamu ni igbesẹ naa ti bẹrẹ ni pẹrẹu ṣugbọn ijọba nilo làti pese awọn ẹkọ fun awọn olukọ láti bẹrẹ si ni kọ àwọn akẹkọọ ọhun, ti wọn yoo si gba awọn olukọ tí wọn kọsẹ mọ isẹ.
O ṣalaye siwaju pé ede abinibi to ba wa ni ayika awọn akẹkọọ ni wọn yoo máa fi kọ awọn akẹkọọ naa.








