Èrò ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí àforíjìn Adamu, akẹ́kọ̀ọ́ fásiti tó sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Aisha Buhari

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Aminu Adamu, akẹkọọ fasiti to sọrọ alufansa si Aisha aya aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti tuuba lori ohun to kọ lori ayelujara.
Akẹkọọ fasiti apapọ Federal university, Dutse, nipinlẹ Jigawa naa tuba lọwọ Aisha Buhari lori ọrọ kobakungbe to kọ nipa rẹ lori ayelujara, bakan naa lo si tun seleri láti lọ gbegi le oju opo ayelujara rẹ ọhun ti pa.
Adamu to jẹ akẹkọọ ipele asekagba lẹka ìmọ nipa akoso ọrọ ayika ni idanwo oun to bẹrẹ lọjọ Aje loun fẹ gbajumọ bayii
Ninu fidio kan to fi soju opo Twitter re, @aminillahie, lọjọ Aiku, O beere fun adura gnogbo ọmọ Naijiria lati lee kogoja ninu idanwo rẹ.
“Mo fẹ fi anfani yii dupẹ lọwọ gbogbo eniyan, ẹgbẹ akẹkọọ ni Naijiria (NANS) ati awọn alaṣẹ fasiti apapọ nilu Dutse fun iranwọ, atilẹyin ati adura wọn.
Mo tun fẹ dupẹ lọwọ iyawo aarẹ orilẹed3 Naijiria, Aisha Buhari fun didariji mi lori awọn iwa mi ẹnu lọwọlọwọ yii ati fun amoran to fun mi lati yi iwa pada si daradara. N o tẹlẹle awọn ọrọ naa
Amoṣa n o gbegile oju opo gbogbo ti mo n lo lori ayelujara nitori idanwo mi n bẹrẹ lọla nitori oun. I yoo jẹ idanwo aṣkagba fun mi.
Akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó bú Aisha Buhari gba ìtúsílẹ̀ ní àhámọ́

Oríṣun àwòrán, Deji Adeyanju
Ijọba Naijiria ti wọgile ẹsun ti wọn fi kan akẹkọọ fasiti kan lẹyin ti wọn fi ṣikun ofin mu lori atẹjade to fi soju opo Twitter rẹ, nibi ti sọ pe owo ilu ni iyawo Aarẹ Aisha Buhari fi n sanra.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ fẹsun ibanilorukọjẹ ati pinpin iroyin ẹlẹjẹ lori ayelujara kan ọdọkunrin naa, eyii to sọ pe oun ko jẹbi rẹ.
Agbẹjọro rẹ, Chijioke Kingsley Agu sọ fun BBC pe ikọ olupẹjọ nile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti sọ pe awọn ko ṣe ẹjọ naa mọ.
Agu ni wọn tu onibara oun silẹ nitori wọn ṣaanu rẹ ati pe yoo pada sile rẹ laipẹ.
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo koro oju si bi ijọba ṣe fi ṣinkun ofin mu akẹkọọ naa, ti ọpọ awọn gbajumọ lori ayelujara si funrere pe ki wọn jọwọ rẹ ni kiakia.
Lọjọbọ, ajọ ajafẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International sọ pe wọn fi iya jẹ akẹkọọ naa ninu ahamọ to wa lọna aitọ, eyii to sọ pe o tẹ ẹtọ rẹ loju mọlẹ.
Bo tilẹ jẹ ọpọ araalu lo n naka abuku si iyawo Aarẹ lori iya ti wọn fi jẹ akẹkọọ naa, ijọba apapọ ko sọ ọrọ kankan lori iṣẹlẹ ọhun.
Ẹkọ nipa ọrọ ayika ni Aminu n kọ ni fasiti ijọba apapọ to wa nilu Dutse, nipinlẹ Jigawa, ọjọ Aje si ni yoo bẹrẹ aṣekagba idanwo rẹ.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Iléẹjọ́ ní kí akẹkọọ fáṣítì tó sọ̀rọ̀ àlùfánsí sí ìyàwó Ààrẹ Aisha Buhari máa gbà àtẹ̀gùn ní ahàmọ́.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti jẹyọ lẹyin ti awọn agbofinro mu akẹkọọ fasiti kan to tabuku sì aya aarẹ Orilẹede Naijiria, Aisha Buhari lori opo Twitter.
Aminu Adamu Mohammed ti wa ni ọgba ẹwọn bayii, ti Agbẹjọro rẹ Chijioke Kingsley Agu sọ fun Ileeṣẹ BBC pe akẹkọọ naa ni wọn ti gbe lọ ileẹjọ giga Maitama niluu Abuja lọjọ isẹgun
Akẹkọọ ọhun ni wọn fi ẹsun ọdaran tí Agbẹjọro rẹ si ti bere fun beeli rẹ, eyi ti ireti wa pe ileẹjọ yoo buwọlu laarin ọjọ meji.
Ọkùnrin naa ẹni mejilelogun ni ọwọ awọn ileeṣẹ ọlọpaa tẹ lẹyin to gbe aworan iyawo aarẹ si ori opo ayelujara Twitter, ti o si kọ si pe ninu ede Hausa pe o n sara sì pẹlu owo awọn araalu.
Akẹkọọ ọhun ni o yẹ ko kopa ninu idanwo pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ni ọsẹ to n bọ sugbọn ko si ireti pe yoo ni anfani lati kopa ninu idanwo naa. Ọpọlọpọ awọn eeyan lori ayelujara lo ti bu ẹnu atẹlu igbesẹ ìjọba apapọ tí wọn si n bere fun itusile akẹkọọ naa. Nibi oṣu diẹ sẹyìn ni awọn ofin mu awọn meji, tí wọn si bo ẹgba sì idì nitori wọn wu iwa ibanilorukọ jẹ fun Gomina ipinlẹ Kano lori opo ayelujara Tiktok.
Àwọn òbí ọmọ tí wọ́n tì mọ́lé nítorí ó bú Aisha Buhari ti sọ̀rọ̀ sókè
Awọn obi ọmọ Fasiti kan ni ipinlẹ Jigawa, Aminu Adamu Mohammed ti wọn fi ẹsun kan pe o bu iyawo aarẹ Niajiria, Aisha Buhari ti sọrọ soke
Awọn obi naa ninu ọrọ wọn ti tọrọ aforiji lọwọ iyawo aarẹ, Aisha Buhari lati dariji ọmọ naa.
Iroyin ni awọn ẹṣọ alaabo gbe akẹkọọ ileẹkọ Fasiti Dutse ni ipinlẹ Jigawa.
Kini Aminu Mohammed kọ si Twitter?
Ninu ọrọ ti ọmọ naa fi si oju opo Twitter rẹ lo ti fi fọtọ Aisha si bẹ, to si kọ ọrọ ni ede Hausa pe, Aisha Buhari ti sanra si nitori o ti ko owo araalu jẹ.
Wọn ni ọjọ Kẹjọ, Osu Kẹfa, ọdun 2022 lo fi tweet ọhun si oju opo Twitter rẹ, to si fi ẹdẹ abinibi rẹ kọ
Amọ ileeṣẹ iroyin BBC ko lee fi idi ọrọ naa mulẹ lori Twitter.
Kini awọn obi rẹ sọ?

Oríṣun àwòrán, AMNESTY INTERNATIONAL
Awọn obi Aminu Adamu Mohammed ni ipe ni an gba lati ọwọ ẹnikan pe ọmọ rẹ wa ni Abuja lẹyin ti ẹṣọ alaabo gbe lori nkan to kọ si oju opo ikansiraẹni Twitter.
Mọlẹbi rẹ to sọrọ ni orukọ ebi, Shehu Baba Azare ni awọn ti bẹbẹ ki iyawo aarẹ dariji awọn, ki wọn si dariji.
‘’Ohun ti a mọ nipe iya wa ni iyawo aarẹ jẹ nitori naa ni a ṣe n ra wọ ẹbẹ si lati dariji wa , ki wọn fi Aminu silẹ’’
Bakan naa ni ọkan lara awọn akẹkọọ to ba BBC Pidgin sọrọ ni idanwo ileẹkọ n bẹrẹ ni ọṣẹ to n bọ, nitori naa ki wọn jọwọ fi silẹ ni kiakia, ki o ma ba daamu rẹ ati esi idanwo rẹ.
Kini awọn eniyan sọ?
Ọpọlọpọ eniyan ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ lo ti fi ero wọn han lori iṣẹlẹ naa, to si ti gba ori ẹrọ ayelujara kan.
Loju ọpọ Twitter ati oju opo ikansiraẹni miran ni #FreeAminuAdamuMohammed ti n trend.
Awọn eniyan n pe fun ki wọn fi akẹkọọ ọhun silẹ.
Bakan naa ni Ajọ Ajafẹtọ ọmọniyan, Amnesty International naa ti pe fun itusilẹ rẹ ni kiakia.
Wọn ni o lodi si ofin ki wọn tii mọle lai ni ẹtọ si agbẹgbọro ati awọn eniyan rẹ.












