Ó tó ọdún méje tí mo ti ń rétí irú ìfẹ́ tí Ooni ń fún mi- Olorì Tobi Ogunwusi

Ooni àti Olori Tobi Phillip

Oríṣun àwòrán, Queen Tobi/INSTAGRAM

Ọkan lara awọn ayaba Ooni ti ilu ile ifẹ, Ayaba Tobi Phillips Ogunwusi tí salaye bíi Oba Adeyeye Ogunwusi ṣe mú ireti rẹ ọlọdun meje wa si ìmusẹ lẹyin to di Iyawo Ọba.

Olori sọ eleyi lori opo ayelujara lati ṣe iranti pẹlu aworan bíi olori Takasufe, Timi Dakolo ṣe fi orin ifẹ 'Iyawo mi' da Ooni ati Iyawo rẹ tuntun laraya lọjọ igbeyawo wọn niluu ile ife 

Lori aworan naa, Ayaba ni Ooni ati oun n kì awọn ololufẹ wọn ku oṣu tuntun.

Ooni ati Olori Tobi

Oríṣun àwòrán, Olori Tobi/Instagram

Ooni àti Olori Tobi

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ooni àti Olori Tobi

Oríṣun àwòrán, Instagram

"Lati ọdọ Ọba alayeluwa,Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi ati Ọlọlajulọ Ayaba Tobi Phillips Ogunwusi, a n kì yín ku oṣu tuntun."

Tobi Phillips ni olorì kejì ti yoo wọ aafin Ọọni lẹyìn tí Ọọni gbé Olorì Mariam Anako niyawo nínu oṣu Kẹsan an

Ọmọ bibi ilu Erinje-Ikale ní Okitipupa ní ìpinlẹ Ondo ni Tobi Phillips.

Ní ọdun 2013 ni Tobi kẹkọọgboye nínu ìmọ nípa sayẹnsi orí omi (Marine Science) ní ilé ẹkọ gíga fásitì ìlu Eko, UNILAG.