Saki Crisis: Yorùbá àti Bòròró ń tako ara wọn ẹni tó pa èèyàn

Saki Crisis: Ilé ìwòsàn Saki ti kọ ọmọ mi ti àwọn Bororo ṣeléṣé- Alhaji Adekola

Oríṣun àwòrán, Shola Ailako

Ìkọlù láàrín Fulani adarandaran àti àwọn àgbẹ̀ ní ìhà ìwọ̀-òrun Nàìjíríà kò fi ìgbà kankan dáwọ́ dúro, ọ̀kan irú rẹ̀ ló tún ti ń wáye ni ìlu Saki, nipinlẹ Oyo, láti bi ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn báyìí.

Gẹ́gẹ́ bi ìròyìn tó tẹ BBC lọ́wọ́, wọ́n ni ọkùnrin kan ti orúkọ rẹ̀ n jẹ́ Gurumọ, to jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ-è[de Burkina Faso, to sì ti n gbe ìlú Saki fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ni àwọn Fulani lọ ṣá ni àdá pa ti wọ́n si kó ǹkan iní rẹ̀ lọ.

Gẹ́gẹ́ bi àlàyé ti Alhaji Lateef Adekola ṣe fun BBC Yorùbá ni òwúrọ̀ òní ni pé, ni kété ti àwọn Bororo mẹjọ wa pé àwọn ọmọ òun pa ọkùnrin kan ni wọ́n ti ja lọ si àgọ́ ọlọ́pàá láti lọ fẹ́jọ sùn ki àwọn Yorùbá tó gbọ́ pé Bororo ló pa ẹni náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alhaji Adekola sàlàyé pé ni kíá náà ni ọ̀gá ọlọ́pàá lẹkun naa ti gbé ìgbẹ́sẹ̀ láti ri pé ọ̀rọ̀ náà ko dá wàhálà sílẹ̀ láàrín ìlú, ọ̀gá ọlọ́pàá pè ìpàdé, sùgbọ́n ó ṣe ni láànu pé gbogbo àwọn Bororo ti sálọ.

Saki Crisis: Ilé ìwòsàn Saki ti kọ ọmọ mi ti àwọn Bororo ṣeléṣé- Alhaji Adekola

Oríṣun àwòrán, Sola Ailako

"Ọgá ọlọ́pàá fọ́wọ́ si pé ki wọ́n lọ sin okú, ki a si yanjú ọ̀rọ̀ náà láàrín ara wọ́n ki ọ̀rọ̀ ma ba bẹ́yìn yọ. Emi ni mo gbé ọlọ́pàá ni ọ̀kadà láti lọ maa yajúlé gbogbo àwọn Bororo, sùgbọ́n a kò bá ẹnikankan nílé."

Alhaji Adekola fi kun àlàyé rẹ̀ pé, ní àná ọjọ́ Aiku ni ìròyìn ń fọ́n ká pé, àwọn Bororo ti kogun de, ti àwọn sì bẹ̀rẹ̀ si ni gbúròó ìbọn.

"Àwọn Yorùbá náà sì jáde àlááfíà láti lọ wó ǹkan tó ṣẹlẹ̀"

Adekola ni bí àwọn Bororo se mú ọmọ òun ti wọ́n só mọ́lẹ̀, " Wọ́n yìn nibọn, ìbọn kò ràn, wọ́n ṣa láda, kò wọlé, ni wọ́n wa bẹ̀rẹ̀ si ni já ni igi, àti okúta.

Ilé ìwòsàn Saki ti kọ ọmọ náà báyìí, wọ́n ni ki a ma gbe lọ sí Ilọrin nítorí wọ́n ni egungun tó ti kan lára rẹ̀ ti pọ̀ jù."

Alhaji Adekọla ni titi di àsìkò yìí ènìyàn kan ni àwọn bọ́ pé ó kú, kò sí ẹlòmíràn tó kú ni gbogbo àgbègbè náà.

Saki Crisis: Ilé ìwòsàn Saki ti kọ ọmọ mi ti àwọn Bororo ṣeléṣé- Alhaji Adekola

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Alhaji Hassan Abdullahi, to jẹ́ Mogaji Koba sàlàyé pé, kìí ṣe àwọn ni àwọn pa ọkùnrin ti wọ́n ni ó ku, sàdédé ni àwọn ri nínú okò Kaṣú rẹ̀ tó kú sí.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Alhaji Hassan Abdullahi to jẹ́ Mogaji Koba, tó tún jẹ́ aṣojú àwọn Bororo ni agbègbè náà sàlàyé pé, kìí ṣe Bororo lo pa ọkùnrin ti wọ́n ni ó ku , sàdédé ni àwọn ri nínú okò Kaṣú rẹ̀ tó kú sí.

Àkọlé fídíò, Adebunmi Adeyeye: Mo jẹ gbèsè gbọ́múléláńtà, ìdí iṣẹ́ kabúkabú ni mo ti ri san

Lẹ́yìn náà ni àwọn ọlọ́pàá wa, ti wọ́n si yanju rẹ̀. Sùgbọ́n lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ ita bẹ̀rẹ̀ si ni finá sílé, ti wọ́n sì ń pa àwọn Maalu àti ọmọ àgùntàn.

Nínú àwọn tí wọ́n n fi ìná sílé náà ni ọkùnrin ti wọ́n so mọ́lẹ̀, láti mú kalẹ̀ títí ti ọlọ́pàá yóò fi wa mu.

"Bí mó se n bá yin sọ̀rọ̀ yìí, ààrìn Saki àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ni a wa báyìí, ti a lọ farapamọ́ sí"

Saki Crisis: Ilé ìwòsàn Saki ti kọ ọmọ mi ti àwọn Bororo ṣeléṣé- Alhaji Adekola