Federal College of Forestry Mechanisation: "Ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá tún wa sílẹ̀, àwọn àjínigbe yìí le ṣe ohunkóhun fún wa"

Ó lé ni ọgbọ̀n nínú àwọn ti ajínigbe ji nile ìwé Federal College of Forestry Mechanization lọ́jọ́ Eti lo fojú hàn nínú fọ́rán kan ti ó jẹyọ ní ọ̀sán yìí.
Sáájú ni ìjọba ìpińlẹ̀ Kaduna ti sọ pé àwọn ti ri àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tó dín díẹ̀ ni igba gba lọ́wọ́ àwọn ajínígbé, sùgban àweọn ko mọ ìbi ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kù wà.
Ijńígbé àwọn ọmọ yìí ni eyi to ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ ni Nàìjíríà, pàápàá jùlọ ni ìhà Aríwá orílẹ̀-èdè yìí.
Nínú fọ́ràn tó yojú lọ́sàn òní, ọjọ́ Abamẹta, ọjọ́ kẹtàlá, ọdún 2021 ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà joko sí ilẹ̀ nínú igbó kan ti ẹnikẹ́ni kò mọ̀ ti àwọn to gbé ìbọ̀n dáni sì dúró tìwọ́n.
Nínú fọ́ràn náà bákan náà, ọkàn nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí sì n rọ ìjọba láti tètè ṣe ǹkan ti àwọn ajínígbe náà ń fẹ́, a ti pé kí ìjọba má pinu lat gbawọ́n silẹ̀ ni tipátipa.

Bákan náà ni àwọn ajínigbe ọ̀hún tún ni ki ọ̀kan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìrin tó wà níbẹ̀ sọ èdè hausa.
Gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni ko wọ asọ, àwọn ọkùnrin wọ sòkòtò lásán nígbà tí àwọn obìnrín ró ìrómọ́ya.
Sáájú ni ọgà kan nínlé ìwé ti sọ pé obìnrin ni gbogbo awọn ri wọ́n n wa.
Nínú àtèjáde kan ti kọmísọ́nà ètò ẹkọ́ fọ́wọ́sí lọ́jọ́ Eti lo ti sàlàyé pé ó tro ènìyàn mọ́kàndílógójì àwọn ko le sọ ibi ti wọ́n wà, ó fi kun pé, obìnrin mẹ́tàlélógún àti ọkùnr;in mẹ́rìndinloógun.
Nínú fọ́an tó jẹyọ lórí ayélujára lọ́sàn yiìí ni a ti ri obìnrin àti ọkùnrin
Ọkan nínú àwọn ti wọ́n ji gbe náà pé ara rẹ Benson Emmanuel, o sì sàlàyé pé, ọ̀pọ̀ àwọn ló ti farapa ti wọ́n sì nílo ìtọ́jú.
Àwọ ajínigbe naa tún ń fi ẹgba lùwọ́n nínú fọ́nran ti jẹyọ.
'A ṣì ń wa 39, akẹ́kọ̀ọ́, 180 tí wọ́n jígbé ní iléèwé Federal College of Forestry Mechanisation Kaduna ti gba ìtúsílẹ̀

Iroyin ayọ ti balẹ si ilu Kaduna ni ile iwe giga Federal College of Forestry Mechanization, Afaka, Igabi LGA nibi ti wọn ti ji akẹkọọ ọgọsan gbe lalẹ Ọjọbọ àmọ́ ọgbọ̀n ninu awọn akẹkọọ ileewe naa ni wọn ko tii ri bayii.
Ikọ ọmọ ogun Naijiria kan si agbami iṣẹ ni kete ti wọn gbọ iroyin naa ti wọn si ri awọn ọmọ ọhun doola. Ọpọlọpọ awọn ti wọn jigbe lo jẹ akẹkọọ.
Awọn agbebọn ti ogunlọgọ wọn yabo ile ẹkọ naa ni nkan bii ago mọkanla abọ alẹ Ọjọbọ ti wọn si gbe ọpọlọpọ akẹkọọ gbe sa lọ.

- Ìsìnkú Kashy Godson tí wọ́n fẹ̀sùn ikú rẹ̀ kan Barry Jhay pa ti wáyé lónìí ọjọ ìbí rẹ̀
- Orílẹ̀èdè Denmark, Norway jápaa lórí lílo abẹ́rẹ́ Covid-19 àmọ́ ohun ti ìjọba Naijiria sọ ní tiwọn rèé
- Ṣé lóòtọ́ ni Alaafin Ọyọ ti fẹ́ olorì tuntun láti ẹ̀yà Igbo? Ẹ wo ǹkan tí a mọ̀ nípa rẹ̀
- Ẹni bá rí i kó sọ o, Ìjọba ń wá ẹni dún 45 tó fipá bá ọmọ ọdún méje lòpọ̀
Awọn agbebọn ọhun fọ fẹnsi ogiri nla ti ileewe naa wọn si wọle lọ si ibi to to iwọn kilomita ẹgbẹta lati ṣe ọṣẹ.
Ni kete ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ aabo abẹnu ni ipinlẹ naa gba ipe ni wọn kan si ileeṣẹ ogun fun igbesẹ kanmọ kanmọ.
Lọgan ni ikọ naa ta mọ iṣẹ, wọn gbe ogun koju awọn ajinigbe naa wọn si ri akẹkọọ obinrin mejilelogoji; akẹkọọ ọkunrin aadoje ati olukọ mẹjọ doola pada ṣugbọn wọn ko tii ri ọgbọn ninu wọn.

Ẹwẹ, lara wọn ti farapa gidi ṣugbọn wọn n gba itọju nile iwosan gẹgẹ bi gomina Nasir El Rufai ti ipinlẹ naa ṣe dupẹ lọwọ ikọ ologun naa fun bi wọn ṣe jara mọ iṣẹ ọhun.
Bí wọn ṣe ri awọn akẹkọọ naa gbe
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe awọn agbebọn tun ti ji awọn akẹkọọ ileewe Federal College of Forestry, to wa ni agbegbe Mando nipinlẹ Kaduna.
Ileewe naa ni wọn ti n kọ nipa amojuto igbo nlanla.

Oríṣun àwòrán, Yusuf Tijjani
Bo tilẹ jẹ pe iye akẹkọọ ti wọn ji gbe ko ti i jẹ mimọ, awọn akẹkọọ ileewe naa sọ pe aarin oru ni wọn ji awọn akẹkọọ naa gbe.
Ọkan lara awọn akẹkọọ ileewe naa sọ fun BBC Hausa pe obinrin ni gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe.
- Ìsìnkú Kashy Godson tí wọ́n fẹ̀sùn ikú rẹ̀ kan Barry Jhay pa ti wáyé lónìí ọjọ ìbí rẹ̀
- 'Ìdí tí a ò fi pa àwọn ajínigbé tó gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kankara nìyìí'
- Fayemi: Àfàìmọ̀ kí ìjọba má bá àwọn jàndùkù ajínigbé sọ̀rọ̀, àmọ́ onímọ̀ nípa ètò àbò ní ...
- Wakili jiyàn ọ̀rọ̀, ó ní òun kò mọ ohunkohun nípa ìṣekúpani tó ń wáyé n'Ibarapa méjèèje
Ṣugbọn ko ti i si ifidimulẹ eyi lati ọdọ awọn alaṣẹ tabi agbofinro.
Bakan naa ni awọn ara adugbo naa sọ fun BBC pe ni nkan bi aado mọkanla aabọ alẹ Ọjọbọ ni awọn n gburo ibọn, ṣugbọn wọn ro pe ile ẹkọ awọn ologun ni iro ibọn ti n dun.

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan sọ fun BBC pe awọn agbofinro ti wa nileewe naa fun iwadii.
Akọroyin BBC to ṣe abẹwo si ileewe naa ni owurọ ọjọ Ẹti sọ pe lootọ ni awọn oṣiṣẹ alaabo ti wa nibẹ, wọn si ti ko awọn akẹkọọ to ku lọ si ileewe ikọṣẹ awọn ologun to wa ni agbegbe naa.
Akẹkọọ bi ọọdunrun lo wa ni ileewe naa lapapọ, ṣugbọn ko si ẹni to mọ iye awọn ti wọn ko lọ.
Ileewe ikọṣẹ ologun ati papakọ ọkọ ofurufu ko jina si ileewe Federal College of Forestry ti iṣẹlẹ yii ti waye.









