Rape of minors: Ẹni bá rí i kó sọ o, Ìjọba ń wá ẹni dún 45 tó fipá bá ọmọ ọdún méje lòpọ̀

Ọmọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile aṣofin nipinlẹ Bauchi ti gbe igbimọ dide lati ṣawari ọkunrin ẹni ọdun marundinlaadọta to fi ipa ba ọmọ ọdun meje lopọ.

Awọn aṣofin kan ni ileeṣẹ ọlọpaa ti gba beeli ọkunrin naa lẹyin ti wọn fi panpẹ ọba gbe.

Agbegbe ijọba ibilẹ Faggo ni Shira ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Ọkan lara awọn aṣofin to gbe ọrọ naa ka ile aṣofin ni ki ileeṣẹ ọlọpaa ni kiakia wa ọkunrin yii jade lai fi akoko ṣofo.

O ni ọkunrin agbalagba naa ba ọmọbinrin naa lopọ lẹyin to dunkoko mọ ọ wi pe oun yoo pa a.

Bakan naa lo fi da awọn oniroyin loju wi pe awọn yoo ri wi pe ijọba fi ọkunrin oun jofin.

O ni awọn yoo ṣewadii ni ijọba ibilẹ Shira ati ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe naa ibi ti wọn de duro lori bi wọn ṣe fi panpẹ ọba mu ọkunrin naa.

Amọ, nibayii awọn aṣofin naa ni awọn ko mọ ibi ti ọkunrin naa salọ, sugbọn awọn fi n da awọn araalu loju wi pe arakunrin oun ko ni lo lai jẹ iya ẹsẹ rẹ.

Ijọba ipinlẹ Bauchi ni ifipabanilọpọ ti wọpọ nipinlẹ naa, ti wọn si ti fi ofin de iru iwa bẹẹ ni ipinlẹ ọhun.

Ẹwọn ogun ni ijọba yoo fun ẹnikẹni ti wọn ba fi idi rẹ mulẹ pe o fi ipa ba obinrin lopọ.

Àkọlé fídíò, Wo obìnrin kanṣoso láàrin àwọ́n ọkunrin agunẹṣin gbafẹ́ nílùú Ilorin àmọ́ tọ́kàn rẹ̀ yii