Barry Jhay's latest news: A gbọ́ pé olóògbé Kashy ti ní àwọn ìṣòro kan tẹ́lẹ̀ kó tó kú - Ẹbí Barrister

Oríṣun àwòrán, therealbarryjhay
Olaronke to jẹ ẹgbọn Barry Jhay ni irẹpọ to wa laarin Kashy ati Barry Jhay ko le mu ki aburo oun ṣe e laburu.
"Torii Kashy gangan ni Barry Jhay ṣe lọ si orilẹede Ghana, Naijiria nibi lo wa tẹlẹ".
Idile gbajugbaja olorin Barry Jhay to jẹ ọmọ ilumọọka agba olori, oloogbe Sikiru Ayinde Barrister ti ba BBC Yoruba sọrọ lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan ọmọ wọn ni orilẹede Ghana.
- Ìhòhò ọmọlúàbí ní òṣèrébìnrin yìí fi lọ sí àmi ẹ̀yẹ tí wọ́n pè é sí
- Wàwúù!!! Lẹ́yìn ọmọ márun-ùn, wo bí ìyàwó àgbẹ̀ se tún bí ìbaàrùn-ún ní Ogbomoso láì ṣe iṣẹ́ abẹ
- Kí ló gbé Barry Jhay ọmọ Alhaji Sikiru Ayinde barrister dé gbaga ọlọ́pàá?
- Mọ̀ síi nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ ríru tó mú ẹ̀mí 16,000 èèyàn lọ tó sì ba dukia $206b jẹ́
- Wọ́n jí mi gbé, só mí mọ́lẹ̀ bí ẹ̀ran, fipábámilòpọ̀ láti di aya wọn torí mo jẹ́ Krìstẹ́nì - Ọmọbìnrin ọdún méjìlà
- Wo iye obìnrin lágbàáye tó ń kojú ìwà ipá, àti ohun tó ń ṣokùnfà ẹ̀?
Olaronke Balogun to jẹ ẹgbọn fun Barry Jhay ni awọn ṣi wa lori ọrọ yii torinaa iwọnba ni ẹbi le sọ nipa rẹ.
"Mi o si nibẹ ṣugbọn ọmọ to da a ni aburo mi, o ni iwa to daa, ko si ni ọwọ ninu iku naa".
Olaronke ni awọn gbọ wipe oloogbe Kashy ti ni awọn iṣoro kọọkan to n koju ṣaaju ọjọ iku rẹ.
O ni Fidio kan to fi sita ni ninu eyi to ti ni eeyan kan na oun ti ẹnu rẹ n ṣe ẹjẹ ti oun si ni lati maa bere pe ki lo ṣẹlẹ gangan.
"Barry Jhay o si nibẹ nigba ti iku naa ṣẹlẹ, o kan wa ni Ghana ni torinaa nkan to ṣe oloogbe ko kan Barry Jhay".
Ẹgbọn Barry Jhay ni idile awọn gbagbọ pe orilẹede Ghana jẹ ilu to maa n ṣamulo ofin daadaa ati pe awọn agbẹjọro tawọn ati awọn kan ninu ẹbi naa ti wa nibẹ pẹlu ẹ lati yanju ẹjọ naa.
"Torinaa a fi wọn silẹ ki wọn ṣe tu ọrọ naa bo ṣe yẹ ko jẹ ṣugbọn emi fẹ fi da gbogbo eeyan loju pe aburo ko lọwọ ninu nkan to ṣẹlẹ a dẹ ti fi gbogbo ẹ le Ọlọrun, lọwọ daadaa lo ma jade nibẹ lagbara Ọlọrun".

Oríṣun àwòrán, Barry jhay
Ibaṣepọ wo lo wa laarin Barry Jhay ati oloogbe Kashy?
Olaronke ni awọn mejeeji fẹran ara wọn gan koda tori Kashy gan ni Barry Jhay ṣe lọ si Ghana.
O ni lootọ ko si keeyan meji wa ko ma si ija laarin wọn.
"Tẹẹ ba wo awọn atẹjade awọn mejeji loju opo instagram wọn, ẹ maa mọ pe wọn rẹ gan, to ba mọ pe nkan bẹẹ ma ṣẹlẹ ko ni tori Kashy lọ si Ghana".
Olaronke ni Ọlọrun nikan lo mọ bo ṣe ṣẹlẹ koda o ni gbogbo awọn lawọn ṣi n daro.
"Bo tilẹ jẹ pe a fẹ ki aburo wa jade, a ni lati ba ẹbi to padanu ọmọ gan kẹdun tori oun naa ni ẹbi".
O ni awọn mejeji kii ja ija to lee pa wọn lara tabi ṣe ara wọn léṣe.
Bawo ni ẹbi Kashy ati ẹbi Barrister ṣe wa bayii?
"Eeyan o le sọ fun ẹni to ba padanu eeyan bi wọn ṣe maa huwa, onikaluku lo ni bo ṣe maa n ṣe".
O ni ko si aridaju kankan ti awọn eeyan ri pe Barry Jhay wa nibẹ rara nigba to ṣẹlẹ.
O ni ẹbi Kashy ko si ni Ghana ẹbi tawọn naa o dẹ si nibẹ torinaa wọn o le sọ fun wọn bi wan ṣe maa ṣe ṣugbọn "nigba ti wọn ba yanju gbogbo ẹ tan, nkan ti onikaluku ba ni lọkan a lọ silẹ".
Arabinrin Olaronke ni oun ko le dahun ibeere boya ẹbi oun ti lọ ki ẹbi Kashy tabi wọn ko lọ latigba to ti ṣẹlẹ toripe oun ko ba wọn pe lọ.

















