Ogbomoso quintuplets birth: Ìyàwó àgbẹ̀ bí ìbarùn-ún lẹ́yìn ọmọ márun-ùn ní Ogbomoso láì ṣe iṣẹ́ abẹ

Awọn Ibaarun

Oríṣun àwòrán, Dr. Afolabi Sikirulahi

Ayọ abara tin-tin ni nile ọkunrin agbẹ kan ati iyawo rẹ, to bi ọmọ marun-un lẹẹkan ṣoṣo nilu Ogbomọsọ nipinlẹ Ọyọ.

Dokita ileewosan Ayoka Clinic and Maternity Centre, Oke-Ado, Ogbomọṣọ, Dokita Afolabi Sikirulahi sọ fun BBC Yoruba pe fun'ra obinrin naa, Funmilayo Oluwadara, lo bi awọn ọmọ naa lai ṣe iṣẹ abẹ.

Ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta, ọdun 2021 lo bi awọn ọmọ naa, ati pe laarin ọgbọn iṣẹju pere.

Ile iwosan ti Iya Ibaarun bi si

Oríṣun àwòrán, Dr. Afolabi Sikirulahi

Àkọlé fídíò, Ilorin Conjoined Twins: Àwọn òbí ìbejì tó lẹ̀pọ̀ ní ọ̀kàn àwọn bàjẹ́ láti rí ibèjì wọn tó

O ni alaafia ni iya ati awọn ọmọ naa wa.

Bakan naa ni dokita ṣalaye pe obinrin naa ti bi ọmọ marun-un tẹlẹ, eyi to mu ki apapọ ọmọ ti oun ati ọkọ rẹ ni jẹ mẹwaa.

Obinrin mẹrin, ọkunrin kan ni awọn ibarun ti Arabinrin Oluwadara ṣẹṣẹ bi i.

Baba ati Iya Ibaarun

Oríṣun àwòrán, Dr. Afolabi Sikirulahi

A gbọ pe ẹni ọdun mejidinlogoji ni obinrin naa, ti ọkọ rẹ to jẹ agbẹ lati orilẹ-ede Togo, Idowu Oluwadara si jẹ ẹni ogoji ọdun, n gbe ni abule Ahoroko nilu Oyo.

Ọgbẹni Oluwadara sọ fun BBC pe niṣe ni ara oun dabi ẹni ti wọn da omi si lara, nigba ti wọn sọ fun oun pe ibarun ni iyawo oun bi.

O ni "o kọkọ dabi pe ki n salọ, ṣugbọn nigba ti mo ro o pe iyawo mi ni, emi ni mo si fun loyun, ni mo ṣe duro".

O si ti n bẹbẹ fun iranlọwọ lati ọwọ ijọba ati araalu fun iranlọwọ, nitori pe wọn ko ti i owo ileewosan san.

Àkọlé fídíò, Ọ̀nà àbáyọ sí àìrọ́mọbí tọkùnrin tobìnrin
Àkọlé fídíò, Wo obìnrin kanṣoso láàrin àwọ́n ọkunrin agunẹṣin gbafẹ́ nílùú Ilorin àmọ́ tọ́kàn rẹ̀ yii