Port Harcourt Sextuplet: Joyce ní ọjọ́ tí òun bímọ lòun mọ̀ pé oyún ìbẹfà ló wà nínú òun

Awọn ibẹfa

Oríṣun àwòrán, Bright Akhimien

Ẹ ku ọwọ lomi lo yẹ ki a maa ki tọkọ-taya Joyce ati Bright Akhimien ti Eledua ti fi odindi ọmọ mẹfa ta lọrẹ lẹẹkan ṣoso.

Lẹyin ọdun meje ti Joyce, ẹni ọdun mọkandinlogoji ati ọkọ rẹ, DSP Bright Akhimien ti wọn wa lati ipinlẹ Edo ni Olodumare to da wọn lohun.

Ọkunrin mẹrin ati obinrin meji lawọn ọmọ naa ti wọn bi lọjọ kejila, oṣu kinni, ọdun 2021 niluu Port Harcourt nipinlẹ Rivers.

Joyce ni oun ko mọ pe ọmọ mẹfa loun yoo bi lẹẹkan naa lẹyin ti dokita sọ fun oun pe ọmọ to pọ lo wa ninu oun.

O ni: ''Ọjọ ti mo bi awọn ọmọ naa lawọn nọọsi bẹrẹ si ni ka wọn ti wọn si ri i pe mẹfa lawọn ọmọ naa,'' Joyce ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Akure incest Momoh Usman case: Láti ẹni ọdún mẹ́tàlà ni Bàbá mi ti ń ba mi sùn- Fatimah Us

''O ṣoro fun mi lati mọ iye ọmọ to wa ninu mi nigba naa tori nigba kuu gba ti a ba lọ si ayẹwo ni awọn ọmọ naa maa n bo ara wọn mọlẹ.

Eleyi to maa n jẹ ko nira lati mọ iye ọmọ to wa ninu mi,'' Joyce lo sọ bẹẹ.

Joyce Akhtimien

Joyce ṣalaye pe inu oun dun debi pe oun ko mọ ohun ti oun tiẹ le sọ gan an.

O ni ''iyalẹnu lo jẹ fun mi bi Eleduwa ṣe n ṣiṣẹ rẹ pẹlu ọmọ mẹfa ti Ọba oke fi jinki emi ati idile mi.''

Bo tilẹ jẹ pe wọn padanu ọkan lara awọn obinrin to wa ninu awọn naa, wọn si n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ẹbun pataki yii.

Ibẹfa idile Akhinmien

Oríṣun àwòrán, Bright Akhimien

''Niṣe ni mo n bi ara mi leere pe ṣe emi naa ree, lẹyin gbogbo ohun ti oju mi ti ri fun ọdun meje.

Emi naa ni mo wa di ẹni to n ka ọmọ ni meni meji, omije ayọ lo n jabọ loju mi bi mo ti n yin Ọlọrun pe O ranti mi,'' Joyce lo sọ fawọn akọroyin bẹẹ.

Ọjọ kọkanla, oṣu kinni, ọdun 2014 ni Joyce ati Bright ṣe igbeyawo ti wọn si gbadura fun ere idi igbeyawo.

Ojoojumọ ni mo n yin Olorun logo nibi to sin mi de.

Lẹyin ọdun kan ti wọn ṣe igbeyawo ni Joyce bi ọmọkunrin kan, ṣugbọn lẹyin ọjọ kan ti ọmọ naa de ile aye lo pada.

Joyce ni lati igba naa, oun ko loyun lati aarọ di alẹ ri, bẹẹ ni oun ko loyun ki oyun naa wa bajẹ.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

O ni ọkọ oun gbaruku ti oun lasiko tawọn fi n wo oju Ọlọrun, ṣugbọn awọn ẹbi lo beere ni gbogbo igba.

''Ọjọ kan wa ti mo lọ ki ẹnikan to bimọ ni abule, nibi ti mo ti fẹ gbe ọmọ ni iya rẹ kọ fun mi lati gbe e, o dun mi gan na, koda mo sunkun nigba ti mo dele.

Arabinrin Akhimien ṣalaye pe alakọkọ ti oun ṣe eto ati loyun pẹlu ilana IVF naa ni oun bimọ yii.

Tọkọ taya Bright ati Joyce Akhtimien

''Niṣe ni a wa owo lati ṣe IVF nitori owo rẹ pọ gan an, ṣugbọn Ọlọrun gbọ adura wa, ẹkan ti a ṣe naa ni a si bimọ.

Bright, baba ibẹfa naa sọ fawọn akọroyin pe oun ko tiẹ fi ọkan si nigba ti iyawo oun sọ pe oun ti loyun nitori oun ko fẹ nkan to maa ba oun ninu jẹ.

Àkọlé fídíò, World Cancer Day: Mo pàdánù ọkọ àti ọ̀rẹ́ bí mo ṣe ni 'Cancer'- Iwalade Adebimpe Adetunji

''Oṣu kinni kọja, oṣu keji, nigba ti o di oṣu kẹta ni a bẹrẹ si ni gbagbọ pe Ọlọrun ti da wa lohun,'' Bright ṣalaye.

O dupẹ lọwọ Eleduwa pe O ranti awọn fun ni ẹbun pataki ọmọ mẹfa lẹẹkan ṣoṣo.