Igboho vs Fulani:Kábíyèsí Ooni ti forí jin Sunday Igboho lẹ́yìn tó túúbá- Ààfin Ile Ife

Oríṣun àwòrán, Instagram/ooniadimula
Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi ti forijin ajijagbara ilẹ Yoruba, Ọgbẹni Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho lẹyin to tọrọ aforijin lọwọ Kabiyesi.
Igboho ti kọkọ sọrọ ninu fọnran kan ninu eyi to ti bu ẹnu atẹ lu bi kabiyesi ti ṣabẹwo si Aarẹ Muhammadu Buhari lori awọn awọn Fulani darandran atawọn agbẹ nilẹ Yoruba.
Amọ Igboro ṣalaye pe ahọn lo gbe oun nitori bi ọrọ ilẹ Yoruba ṣe ka oun lara to.
- Ọlọ́pàá Ogun ké pe ẹni tó ni Pavillion Hotel láti wá ṣàlàyé ìdí tí kámẹ́rà fi wà nínú yàrá
- Irọ́ ní o, a kò buwọ́lu Goodluck Jonathan fún ipò ààrẹ 2023 - APC
- Bàbá mi Ooni, ẹ foríjìn mí, ẹnu mi ò gbàá láti bú yín- Sunday Igboho tọrọ àforíjìn
- Ènìyàn 1,138 tún ti lùgbàdì ààrùn Covid-19 ní Nàijíríà
- Èrò àwọn eèyàn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí iléẹ̀kọ́ Gbogbonìṣe tuntun tí Buhari ní kí wọ́n dá sílẹ̀ ní Oyo
- Mọ̀ síi nípa Aung Suu Kyi tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n ní Myanmar àti bí ìgbàjọba ṣe wáyé níbẹ̀
O ni ẹnu oun ko gbaa lati bu ori ade gẹgẹ bi ọmọ ti wọn bi nile 're nilẹ Yoruba.
Agbẹnusọ fun kabiyesi, Ọgbẹni Moses Olafare ti wa sọ pe Ooni ti darijin Igboho gẹgẹ bi ọkan lara ọmọ kabiyesi.
Olafare ni bo tilẹ jẹ pe iwa ti Igboho hu kudiẹ kaato, o ni a kii mọ rin ki ori ma mi.
O ni Ooni si wa lẹyin Igboho lori gbogbo akitiyan to n ṣe lori ọrọ ilẹ Yoruba.
Eselu ti ilu Iselu, Ọba Akintunde Akinyemi ni ijọba ibilẹ Yewa ni ipinlẹ Ogun ti ni awọn Yoruba ko korira awọn Fulani, amọ awọn oniwa buruku ninu wọn ni a o fẹ.
Oba Akinyemi ni o ba si agbegbe ti awọn Fulani darandara ti ṣọṣẹ ni ipinlẹ Ogun.
Ninu ọrọ rẹ, Ọba Akinyemi wa gboriyin fun Sunday Igboho fun ipa ribiribi to ko lati ri wi pe awọn Fulani darandaran ti wọn n ji awọn eniyan gbe kuro ni agbegbe naa.
Oba sọ ọrọ yii lasiko ti Igboho lọ si ipinlẹ Ogun, to si fi ikini ranṣẹ si ọba naa.

Oríṣun àwòrán, Google
Oba ni ko dun mọ oun ninu pẹlu bi awọn Fulani darandaran ṣe n pa eniyan ni agbegbe naa, lo jẹ ki oun ṣe atilẹyin fun Sunday Igboho.
Bakan naa lo ni oun wa lẹyin Sunday Igboho, Gani Adams, Femi Falana ti wọn n ja fun ẹtọ awọn ọmọ Yoruba.
- Inú mi kò bá dùn tí wọ́n bá le fi àwọn ọlọ́pàá tó lù mí jófin yàtọ̀ sí N5m tí wọ́n fẹ́ fún mi- Tola
- Àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin dá pín ogun bàbá wa, wọ́n ní pé obìnrin ni mí- Onyinye
- Àwọn aláìsàn ń padà lọ sílé lẹ́yìn tí àwọn Dókítà bẹ̀rẹ̀ ìyànṣẹ́lódì ní Ondo
- Ìpayà ní Kano lẹ́yìn tí òṣìṣẹ́ Àjọ NYSC kú lẹ́yìn tó lùgbàdì ààrùn Coronavirus
- Ọlọ́pàá fòfin de lílo "siren" àti "tinted glass" lọ́nà àìtọ́
- Ǹkan tÍ Sunday Igboho ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Olórí Miyetti Allah ilẹ̀ Yorùbá
- Ilẹ̀ Amerika ń wá olùkọ́ èdè Yorùbá, wo bí o ti lè forúkọ sílẹ̀ níbí
- Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ní pé wọ́n pa ọmọ ogun mẹ́fà tó jẹ́ iran Igbo nikọ̀kọ̀ ní Abuja- Iléeṣẹ́ ológun
Bàbá mi Ooni, ẹ foríjìn mí, ẹnu mi ò gbàá láti bú yín- Sunday Igboho tọrọ àforíjìn
Ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti tọrọ aforijin lọwọ Ooni Ile Ife, Oba Enitan Adeyeye Ogunwusi lọrọ ọrọ to sọ pe Ooni ti gba owo lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari nigba to ṣabẹwo sii niluu Abuja.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ooni
Nigba to n sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan kan l'Ọjọru, Igboho ni ahọn lo gbe oun ti oun fi ṣi sọ notori ẹnu oun ko gbaa lati bu oriade.
''Gbogbo bi awọn Fulani ti n huwa ọdaran nilẹ Yoruba lọ jẹ ki n fi itara sọrọ, bi bẹẹ kọ, ẹnu mi ko gbaa lati bu ọba alade nilẹ Yoruba,'' Igboho ṣalaye.
- Ọkọ̀ agbépo bẹ́ntiról kankan kò gbọdọ̀ gun afárá nípínlẹ Ogun mọ́ - Gomina Dapo Abiodun
- Àwọn ọmọ onílẹ̀ lọ ṣe àmúṣẹ àṣẹ iléẹjọ́ ní Soka, làwọn ‘Jàǹdùkú’ fi dá wọn lọ̀nà - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ọyọ
- Wo ìgbésẹ̀ tí àwọn lọ́balọ́ba, ọlọ́pàá àti Seyi Makinde fẹ́ gbé lórí áàwọ Ibarapa
- Olóṣèlú ti tọwọ́ bọ ọrọ Igboho àti ìṣòro Fulani, mo gbọdọ̀ ṣọ́ra - Gani Adams
- Mo ń padà bọ̀ ní Ibarapa lọ́sẹ́ tó ń bọ̀- Igboho; Gbogbo dúkìá mi làwọn ọmọ Igboho jó tán- Seriki Fulani
- Igboho vs Fulani: Báyìí ni nǹkan ṣé ń lọ nílé Sunday Igboho lónìí
Igboho ni ọrọ ọmọ ati baba ni ọrọ to ṣẹlẹ laarin oun ati Ooni, ati pe awọn si ti jọ sọrọ, koda o ṣalaye pe Olugbọn ti Orile Igbọn naa da si ọrọ ọhun.
Ajijagbara Igboho sọ pe Ooni nikan gan an kọ ni oun n baa wi ninu fidio ti oun ti sọrọ.
O ni gbogbo awọn to n gbẹyin gbẹbọ jẹ fun ilẹ Fulani lori ọrọ awọn Fulani ni oun ba wi.
- 'Ẹ yé bú Seyi Makinde, owó rẹ̀ ló fí ra Ọkọ bọ̀gìnì fún Alhaja Abosede Adedibu, Taye Currency, Mutiat Ladoja'
- Mọ̀ síi nípa Aung Suu Kyi tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n ní Myanmar àti bí ìgbàjọba ṣe wáyé níbẹ̀
- Ọlọ́pàá Ogun ké pe ẹni tó ni Pavillion Hotel láti wá ṣàlàyé ìdí tí kámẹ́rà fi wà nínú yàrá
- Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ní pé wọ́n pa ọmọ ogun mẹ́fà tó jẹ́ iran Igbo nikọ̀kọ̀ ní Abuja- Iléeṣẹ́ ológun
Ẹwẹ, Aafin Ooni Ile Ife ti fesi si ọrọ ti ajijangbara ọmọ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho sọ nipa Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi.
Ninu ọrọ naa to ti gba ori ayelujara kan bayii ni Igboho ti sọ pe Ooni ti gbabọde lẹyin to ṣepade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari niluu Abuja.
Agbẹnusọ fun Ooni, Moses Olafare ṣalaye pe Ooni ko lodi si ohun ti Igboho n ṣe lọna kọna.
O ni lootọọ ni Ooni ṣe abẹwo si Aarẹ Buhari l'Abuja lati lọ pẹtu si aawọ to n ṣẹlẹ laarin awọn agbẹ ati awọn darandaran Fulani ni gẹgẹ bi ọba alaye.

Oríṣun àwòrán, @Ooni of Ife
Ooni ti gboriyin fun Igboho fun ohun to n ṣe nilẹ Yoruba nitori awọn eeyan lo ja fun un.
''Ọba o le sọ pe ẹyin ọmọ Yoruba, ẹ jẹki a lọ jagun, ko si ọba to le sọ iru rẹ, ọba to ba ṣe bẹẹ tapa sofin alaafia ati ofin ijọba,'' Olafare lo sọ bẹẹ.
Olafare ṣalaye pe awọn agbaagba ilẹ Yoruba atawọn gomina ni kabiyẹsi ti ba ṣepade pọ ki o to lọ si ọdọ Aarẹ Buhari.
Ọgbẹni Olafare ni oju ni agbalagba maa n ya, agbalagba kii yanu, o ṣalaye pe gbogbo aṣọ kọ ni a maa fi sa loorun.
''Imọran oju lalakan fi ṣọri ni Ooni fun Igboho, ko si apọnlẹ to tun ju bayẹn lọ,'' Olafare ṣalaye.
Olafare ni Igboho ni lati wẹ̀yìn wo, àmọ́ Ooni kò tako ohun tó ń ṣe nílẹ̀ Yoruba.
Olafare tun fikun ọrọ rẹ pe ki Igboho mu ẹri to daju wa pe Ooni gbowo lọdọ Buhari
- Ọlọ́pàá Ogun ké pe ẹni tó ni Pavillion Hotel láti wá ṣàlàyé ìdí tí kámẹ́rà fi wà nínú yàrá
- Ọọni ti gbàbọ̀dè fún Yorùbá lọ́dọ̀ Buhari- Sunday Igboho
- Ìpayà ní Kano lẹ́yìn tí òṣìṣẹ́ Àjọ NYSC kú lẹ́yìn tó lùgbàdì ààrùn Coronavirus
- Àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin dá pín ogun bàbá wa, wọ́n ní pé obìnrin ni mí- Onyinye
Ọọni ti gbàbọ̀dè fún Yorùbá lọ́dọ̀ Buhari- Sunday Igboho
Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho lo fi fọnran fidio kan sita lori ayelujara nibi to ti sọ pe Ooni ti Ile Ife ti gbabode lọdọ Buhari.
O ni Oba Adeyeye Ogunwusi ti kuna lati ṣoju iran Yoruba daadaa ninu ipade ti Ooni ni laipẹ yii pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ni ile ijọba ni Abuja.
Ipade yii ni Ooni Ile Ife ti kọkọ ṣalaye pe o di dandan ki oun ri Aarẹ Buhari lori wahala eto aabo to mẹhẹ to n da ọkan awọn ara ilu laamu nilẹ Yoruba lasiko yii.

Oríṣun àwòrán, @Ooni of Ife
Sunday Igboho ni pe Oba Ogunwusi ko fi itara ṣalaye ni kikun fun Aarẹ Buhari ibi ti nkan de duro nilẹ Yoruba bayii.
O ni Kabiesi ko sọ iya ati ẹkun ati wahala ti oju iran Yoruba ti ri lọwọ awọn fulani ajinigbe fun aarẹ Buhari to bi o ti yẹ.
Ati pe oun mọọmọ ma da Kabiesi lohun nigba to ranṣẹ pe oun ni notiri ẹsun pe Kabiesi ko sọrọ to nigba to ni anfaani ipade pẹlu aarẹ Buhari to n tukọ Naijiria.
Laarọ oni ọjọ Ru, ni fọnran fidio ọlọrọ kan jade ti wọn si ni Igboho lo fi fọnran fidio naa sita pe nibi ipade awọn Yoruba nilẹ okeere ni.
Ki lo ti kọkọ ṣẹlẹ laarin awọn mejeeji?
Lọsẹ to kọja ni Oba Ogunwusi lọ si Abuja lọ ṣe ipade pẹlu Aarẹ Buhari ni Abuja.
Saaju ni Oba Ogunwusi ti gba Sunday Igboho ni imọran pe nitootọ ọmọ akin ni ṣugbọn ki o rọra ṣe ki o ma baa tẹ oju ofin mọlẹ.
O ni Igboho ti ja fun awọn ti ko lẹnu lati sọrọ ṣugbọn ki ọmọ ọdọ naa fi ọgbọn ṣe e ki awọn alaṣẹ, awọn agbofinro ati awọn adari ipinlẹ kọọkan laaye lati ṣe nkan to wu wọn.
Saaju naa ni Sunday Igboho ti sọ ninu fọnran fidio kan tẹlẹ pe awọn Oba ilẹ Yoruba wa lẹyin oun paapaa Ooni ati awọn miran to tun darukọ.
O ni ọrọ awọn Fulani to n ji eeyan gbe ti su awọn Oba ṣugbọn ẹru lo n ba wọn nitori ipo ti wọn di mu.
Awọn wo ni Igboho tun mẹnuba ninu fọnran naa?
Sunday Igboho sọrọ lọ ba Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, O darukọ Gomina Seyi Makinde ati awọn eekan miran pe wọn ko ṣetan lati sọ ododo bi o ṣe yẹ.
O fi ẹsun kan wọn pe eyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe n gbe igbiyanju ati erongba koowa wọn ṣaaju ifẹ awọn Yoruba.
Kini Igboho tun sọ?
Igboho ni ẹru ti n ba awọn Oba ṣugbọn ki a maa gbadura fun wọn.
O gba awọn ori ade ni imọran pe ki wọn ma bẹru atimọle bikoṣe pe ki i ṣe pe ki wọn maa bẹru nibi ti ọjọ ori wọn de duro.
O ni Oọni dojuti oun nitori pe ọrọ rẹ dabi ọrọ ẹni to ti gba owo ni nitori pe oloselu ti lọwọ nibẹ.
O tun ni oun ko ni da Oba ki Oba ti ko ba sọ ootọ ọrọ lori ijinigbe to n ṣẹlẹ nilẹ Oodua lohun lasiko yii.
- 'Ẹ yé bú Seyi Makinde, owó rẹ̀ ló fí ra Ọkọ bọ̀gìnì fún Alhaja Abosede Adedibu, Taye Currency, Mutiat Ladoja'
- Ìjọba Nàìjíríà ti sún ọjọ́ ìforúkọsílẹ káàdi ìbánisọ̀rọ̀ síwájú síi
- Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ mú àgùnbánirọ̀ di èrò iléẹjọ́ ní ìpínlẹ̀ Kogi
- Ǹkan tÍ Sunday Igboho ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun- Olórí Miyetti Allah ilẹ̀ Yorùbá
- Seyi Makinde fi ọkọ̀ ńlá mẹ́rin dá ikọ̀ Amotẹkun lọ́lá nípìnlẹ̀ Oyo























