Six soldiers secretly executed: Ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ní pé wọ́n pa ọmọ ogun mẹ́fà tó jẹ́ iran Igbo nikọ̀kọ̀ ní Abuja- Iléeṣẹ́ ológun

ologun

Oríṣun àwòrán, @Nigeria Army

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọmọ ogun ilẹ ni orilẹ-ede Naijiria ti kede pe iroyin ẹlẹjẹ ni o gab igboro kan bayii.

Wọn ni iroyin naa to n sọ pe wọn ti ṣe iku pa awọn ọmọ ogun mẹfa kan ni ikọkọ jẹ irọ to jinna si ootọ.

Iroyin naa tun ṣapejuwe awọn ọmọ ogun ti wọn pa naa pe iran Igbo ni wọn ti wa ni ila oorun guusu Naijiria tai pe ẹsin Igbagbọ ni awọn ọmọ ogun mẹfa naa n sin.

Lọsan yii ni ileeṣẹ ologun fi soju opo ayelujara twitter wọn pe iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin naa:

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Lẹyin ti wọn fi eyi sita ni oju opo ayelujara wọn ni ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti n sọrọ pada fun wọn.

omo ogun
Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Iroyin to jade naa sọ pe Ogagun Buratai lo paṣẹ pe ki wọn pa awọn ọmọ ogun mẹfa naa nikọkọ lalẹ ọjọ to n fẹyinti kuro lẹnu iṣẹ ologun.

Awọn miran ni aṣẹ lati pa awọn ọmọ ogun ẹya Igbo méfa yii ni aṣẹ ikẹyin ti Tukur Buratai pa gẹgẹ bii adari ikọ ọmọ ogun Naijiria.

O fẹyinti lọjọ kérindinlọgbọn, osu kinni ọdun 2021.

omo ogun

Bẹẹ naa ni awọn eeyan miran n sọ pe ki ileeṣẹ ọmọ ogun pe ipade pẹlu awọn akọroyin ki wọn si ṣafihan awọn ọmọ ogun ti iroyin naa n sọ pe wọn ti pa danu.

Wọn ni eyi yoo jẹ ki awọn eeyan mọ pe ootọ ni ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria n sọ.

omo ogun
Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ